“Kátàkárà ní ìbò gómìnà Osun, ’ìkòkò ọbẹ̀‘ àti ‘ọmọ́bọ́láńlé’ ló fi owó dárà láàrin ara wọn”

Àkọlé fídíò, Osun 2022: Olùdíje gómìnà fẹ́gbẹ́ ZLP àti SDP sọ̀rọ̀ lórí èsì ìbò gómìnà

Nigbayii ti eto idibo gomina nipinlẹ Osun ti wa, ti ajọ eleto idibo si ti kede ẹni to jawe olubori, oniruuru ọ̀rọ̀ lo ti n jade nipa esi ibo naa.

Eyi lo mu ki BBC Yoruba kan sawọn oludije to lulẹ ninu idibo gomina naa lati mọ ero wọn lori esi ibo ti ajọ INEC kede rẹ naa ati ẹni to jawe Olubori.

Awọn oludije meji to ba wa sọrọ naa lo wa latinu ẹgbẹ oselu ZLP ati SDP, eyiun John Adesuyi ati Oyegoke Omigbodun.

A ti gba fun Ọlọrun, n ko le du ipo gomina mọ tori ọjọ ori:

Awọn oludije mejeeji naa, nigba ti wọn n sọ ero wọn lori esi ibo gomina Osun salaye pe awọn ti gba fun Ọlọrun lori esi ibo naa.

Koda wọn ni awọn ko ni ẹjọ kankan tawọn le pe lori esi ibo naa nitori inu awọn dun sibi ti igi ibo naa wo si.

“Imọlẹ ti de sipinlẹOsun, okunkun si ti parada bayii, esi ibo naa si lo n sọ fun wa pe Naijiria si le dara si.

Koda, inu mi dun pe ibo lulẹ lọdọ awọn ta fẹko kuro ni ijọba nitori aigbọran wọn ti pọju.

Aburu wọn ti to gẹẹ, ọrọ araye ko ye wọn, ti ọrọ wọn naa ko si ye araye rara.

Iwa ‘dibo ko sebẹ’ waye lasiko ibo gomina l‘Osun:

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn oludije sipo gomina naa, Omigbodun ati Adesuyi ni wọn dijọ gba pe lootọ ni awọn oloselu kan na owo tabua lati ra ibo araalu lasiko idibo naa.

Wọn ni awọn oludije PDP ati APC to se ipo kinni ati ipo keji ninu esi ibo naa, lo fi owo taaka laarin ara wọn lati ra ibo.

“Olowo meji lo ta kangbọn sira wọn lasiko ibo Osun, owo nina ko ipa pupọ ninu ibo naa.

Katakara gbaa ni ibo ta se ni Osun, awọn olowo meji lo ta kangbọn laarin ara wọn lasiko ibo naa, obitibiti owo si lo lọ nibẹ.

Ọkan jẹ ikoko ọbẹ, ti owo ijọba Osun wa lọdọ rẹ nigba ti ekeji jẹ ọmọbolanle, to ba owo nile, ti ọla si tun n gori ọla fun.”

Awọn oludije naa ni asiko tawọn naa yoo de laipẹ bi o tilẹ jẹ pe Omigbodun ni oun ko le du ipo gomina mọ nitori ọjọ ori oun.

A ti ki Adeleke to wọle ibo lori aago:

Awọn oludije mejeeji sipo gomina naa wa kede pe awọn ti pe Ademola Adeleke to wọle ibo naa lori aago lati ki ku oriire.

Koda, wọn ni awọn setan lati sugba rẹ, kawọn si fun nimọran pẹlu ọgbọn iselu tawọn ni, ko ba le se aseye ti alakan n sepo, ki ipinlẹ Osun le ni igbega to yẹ.

Wọn wa gba nimọran lati se agbeyẹwo awọn ohun to ti bajẹ nipinlẹ Osun, ko si wa ọna ti yoo fi se atunse wọn.