Adeleke, yàgò fún ìwà ìdàlúrú pẹ̀lú àwọn alátìlẹyin rẹ̀ - Ọlọ́pàá Osun

Oríṣun àwòrán, aadeleke_01/Instagram
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti kilọ fun gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Ademola Adeleke atawọn alatilẹyin rẹ, pe ki wọn rọra ṣe ajọyọ lasiko ti yoo gba iwe ẹri mo yege lọwọ ajọ INEC.
Ikilọ yii lo jade ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ naa, Yemisi Opalola fi ṣọwọ si awọn akọroyin.
Opalola kilọ fun Adeleke, to fi mọ awọn alatilẹyin rẹ pe ki wọn wu iwa ọmọluabi lasiko ti yoo gba iwe ẹri naa, ki wọn si sọra fun sisọ awọn ọrọ kobakungbe to le da wahala silẹ ni ọọfisi INEC ti yoo ti gba iwe ẹri ọhun.
Atẹjade naa ni “Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe Sẹnetọ Ademola Adeleke yoo gba iwe ẹri moyege lọwọ ajọ INEC logunjọ, oṣu Keje, ọdun 2022 yii.”
“Fun idi eyii, kọmiṣọna ọlọpaa, Olawale Olokode, to ni ojuṣe lati daabo bo awọn araalu fẹ kilọ fun awọn eeyan ki wọn maa wu iwa ọmọluabi ni gbogbo igba.”
“O tun fẹ fi akoko yii ke si Sẹnetọ Ademola Adeleke atawọn alatilẹyin rẹ ki wọn ṣajọyọ ni iwọmba, ki wọn si yago fun sisọ ọrọ alufansa to le da omi alaafia ipinlẹ Osun ru.”
Opalola tẹsiwaju pe ikilọ naa ṣe pataki nitori awọn kọlọrọsi ẹda kan le fẹ lo anfani eto naa lati da wahala silẹ laarin ilu, ileeṣẹ ọlọpaa ko si ni la oju rẹ silẹ ki irufẹ nnkan bẹẹ waye.
Lẹyin naa lo ke si awọn eeyan ipinlẹ Osun lati fọwọsowọpọ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa ki alaafia ti awọn eeyan ipinlẹ naa n gbadun le maa tẹsiwaju.
Ẹwẹ, opin ọsẹ to kọja ni eto idibo naa waye, nibi ti Ademola Adeleke ti leke lẹyin ti esi idibo ọhun jade, nigba ti gomina Gboyega Oyetola to n diju du ipo fun saa keji si lulẹ.
Ọdun 2018 ni ibo kọkọ gbe Oyetola wọle gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Osun fun saa akọkọ.
Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?
Janduku kọlu pátákó ìpolongo Oyetola, lẹ́yìn to lulẹ̀ nínú ìbò Gómìnà

Lẹyin abajade esi idibo sí ipò gomina ni ipinlẹ Ọsun, eyi to waye lọjọ Sátidé ọjọ kẹrindilogun oṣu keje, awọn èèyàn kan ti n huwa janduku.
Ọpọ ọkundun omo isọta kan ti kọlu awọn patako ipolongo ti gomina ipinlẹ naa, to wa kaakiri awọn ibudo kan ni Ilu Osogbo, tii ṣe olu ilu ipinlẹ naa.
Lawọn agbegbe bii Ọlaiya labẹ afara to wa nibẹ, aworan ipolongo Oludije ẹgbẹ oṣelu APC naa ni wọn ya pẹrẹpẹrẹ.
Bakan naa lọrọ ri lagbegbe Oke-fia, Ọfiisi gomina tẹlẹ, ọjaaba ati bẹẹbẹ lọ.
Ni gbogbo awọn agbegbe ti ìkọ BBC de wọnyii, awọn araalu ti wọn ba wa sọrọ ṣalaye pe awọn kò leè sọ ni pato igun ti awọn to ṣiṣẹ naa ti wa.
Amọsa lẹyin ti ajọ INEC Kede esi idibo naa ninu eyi ti Ademọla Adeleke, Oludije ẹgbẹ oṣelu PDP ti jáwé Olubori, ni wọn ṣe iṣẹ náà.
Gomina ipinlẹ Ọsun, to jẹ Oludije ẹgbẹ oṣelu APC ninu idibo gomina naa, lo gbe ipo keji pẹlu ibo ẹgbẹrun lọna ọrinlelọdunrun o din marun ati mẹtadinlogbon (375,027).
Ademọla Adeleke, ti ẹgbẹ oṣelu PDP si gbe igba oroke pẹlu ibo ẹgbẹrun lọna irinwo le mẹta ati ọdunrun le mọkanlelaadọrin (403, 371)

