Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí rèé pé Naira Marley fi jìbìtì wọ́ ike owó ọ̀pọ̀ èèyàn - EFCC

Aworan Naira Marley

Oríṣun àwòrán, NAIRA MARLEY / @DANYWONDERS

Ajọ to n risi iwa ajẹbanu ni Naijiria, EFCC ti se agbekalẹ awọn ẹri mii niwaju ileẹjọ, eyi ti wọn lo fi han pe akọrin nii, Naira Marley, fi ọna ẹburu lu kaadi owo awọn eeyan ni ponpo.

Eleyi ni ẹri kẹta ti ajọ EFCC yoo gbe wa lori ẹjọ ẹsun ti wọn fi kan akọrin takasufe yii, torukọ rẹ n jẹ Afeez Fashola, t wọn si fi sọwọ siwaju adajọ.

Ni iwaju ile ẹjọ giga to wa ni Eko ni ẹlẹri EFCC naa ti fi ọrọ to adajọ leti pe awọn ri ẹri pe Naira Marley lo ọna ẹburu fi lo akọsilẹ ori kaadi owo awọn eeyan lori kọputa alagbeka, laptop, rẹ.

Ki ni ẹlẹri sọ fun ile ẹjọ gan?

Dein Whyte, to jẹ ọga agba ẹka ọtẹlẹmuyẹ fajọ EFCC sọ pe ''nipa ayẹwo foonu Naira Marley, a ri pe o ni awọn iroyin kan nipa kaadi owo ti kii ṣe tiẹ''

O fi kun pe afurasi yii pin awọn akọsilẹ nipa ẹni ẹlẹni yii pẹlu ẹlomiran.

Bẹẹ lo ni wọn ti fẹjọ sun saaju lori kaadi owo yyi pe mago mago ti waye lori rẹ ri.

Bẹẹ lo ni lori laptop Naira Marley, awọn ri awọn irinṣẹ kan ti wọn fi daabo bo ẹnikẹni to ba lo awọn kaadi ti wọn ti lu pa wọnyi.

Ọ́ga agba ọtẹlẹmuyẹ EFCC to jẹri niwaju adajọ wa sọ pe, awọn fi iwadii yi sọwọ si ẹka to n ṣayẹwo ẹri .

O ni abọ iwadii naa si fi han pe Naira Marley n lo VPN kan lori laptop rẹ lati fi daabo bo ẹnikẹni to ba lo awọn kaadi owo ti wọn ti lu pa yi.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ''nipa awọn nnkan taa ri lori laptop Naira Marley, a ri software kan pẹlu awọn ayederu nọmba kaadi ati akọsilẹ nipa ẹni to ni kaadi naa ati adirẹsi IP kan''

Agbẹjọro fun Naira Marley, Olalekan Ojo tako ẹri ti wọn gbe kalẹ yii, to si ni wọn n gbe ẹri kalẹ lori nkan ti wọn lero pe o le wa ni ọkan ẹni to ni laptop lodi si nkan to han kedere si wọn.

O ni ẹni to wa jẹri niwaju adajọ ko si nipo lati sọ pato nkan to jẹ ero ọkan ẹni to ni laptop tabi nkan to gbero lati fi awọn akọsilẹ to ko jọ sori rẹ ṣe.

Ẹwẹ adajọ ti wọgile alaye rẹ yi to si ni lootọ ni ẹni to ni laptop wa nipo lati ṣalaye ohun to fẹ fi awọn iroyin to ko sori laptop naa ṣe.

Adajọ Oweibo ti wa sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ Kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹsan ati ọgbọnjọ oṣu Kẹsan ọdun 2022.