WAFCON 2022: Super Falcons kọ̀ láti lọ fún ìgbaradì lórí pápá torí owó tí NFF jẹ́ wọn
Àìrí owó ilẹ̀ òkèèrè ṣẹ̀ẹ́ ló n dá owó Super Falcons àti àwọn àlámòjútó wọn dúró - NFF

Oríṣun àwòrán, super falcons
Ajọ bọọlu alafẹsẹgba ni Naijiria, NFF, ti sọ pe iṣoro ọ̀wọ́n gogo owo ilẹ̀ okeere ni ko jẹ ki oun ti san owo oṣù fun àwọn agbabọọlu Super Falcons.
Owurọ Ọjọ́ru ni àwọn agbabọọlu obìnrin orile-ede Naijiria, Super Falcons, kọ̀ lati lọ si pápá igbaradi wọn ṣáájú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ pẹlu agbabọọlu orile-ede Zambia.
Eyi ko sẹ́yìn owo ti ìjọba Naijiria jẹ wọn.
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa ni yoo sọ ẹni ti yoo gba àmì ẹyẹ fun ipo kẹta ninu idije WAFCON 2022 to n lọ lọwọ ni Morocco.
Sugbọn ninu fidio kan ti ajọ NFF fi sita, aṣoju aarẹ NFF, Amaju Pinnick, Alhaji Ibrahim Gusau sọ pe aitete ri owo àwọn agbabọọlu naa san, jẹ ibanujẹ fun 'gbogbo wa'.
'Inu gbogbo eeyan nile ati nilẹ okeere lo dun si bi àwọn agbabọọlu naa ṣe ṣe ni idije yìí.

Oríṣun àwòrán, super falcons/ twitter
' Gbogbo ipa wa la sì n ṣa, lati ri paṣipaarọ owo ilẹ̀ okeere ṣe."
O ṣàlàyé pe àwọn ti n ṣiṣẹ pẹlu gbogbo awọn ti ọ̀rọ̀ kan lati mu ki owo wọ inu apo àsùnwọ̀n àwọn agbabọọlu obìnrin naa laipẹ.
Alhaji Gusau sọ pe oun ti ṣe ipade pẹlu awọn agbabọọlu naa ni ile ìtura ti wọn wà, lori ọrọ naa.
O ni ibinu wọn si ti rọlẹ̀ lẹyin àrọwà ati àlàyé ti awọn ṣe fun wọn.

Ẹgbẹ́ agbabọọlu obìnrin orile-ede Naijiria, Super Falcons, ti kọ̀ lati lọ fun igbaradi wọn ṣáájú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ pẹlu agbabọọlu orile-ede Zambia.
Ọjọ Ẹti ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa yoo waye, nibi ti ẹgbẹ́ agbabọọlu mejeeji yoo ti koju ara wọn lati jà fun ipo kẹta ninu idije WAFCON 2022 to n lọ lọwọ ni Morocco.
Sugbọn iroyin to jade ni owurọ Ọjọ́ru ni pe, awọn agbabọọlu naa kọ lati jade kuro ni ile itura wọn, nigba ti asiko to o lati lọ si papa igbaradi.
Bo tilẹ jẹ pe BBC ko tii le fìdí nkan to fa igbeṣẹ naa mulẹ lati ọdọ awọn agbabọọlu, Iroyin sọ pe wọn ṣe bẹ́ẹ̀ nitori owo oṣù ati ajẹmọnu ti ajọ to n sakoso bọọlu ni Naijiria, NFF, jẹ wọn.
Gbogbo igbiyanju ikọ iroyin BBC Yoruba to wa ni Morocco lati ba awọn alaṣẹ ẹgbẹ́ agbabọọlu Super Falcons naa sọ̀rọ̀, ni ko tii so eso rere.
A o ma a fun yin ni ẹkunrẹrẹ iroyin naa, to ba ṣe n jáde.


Oríṣun àwòrán, others
Ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ́lù Morocco ṣí adé akọni ìdíje WAFCON kúrò lórí Naijiria
Àlá ẹgbẹ́ agbabọọlu obìnrin ti orile-ede Naijiria, Super Falcons, lati tun gba ife ẹyẹ idije bọọlu àwọn obìnrin ni Africa, lọdun yii ti já si òfo.
Eyi waye lẹyin ti ẹgbẹ́ agbabọọlu orile-ede Morocco lu wọn ninu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ to kangun si aṣekagba, semi final to waye lọjọ Aje.
Papa ìṣeré Moulay Abdellah n'ilu Rabat, Morocco ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa ti waye.
Igba mẹsan-an ni Naijiria ti gba ife ninu igba mejila ti WAFCON ti waye.
Ọdún 2018 ni wọn gba a kẹhin, amọ ti 2022 ti ko bá jẹ ikẹwa bọ mọ wọn lọwọ.
Ni bayii, ipo kẹta ni Super Falcons yoo jà fun nigba ti wọn ba koju orile-ede Zambia.

Oríṣun àwòrán, CAF
Bi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa ṣe lọ
Aago mẹsan-an alẹ ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa bẹ̀rẹ̀.
Lati ibẹrẹ lo si ti gbóná janjan.
Titi abala akọkọ fi parí, ọ̀mì odo ni Super Falcons ati Atlas Lionesses ti Morocco gbá.
Sugbọn nigba ti ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọ abala kejì, ní iṣẹju, Uchenna Kanu gbá bọọlu si awọn Morocco.
Amọ ko ju iṣẹju meji lọ, ti Morocco fi da a pada fun wọn.

Oríṣun àwòrán, CAF
Agbabọọlu gbòógì meji ninu ikọ̀ Super Falcons lo gba 'red card' ni abala keji.
Halimatu Ayinde ati Rasheedat Ajibade.
Eyi to mu ki ọmọ ikọ̀ wọn ku mẹsan-an.
Àwọn mẹsan-an lo si pari ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa, lati koju mọkanla ti Morocco ní.
Ọ̀mì ayo kan ni wọn ta titi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ fi pari lẹyin aadọrun iṣẹju.
Sugbọn àwọn adari ayo fun wọn ni ọgbọn iṣẹju si i.
Ko si ayipada kankan, eyi to mu ki wọn o gba pẹnariti.
Ninu maarun-un ti ẹgbẹ́ agbabọọlu kọọkan gbá, Naijiria padanu ẹyọkan.
Ohun si lo mu ki Morocco bori.

Oríṣun àwòrán, CAF