Àwọn alágbára yí ìbò lọ́dún 2018 àmọ́ Ọlọ́run fi ‘Hammer’ jàn wọ́n mọ́lẹ̀ ní 2022 - Aráàlú
"Ẹ ṣe àjọyọ̀ bí Adeleke ṣe mókè lọ́nà tí kò ní mú ẹ̀mí lọ tàbí ba dúkìá jẹ́"

Bi eto idibo gomina nipinlẹ Osun ṣe ti kasẹ nilẹ fun ọdun 2022, ti ajọ eleto idibo nilẹ wa si kede Sẹnatọ Ademola Adeleke, tii se oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori, ogunlọpọ awọn arailu ti sọrọ nipa esi ibo naa.
Nigba ti wọn n ba ikọ iroyin BBC Yoruba sọrọ nilu Osogbo, ọpọ araalu salaye pe kaadi idibo awọn, eyiun PVC lo ṣe idajọ fun awọn lati yan gomina tuntun.
Adeleke ni o jawe olubori pẹlu apapọ ibo 403,371 eyi to mu ko fi ẹyin gomina to wa lori aleefa janlẹ, eyiun Adegboyega Oyetola.
Ẹ ṣe àjọyọ̀ bí Adeleke ṣe mókè lọ́nà tí kò ní mú ẹ̀mí lọ tàbí ba dúkìá jẹ́:
Eekanlu kan, Hon Abdulmaroof Adewale Adebayo, to jẹ oludije fun ile asoju-sofin labẹ asia ẹgbẹ PDP, to fẹ soju ẹkun idibo Orile, Orolu, Osogbo ati Olorunda nipinlẹ Osun, ni eto idibo naa ati ikede lo jẹ orire ti ọpọlọpọ awọn ọmọ ipinlẹ Osun beere fun.
“Awọn alagbara yii ibo to koja lọdun 2018, sugbọn Ọlọ́run fi ‘Hammer’ jàn wọ́n mọ́lẹ̀ ní 2022.”
“Ibẹrẹ ohun tuntun ti bẹrẹ bayi ni ipinlẹ Osun bi Ademola Adeleke ṣe bori ibo, irorun ni yoo jẹ fawa arailu, a ko ni kabamọ.”
“Mo fẹ sọ fawọn eeyan ipinlẹ Osun pe ibẹrẹ ọtun ree, ki awa alatilẹyin si ṣe ajoyọ lọna ti ko ni gba mu ẹmi lọ tabi ba dukia jẹ.”

Ẹyin PDP, ẹ se suuru, ilu ko gbọdọ daru ki Adeleke to gba ijọba:
Sẹnatọ Francis Fadahunsi ni ohun ayo lo gbode nitori ipinlẹ Osun ti sorire, Ademola ti gbe orire wa.
O ni ọdun mejila tawọn ti wa ninu isoro APC ree nipinlẹ naa, awọn to jẹ oludari ẹgbẹ PDP ni Osun si lawọn mọ ohun tawọn n fori rọ.”
“Ọrọ iyanju mi ni pe a si nilo adura si ni asiko perete to ku ki Ademola Adeleke fi gba ijọba, a gbọdọ ṣe suuru, ilu ko gbọdọ daru.”
Ọpọ ọdọ to kẹko jade nile ẹko fasiti lo n gun okada kiri lati ri ọwọ mu lọ sẹnu, ọpọ si ni yoo ri isẹ akanṣe ti a ṣe ta ba depo.”

Káàdì ìdìbò ló ṣe idajọ láàrin wa àti APC- Àwọn Aráàlú
Awọn arailu miiran to BBC NEWS YORUBA sọrọ ni ko si eru ninu idibo to waye ni Osun, ti ẹgbẹ PDP si ti setan lati fa APC mọra, ti wọn ba fẹ bẹẹ.
Awọn araalu naa ni imọlẹ sẹsẹ wọ ipinlẹ Osun ni nitori inu okunkun ni awọn wa tẹlẹ.
“Ikede Adeleke pe oun lo moke ninu esi ibo gomina yii lo jẹ imọle ati itura fawa eeyan ipinlẹ Osun.”
“APC n fi iya jẹ wa tẹlẹ, wọn pin ẹgbẹrun mẹẹdogun fun wa lọjọ idibo, nibo ni wọn ko owo si tẹlẹ, ti wọn si n fi iya jẹ wa.”












