Mo mọ̀ pé àwọn àgbà APC kan ṣiṣẹ́ fún mi láti borí ìbò - Adeleke

Ademola ati Isiaka Adeleke

Oríṣun àwòrán, Screenshot/Channel

Gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti ṣapejuwe ẹgbọn rẹ to doloogbe, Isiaka, gẹgẹ bi akinkanju eniyan ti oun ko le gbagbe ipa rẹ ninu aye oun.

Adeleke sọ eyi pẹlu omije loju lasiko to n ba ileeṣẹ Channels sọrọ lori bi oun se pegede ninu idibo sipo gomina nipinlẹ Osun.

Adeleke ni oun ko lee gbagbe ẹgbọn oun titi lai nitori ipa rẹ ninu aye oun, lo jẹ ki oun ṣe aṣeyọri, to fi di gomina ti wọn dibo yan ni ọjọ oni.

O ni nitori naa ni oun ṣe fi aṣeyọri gẹgẹ bi gomina naa fun ẹgbọn oun to doloogbe, lasiko to n dije dupo gomina nipinlẹ Osun.

Ẹgbọn rẹ ọhun lo doloogbe ni Ọjọ Kẹtalelogun, Oṣu Kẹrin, ọdun 2017 saaju idibo sipo gomina ni ọdun naa lọun.

Gomina ti wọn dibo yan naa ni oun dupẹ pe ẹmi ẹgbọn oun si n wa sibẹ nitori nibayii ti oun ti di gomina ti won dibo yan an, oun lo ṣe atilẹyin fun oun.

‘’Pẹlu Igbagbọ ninu Ọlọrun mo ṣetan lati sin awọn ara ipinlẹ Osun’’

Gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti fi ọkan awọn ara ipinlẹ Osun balẹ wi pe oun yoo ṣiṣẹ fun wọn.

Adeleke lo sọ ọrọ yii ninu atẹjade to fi lede lati gba esi idibo to gbe e wọle gẹgẹ bi gomina ni ipinlẹ Osun.

O fi gbogbo ogo fun Ọlọrun to si dupẹ lọwọ awọn oludibo to yan oun sipo to fi mọ gbogbo awọn to ṣatilẹyin fun un, paapaa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ninu atẹjade naa lo ti ni oun gba lati sin awọn eniyan ipinlẹ Osun gẹgẹ bi gomina wọn, ti oun si fi n da wọn loju pe oun yoo ṣiṣẹ fun wọn, ti oun ko si ni ja wọn kulẹ.

Bakan naa lo fikun un pe, aṣeyọri naa ko ṣẹyin ẹgbọn oun gomina tẹlẹri, Isiaka Adetunji Adeleke,to fi mọ gbogbo awọn ẹbi Adeleke patapata, awọn ọmọbibi ilu Osun ni ile ni oko ati gbogbo awọn alatilẹyin rẹ.

O dá mi lójú pé awọn kan ni APC ṣiṣẹ fun mi lati bori ibo

Sẹnatọ Ademola Adeleke ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan naa ti ni oun ko ni nkankan ṣe pọ pẹlu minisita fun ọrọ abẹle ni Naijiria, Rauf Aregbesola lori bi oun ṣe de ipo gomina ipinlẹ Osun.

Eyi ko ṣẹyin iroyin to n ja ranyin pe Aregbesola ṣiṣẹ lati ripe Adeleke bori ninu idibo sipo gomina to waye nipinlẹ Osun.

Iroyin kan lo ti kede saaju pe Aregbesola ati oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu gbena woju ara wọn.

Amọ nigba ti Adeleke n ba ileeṣẹ Iroyin Channels sọrọ, o ni oun ko fi igba kankan ba Aregbesola sọrọ ṣaaju lasiko idibo.

Amọ o fikun un pe awọn minisita kan ni ijọba Buhari ṣiṣẹ papọ pelụ oun lati ripe oun di gomina ipinle Osun tako oludije lẹgbe oselu APC.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Twitter

‘’Mi o ṣiṣẹ pẹlu Aregbesola, mi o si ba sọrọ amọ o damiloju pe awọn olubaṣiṣẹ pọ rẹ ati awọn kan ni ẹgbẹ oṣelu APC ṣiṣẹ fun mi lati bori ninu idije si ipo gomina naa.’’

Bakan naa lo fikun un pe kii ṣe iṣẹ kekere lati bori ninu idibo naa nitori ẹgbẹ oṣelu miran lo di ipo naa mu , ti oun naa si pẹlu awon oludije fun saa keji.

Amọ o ni oun fi gbogbo ogo fun Ọlọrun to jẹ ki o ṣeese fun oun lati di gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ni ipinlẹ Osun.