"Ẹ wo àwòkọ́ṣe Osinbajo, ẹ dẹ́kun lílọ sókè òkun fétó ìwòsàn"

Oríṣun àwòrán, others
Ẹgbẹ awọn dokita oniṣegun oyinbo ti parọwa si awọn oloṣelu Naijiria pe ki wọn tẹle awokọṣe Igbakeji Aarẹ orilẹede Naijiria, Ọjoọgbọn Yemi Osinbajo, bi o ṣe ni igbagbọ ninu eto ilera Naijiria.
NMA wa rọ awọn oloselu lati dẹkun lilọ oke okun fun itọju ara wọn.
Aarẹ ẹgbẹ NMA, Uche Ojinmah, lo gba wọn ni imọran bẹẹ niluu Abuja.
Bẹẹ ba gbagbe, laipẹ ni Igbakeji aarẹ kede loju opo Twitter rẹ lọjọ Satide pe oun wa nile iwosan lati sisẹ abẹ lẹyin ti oun n ni irora ooreekoore ni ẹsẹ oun.
Lẹyin isẹ abẹ ni alaafia de ba Igbakeji Aarẹ, to si ti kuro ni ilewosan, nibi ti o ti lọ sisẹ abẹ.
Ile iwosan Duchess International Hospital to wa niluu Eko, ni igbakeji aarẹ ti sisẹ abẹ naa.
Ojinmah ni oun kan saara si Igbakeji Aarẹ fun bi o ṣe ni igbagbọ ninu awọn dokita oniṣegun ati eto ilera Naijiria.
O fikun pe asiko ti to lati ṣe atunṣe si ọrọ eto ilera to mẹyẹ nilẹ wa, ka le fi mu idagbasoke ba eto ọrọ aje wa.
Gẹgẹ bi Ojinmah ṣe sọ, o ni inu awọn ẹgbẹ naa dun bi Igbakeji Aarẹ ṣe ransẹ ikini si ẹgbẹ fun isẹ takuntakun ti wọn ṣe lori isẹ abẹ naa.
”A fẹ dupẹ lọwọ Ọlọrun fun isẹ abẹ ti Igbakeji Aarẹ ṣe, ti a si gba ni adura pe ki Ọlọrun fun ni alafia.”
Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria ni wọn ma lọ si oke okun fun itọju nitori bi eto ilera ṣe mẹyẹ eyi to ti ṣe akoba fun idagbasoke fun wa.”
“Lati dẹkun iwa yii, a nilo lati ṣe atunṣe si eto ilera wa, ki awọn oloṣelu si gbaruku ti wa.”















