Bàtà MKO tóbi fún mi láti wọ̀ àmọ́ kó tó kú, ló ti ń fi mi yangàn - Kola Abiola
Odu ni Basọrun Moshood Kashimaawo Olawale Abiola ti ọpọ eeyan mọ si MKO Abiola, ni agbo oselu ati okoowo ni Naijiria.
Abiola yii si ni ọpọ eeyan gba pe o bori idibo aarẹ lọdun 1993 amọ ti ijọba ologun wọgile ibo naa, ti wọn si ju si atimọle, nibi ti ọlọjọ de ba si.
Amọ lọdun 2023 ti ibo gbogbo gboo yoo waye ni Naijiria, eyi ti yoo pe ọgbọn ọdun ti MKO Abiola dije fun ipo aarẹ, akọbi rẹ, Kola Abiola naa yoo kopa lati dije fun ipo aarẹ naa.
Abẹ ẹgbẹ oselu Peoples Reddemption Party, PRP si ni Kola Abiola ti fẹ dije fun ipo aarẹ.
Idi ree ti BBC Yoruba fi tọ akọbi MKO lọ, lati mọ idi to se fẹ ti ẹsẹ bọ bata ti baba rẹ bọ silẹ ati awọn erongba to ni fun Naijiria.
Ki nnkan yatọ ni Naijiria ni mo n wa, ti mo se fẹ dije fun ipo aarẹ:
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Kola Abiola ni ohun to jẹ oun logun julọ, ti oun se pinnu lati dije fun ipo aarẹ, ni lati mu iyipada rere ba ipo ti orilẹede yii wa.
Kola ni oun ti kọ ẹkọ to ye kooro ati iriri pupọ ni ọdọ baba oun, ti oun si ti setan lati se amulo awọn ẹkọ naa fun Naijiria nitori ọmọ kii ba ipele iya rẹ, ko si asọ da.
O salaye pe awọn adari wa tẹlẹ ko se ohun to wu ni lori to fun Naijiria.
:”Pẹlu ẹkọ ti mo ti kọ lara MKO ati iya to bi mi lọmọ, mo ti to oju bọ, mo ti tun ara mi bi, laifoya, mo setan fun isẹ aarẹ ti mo fẹ se.
Mo le sọrọ nipa eto ẹkọ, aabo ati ọrọ aje, ohun to ba ba oju, yoo ba mu, ti aarẹ ko ba si mọ ohun to fẹ se, wisẹ rẹ ko ni seese, ọrọ lasan ni yoo jẹ.
Ẹgbẹ PRP nikan ni ẹgbẹ to rọrun lati dije labẹ rẹ pẹlu owo pọọku:
Nigba to n sọrọ lori idi to se fẹ dije labẹ ẹgbẹ oselu PRP, Kola Abiola ni fun oun, ẹgbẹ naa lo rọrun julọ lati dije.
“Ẹgbẹ PRP nikan ni eeyan ti le lo ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan naira dije sile asoju-sofin, miliọnu kan abọ nairalati dije sipo gomina ati ẹgbẹrun lọna aadọta naira sile asofin ipinlẹ.
O ni eyi ni yoo mu ko rọrun fun awọn ọdọ lai le kopa ninu oselu, ti wọn yoo si tọ wara to n san ni Najiria wo.
Ẹgbẹ PRP yii si ni yoo fun mi ni anfaani lati se amusẹ erongba mi fun orilẹede Naijiria.
Ko si ẹni to mọ Kola, ti ko MKO:
Nigba to n sọ nipa ajọsepọ to wa laarin oun ati baba rẹ, ki onitọun to jade laye, Kola ni bi igbin ba fa, ikarahun a tẹle ni awọn mejeeji.
O ni ibi ti baba oun maa n lọ, ti oun kii tẹle, bẹẹ ni ko si ẹni to mọ MKO, ti ko mọ Kola, kò sí sí òun tí MKO fẹ́ ṣe, ti ko ni fi lọ oun nitori oun ti kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ lára rẹ̀.
“Nitootọ bata MKO tobi lati ki ẹsẹ sinu rẹ, amọ ko si ẹni to mọ MKO ti ko mọ Kola, ko si si ẹni to mọ Kola, ti ko mọ MKO.
Ko si ibi ti MKO n lọ, ti ko mu Kola dani, ko si si ibi to de, ti ko fi Kola yangan pe ọmọ mi yii dara to mi, ti ko ba tiẹ dara ju mi lọ."






