Tèmi yémi, àlàyé rèé lórí ìdí tí mo ṣe dúró ti Oyetola - Oluwo
Ìyà ń jẹ́ wá ní Iwo, ó yẹ káwa náà jẹ Gomìnà l‘Osun – Oluwo

Oríṣun àwòrán, Oluwo of Iwo
Oluwo ti ilu-Iwo, Oba AbdulRasheed Akanbi ti sọrọ lori bi esi idibo gomina to waye ni ipinlẹ Osun lọjọ Satide.
Esi ibo naa lo gbe Ademola Adeleke wọle gẹgẹ bi gomina tuntun fun ipinlẹ Osun.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori abajade esi idibo naa, Oluwo ni ohun to jẹ oun logun ni bi Ilu Iwo yoo ṣe fa gomina kalẹ ni ipinlẹ Osun.
O ni ẹkun idibo kan naa, eyiun ẹkun idibo iwọ oorun ipinlẹ Osun ni Iwo ati Ede, ti oludije gomina fẹgbẹ PDP, Ademola Adeleke ti jade.
“Awa ti Ede jọ wa labe iwo oorun ipinlẹ Osun ni, Ilu mi si ni ohun akọkọ ti mo fẹran ju ati pe ti ba ri nkan ti yoo di lọwọ, mo gbọdọ kọkọ sọ fun awọn ọmọ ilu pe nkan bayi iṣẹlẹ.”
Oluwo ni ọpọlọpọ igba ni oye ti wọn fi awọn ọmọ Iwo jẹ ni Kọmisana, ti o sapejuwe gẹgẹ bi ipo iransẹ.
“Ni Iwọ oorun ipinlẹ Osun, Iwọ si ni olu ilu ni bẹ, ko wa si ọmọ iwo kan to ṣe gomina ri, nkan ti wọn le fun wa ko ju kọmisana lọ, komisana si ni yi, ibi iransẹ ni, gomina ni ijọba.”
Oluwo wa ni ọlọrun nkan lo le yan eeyan si ipo, ti oun si fara mọ ohunkohun ti ọlọhun ba ti fọwọ si .
Mo tiraka pe ki ipo gomina kan Iwo lẹyin ọdun mẹjọ Oyetola, ni mo se duro tii - Oluwo
O ni amọ ti Oyetola ba pari saa keji, anfaani yoo wa fun Iwo lati fa oludije sipo gomina kalẹ.
Idi si ree ti oun se n tiraka pe ki Iwo ni anfaani si aga gomina lẹyin ọdun mẹjọ Oyetola.
Oluwo tẹsiwaju pe ko si anfani fun ọmọ Iwo lati di gomina ipinlẹ Osun, ti oun si fẹ ṣe ohun ti yoo mu idagba soke ba ilu iwo.
“Nnkan ti mo sọ fun awọn eniyan ni pe awa ni Iwo naa nilo lati jẹ gomina, sugbọn bi Ọlọrun ṣe pin niyẹn.”
“Nnkan to kan Iwo lo kan mi ju, ẹ jẹ ki Iwo na di gomina ni ipinlẹ Osun.”
“Ti a ba jẹ ki ibomiran labẹ ẹkun idibo iwọ oorun ipinlẹ Osun di gomina, ipo gomina ko le kan ilu Iwo niyẹn.”
Bi ọmọ Ede ba di Gomina, ipo naa ko le kan Iwo mọ, eyi lo si jẹ mi logun - Oluwo
Oluwo ni tawọn ba fi gba ki ilu miran se gomina ni ẹkun idibo Osun West, ipo gomina ko le kan Iwo mọ niyẹn.
"Mo gbọdọ kọkọ nifẹ ilu mi, ki n to nifẹ ibomii, n ko si fẹ ohunkohun to le di ilu mi lọwọ.
Iwo ni ibujoko Osun West Senatorial District, amọ ipo Kmisana ni wn maa n fun wa, eyi ti ko yatọ si ipo akọwe, amọ ipo gomina gan ni ijọba.
Ẹ ni ko ba gba fun Ọlọrun, o n ba Ọlọrun ja ni:
Nigba to n sọrọ lori bi yoo se fi ọwọ sowọpọ pẹlu gomina tuntun to n bọ, Oluwo ni oun ti gba fun Ọlọrun.
Ẹni ti lọrun ba ti yan, o ti yan niyẹn - Oluwo
Nigba to n sọrọ lori bi Ademola Adeleke se bori ibo gomina naa ati iru ajọsepọ ti yoo waye laarin awọn mejeeji, Oluwo ni ko si isoro kankan nibẹ.
"Ki ni mo wa fẹ se, mo ti jẹ amala ni aarọ yii, inu mi ti dun, n ko le ba Ọlọrun ja.
Ọlọrun lo maa n yan eeyan sipo, n ko si le ba Ọlọrun ja.
Isẹ tiwa ni ka maa gba awọn to n se ijọba nimọran, mo si mọ pe ko si nnkan to kan Iwo, ti ko ni kan Ede, a dijọ paala ni.
Ko si ẹni to le ya ajọsepọ wa, nnkan kan naa ni wa."















