“APC, ẹ má kábàámọ̀ lórí èsì ìbò Osun, àtúntò la nílò fajọ́ ìwájú”

Oríṣun àwòrán, officialasiwajubat/Instagram
Awọn ọmọ ẹgbẹ oselu APC nilẹ wa ti n gba raa wọn niyanju lori esi ibo gomina to waye nipinlẹ Osun eyi to mu ki ẹgbẹ oselu naa lulẹ.
Imọran si ti n wa pe ki awọn ọmọ ẹgbẹ oselu naa mase karibọnu tabi maa fi akoko sofo lati kabamọ lori esi ibo naa.
Sugbọn wọn ni nse lo yẹ ki wọn sanna lati wa ọna atunto, ti esi ibo yoo fi se wọn ni oore lọjọ iwaju.
Alakoso apapọ fun ẹgbẹ to n se atilẹyin fun Bola Tinubu lati di aarẹ, Disciples of Jagaban (DOJ), Alhaji Abdulhakeem Alawuje lo gbe imọran naa kalẹ.
Alawujẹ wa ke sawọn alatilẹyin Tinubu lati mase jẹ ki abajade esi ibo gomina nipinlẹ Osun da omi tutu si wọn lọkan lati maa ro erokero.
“Otitọ ọrọ to wa nilẹ, eyi to kọja ọrọ ẹlẹyamẹya tabi ẹlẹsinjẹsin ni pe awọn alatako Tinubu yoo gọ saarin ika kan.
O si yẹ ko ye awọn ọmọ Naijiria pe ta fi awọn idi imọtaraẹni nikan dibo, oju wa yoo da wai lẹyin eto idibo, ta si maa jẹrora ipinnu odi ta ba se nidi didi ibo wa lori sisegbe sibi kan.
Ohun ta nilo ni eto isejọba rere ati ọna ta gba mu ki ohun gbogbo lọ leto leto nilẹ wa fun tru tọmọ ati agbelarugẹ ọrọ Aje wa.”

Oríṣun àwòrán, Abdulhakeem Alawuje
















