Adeleke, èsì ìbò fihàn pé aráàlú fẹ́ràn rẹ̀, jọ̀ọ́ san oore padà fún wọn - Ooni

Oríṣun àwòrán, From The Palace of Ooni of Ife/Facebook
Ooni Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi Ojaja keji, ti ki Sẹnetọr Ademola Adeleke , to jawe olubori ninu eto idibo sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ku oriire.
Ooni sọ pe ki gomina tuntun naa gbiyanju lati ko gbogbo araalu mọra, lai fi ti ẹgbẹ tabi awọn alatako ṣe.
Ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin lati ọwọ agbẹnusọ rẹ, Otunba Moses Olafare ni Ọba Ogunwusi ti fi ọrọ naa lede.
Gẹgẹ bii ohun ti Ooni sọ, esi idibo naa fi han pe awọn eeyan ipinlẹ Osun fẹran Adeleke gidi.
Ọba alaye naa ni o si yẹ ki gomina tuntun ọhun san oore pada fun wọn nipa ṣiṣe awọn ohun ti yoo mu ara rọ awọn araalu.
Atẹjade naa ni “Kii ṣe igba akọkọ ti Adeleke yoo dije ree, aṣeyọri rẹ ninu eto idibo yii jẹ ọna kan gboogi fun lati mu gbogbo awọn ileri to ti se fun awọn araalu lasiko ipolongo ibo rẹ ṣẹ.”
“Adeleke gbọdọ ri daju pe awọn araalu, paapaa awọn eeyan igberiko jẹ mudun-mudun ijọba awarawa, ti wọn fi ibẹru Ọlọrun ati ifẹ araalu dari.”
Ọọni tẹsiwaju pe Adeleke, to wa lati idile gbajumọ, ti kii si ṣe majesin ninu eto oṣelu, gbọdọ ṣọra fun awọn gbọyisọyi ti yoo gbiyanju lati kọ ẹyin rẹ si awọn ti wọn n wo gẹgẹ bii alatako ninu oṣelu.

Oríṣun àwòrán, Moses Olafare
Ooni kan sara si Oyetola

Oríṣun àwòrán, Moses Olafare
Ẹwẹ, Ojaja keji tun kan sara si gomina Gboyega Oyetola fun iwa ọmọluabi to wu lẹyin to padanu anfani rẹ lati ṣe gomina fun saa keji lẹyin eto idibo naa.
Ooni sọ pe idunnu lo jẹ fun oun bi Oyetola ṣe mu ileri to ṣe lasiko ti awọn oludije n tọwọ bọwe adehun alaafia ṣẹ, ti ko si wu iwa oloṣelu oni jagidijagan lẹyin to lulẹ lẹyin eto idibo naa.
O ni “Gomina Oyetola tọwọ bọwe adehun Alafia naa pẹlu awọn oludije mejila miran, nibi to ti ṣeleri lati wu iwa ọmọluabi lasiko ati lẹyin eto idibo, o si ṣe bẹẹ, eyii jẹ ohun iwuri nla fun awọn ori ade, o si yẹ ki a gboriyin fun.”
Ooni pari ọrọ rẹ pẹlu ọrọ idupẹ si awọn oludibo ti ko fa wahala kankan ṣaaju, lasiko, ati lẹyin eto idibo naa.
Lẹyin naa lo ni ti wọn ba tẹsiwaju lati maa wu iwa ọmọluabi bẹẹ, ipinlẹ Osun yoo goke agba, awọn araalu yoo si jere eto ijọba awarawa.
Óse! Ọkùnrin kan kó sí kàǹga ní Kwara, ló bá kú

Oríṣun àwòrán, KWARA FIRE SERVICE
Ọ̀dọ́mọkùnrin kan, ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lẹ́yìn tó já sí kàǹga ní ìpínlẹ̀ Kwara.
Banji Adebayo ti agboolé Ile-Nla ní Omu-Aran, ìjọba ìbílẹ̀ Irepodun pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sínú kàǹga náà lẹ́yìn tí ẹsẹ̀ rẹ̀ yẹ̀ sínú kàǹga náà.
Ní nǹkan bí ago márùn-ún àbọ̀ ìdájí ni Banji fẹ́ pọnmi nínú kàǹga náà ṣùgbọ́n tí ẹsẹ̀ rẹ̀ dédé yọ̀ tó sì kó sínú kàǹga náà.
Nígbà tó ń kéde ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà, agbẹnusọ iléeṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Kwara, Hassan Adekunle ní nígbà tí àwọn ma fi yọ ọkùnrin náà kúrò nínú kàǹga, ẹ̀mí rẹ̀ ti bọ́.
Adekunle ní àwọn ti gbé òkú Banji Adebayo lé àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ lọ́wọ́.
Bákan náà ló rọ àwọn ènìyàn láti máa ṣe jẹ́jẹ́ nídìí iṣẹ́ òòjọ́ wọn.












