Wo ẹ̀kọ́ márùn ún tí ìbò Osun kọ́ olóṣèlú àti aráàlú

Osun Election

Oríṣun àwòrán, APC/PDP

Eto idibo gomina nipinlẹ Osun ti wa, to si ti kasẹ nilẹ, koda, ajọ eleto idibo INECm ti kede ẹni to jawe olubori ninu ibo naa.

Sẹnetọ Ademola Adeleke, tii se oludije ẹgbẹ oselu PDP, lo moke ninu ibo naa pẹlu ibo 403,371.

O si fi ẹyin gomina to wa lori aleefa, Gboyega Oyetola janlẹ, ẹni to jẹ oludije ẹgbẹ APC, to ni ibo 375,027.

Amọ bi o tilẹ jẹ pe idibo naa ti waye, to si ti lọ, sibẹ awọn ẹkọ kan wa to yẹ ki awọn oludibo ati oloselu kọ lara ibo gomina to waye naa.

Idi si ree ti BBC Yoruba fi se akojọpọ koko marun to yẹ ka fi kọ ẹkọ nla nipa ibo gomina ni Osun.

Yoruba ni ti ọmọde ba subu, yoo wo iwaju, bawọn agba ba si subu, wọn yoo wo ẹyin wo, lati mọ ohun to gbe wọn subu.

Ẹgbẹ Alatako si le yẹ aga mọ gomina to wa nipo nidi:

Ẹkọ nla kan gboogi ti eto idibo gomina ipinlẹ Osun kọ awọn araalu ni pe ẹgbẹ alatako ṣi le gba ijọba lọwọ ẹgbẹ to wa lori alefa lọwọ, ti ko si si nkan to maa ṣẹlẹ lẹyin idibo naa.

Ni awọn ọdun diẹ sẹyin, ọpọ eeyan lo gbagbọ pe ẹgbẹ to ba wa lori alefa nikan lo le jawe olubori ninu eto idibo.

O maa n ri bẹẹ nigba mii, amọ eto idibo gomina Osun kọ wa lẹkọọ tuntun pe nnkan ti yi pada kuro ni ti atijọ.

Awọn ẹkọ miran ti idibo gommina l’Osun kọ wa ree.

Gboyega Oyetola

Oríṣun àwòrán, @GBOYEGAOYETOLA

Oṣelu to so mọ ẹsin ko ni ipa to pọ

Lootọ ni pe ipa ti ẹya ati ẹsin n ko ninu eto oṣelu Naijiria ko kere, paapaa ni ipinlẹ bii Osun.

Bo tilẹ jẹ pe ilẹ Yoruba ni idibo Osun ti waye, awọn ololufẹ awọn oludije meji to lami laaka julọ pin si ẹsin meji, tii ṣe ẹsin Musulumi ati ẹsin ọmọlẹyin Kristi.

Musulumi ni oludije ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Gboyega Oyetola, nigba ti ọpọ ri Ademola Adeleke gẹgẹ bii Kristẹni, amọ ẹsin mejeji lo n ba ṣepọ, bakan naa, Kristẹni ni igbakeji Adeleke, iyẹn Kola Adewusi.

Igun awọn eeyan kan n ṣatilẹyin fun Oyetola nitori o jẹ Musulumi, wọn si n ke si awọn Musulumi bii tirẹ lati dibo fun un nitori ẹlẹsin kan naa ni wọn.

Ara awọn to n ṣe ipolongo bẹẹ ni gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje.

Bo tilẹ jẹ pe ko si akọsilẹ kankan to fidi rẹ mulẹ pe ipinlẹ Musulumi ni ipinlẹ Osun, ọpọ eeyan lo gbagbọ pe Musulumi lo pọ ju l’Osun, sibẹ, Oyetola lulẹ.

Iṣoro ‘dibo koo sebẹ’ ṣi n ba Naijiria finra

Osun Election

Oríṣun àwòrán, INEC

Lootọ ọpọ awọn to bojuto eto idibo Osun lo n sọ pe eto idibo Naijiria ti n yi pada, bẹẹ ni ko si idarudapọ tabi iwa janduku bii ti atijọ, amọ ọpọ awọn eeyan lo ṣi n ta ibo wọn bi a ṣe ri l’Osun.

Awọn ẹri lati awọn ibudo idibo fi han pe ẹgbẹ oṣelu APC ati PDD mi wọn jọ ra ibọ lọjọ idibo ọhun.

Obinrin kan tilẹ sọ fun BBC pe awọn oludibo kan kọju ija si oun nitori pe oun kọ lati fun wọn lowo lẹyin ti wọ n dibo fun ẹgbẹ oun tan gẹgẹ bii ileri ti oun ti ṣe fun wọn ṣaaju.

Bo tilẹ jẹ ijọba n gbiyanju lati gbogun ti iwa ibo rira ati tita yii, awọn eeyan ṣi n ṣe bẹẹ gẹgẹ bo ṣe waye ni Ekiti ati Osun.

Esi ibo Osun ko sọ pe bi esi ibo gbogbogbo ọdun 2023 yoo ṣe ri ree

Osun Election

Oríṣun àwòrán, YIAGA AFRICA

Ni kete ti INEC kede pe PDP lo jawe olubori l’Osun, awọn alatilẹyin ẹgbẹ naa bẹrẹ si n sọ pe ẹgbẹ ọhun ni yoo bori lọdun to n bọ ninu eto idibo gbogbogbo.

Ṣugbọn awọn onimọ nipa ohun to n lọ kan ti sọ pe ọrọ le ma ri bi awọn alatilẹyin ẹgbẹ naa ṣe n sọ.

Ọjọgbọn kan ni fasiti ilu Maiduguri, Abubakar Mu'zu ni “Ẹwẹ, ẹnikẹni to ba sọ pe bi PDP ṣe gbajọba ni Osun ni yoo ri lọdun 2023 n tan ara rẹ jẹ ni, nitori ipinlẹ mẹrindinlogoji lo wa ni Naijiria, yatọ si Abuja ro jẹ olu ilu Naijiria.”

INEC gbiyanju

Gẹgẹ bii ohun ti a foju ganni l’Osun, lati Ọjọbọ ni ọpọ awọn ohun elo idibo ti balẹ si gbogbo ijọba ibilẹ ọgbọn to wa l’Osun.

Eyii jẹ atunṣe si idibo ipinlẹ Ekiti to jẹ pe ọjọ Ẹti ni wọn ko awọn ohun elo naa de awọn ijọba ibilẹ.

Bo tilẹ jẹ awọn ẹrọ BIVAS n fa bii igbin lawọn ibikan ni Iragbji, ni ijọba ibile Boripe.

Lootọ ni idibo naa kii ṣe idibo gbogbogo, amọ nnkan ti n ṣẹnu ire ju ti tẹlẹ lọ.

Ti gbogbo eto ba lọ bo ṣe yẹ, inu araalu yoo dun, ọkan wọn yoo si balẹ

Osun Election

Oríṣun àwòrán, NPF

Gbogbo ibudo idibo ti a de ni a ti ri awọn agbofinro to duru wamu-wamu lati pese abo to peye.

Bi a ṣe ri awọn ọlọpaa naa ni a ri awọn oṣiṣẹ NSCDC, DSS, NDLEA ati bẹẹ lọ.

Eyii lo mu ki agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria, Olumuyiwa Adejobi sọ pe inu oun dun pe awọn agbofinro mu ileri wọn ṣe lati daabo bo awọn araalu lasiko eto idibo naa, awọn yoo si tẹsiwaju lati maa ṣe bẹẹ lọjọ iwaju.