Yemi Osinbajo: Àlàyé rèé lórí bí iṣẹ́ abẹ ẹsẹ̀ tí igbákejì ààrẹ ṣe lọ ní ìrọ̀rùn

Oríṣun àwòrán, Yemi Osinbajo
Alaafia ti de ba Igbakeji Aarẹ oriléede Naijiria, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo lẹyin ti o dero ilewosan lati sisẹ abẹ.
Ile iwosan Duchess International Hospital to wa niluu Eko ni igbakeji aarẹ ti sisẹ abẹ naa.
Isẹ abẹ naa lo waye nitori bi o ṣe ni irora ooreekoore ni ẹsẹ re lọjọ Satide.
- Wò gbajúmọ̀ òṣèré tíátà míì tó délé ẹjọ́ lẹ́yìn Baba Ijesha
- Olùkọ́ girama wọ gbaga ọlọ́pàá fẹ́sùn bíbá akẹ́kọ̀ọ́ lòpọ̀
- Ohun tóo ní láti mọ̀ nípa àwọn olùdíje Gómìnà Osun tí ẹnu ń kùn jù rèé
- 'Ó ń ṣe mi bíi kí n tètè parí sáà mi... Wo àwọn ǹkan tí Buhari ti sọ rí pé òun yóò máa ṣe lẹ́yìn sáà òun
- ‘’Ohun tó jẹ́ ìbànújẹ́ ọkàn fún mi jùlọ nipé mi ò lè rí ìyàwó tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́’’
Osinbajo ni o kede loju opo Twitter pe lootọ ni oun wa nile iwosan lati sisẹ abẹ.
Dokita ile wosan ọhun, Adedoyin Dosunmu Ogunbi ninu atẹsita kan ti o fi sita fun awọn akoroyin ni isẹ abẹ naa waye, ti ko si ba odi lọ lara igbakeji.
Ogunbi ni awọn akọsẹmọsẹ dokita oyinbo lo ṣe isẹ abẹ ọhun
Atẹsita ti Ogunbi fi si ita ni akole rẹ n jẹ, "Bi isẹ abẹ igbakejiAarẹ ṣe lọ ni irọrun."
"Igbakeji Aarẹ orilẹede Naijiria , Ọjọgbọn Yemi Osinbajo lo kalẹ si ile wosan wa ni Ikẹja nitori bi o ṣe n ni irora oorekoore ni ẹsẹ rẹ lẹyin ti o kopa ninu ere idaraya kan ti oloyinbo pe ni 'Squash'. "
"Isẹ abẹ ti igbakeji Aarẹ ṣe ni o jẹ pe awọn akọsẹmọsẹ bi Dokita Wallace Ogufere, Dokita Om Lahoti, Dokita Ken Adegoke, Dokita Oladimeji Agbabiaka ati Dokita Adedoyin Dosunmu Ogunbi dari, ti o si lọ ni irọrun."
"Alaafia si ti de ba igbakeji aarẹ bayi, wọn yoo kuro ni ile wosan laipe yi."

Igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo ti dero ile iwosan

Oríṣun àwòrán, Yemi Osinbajo
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo ti dero ile iwosan, to si fẹ se isẹ abẹ.
Akọwe iroyin fun igbakeji aarẹ, Laolu Akande lo kede bẹẹ loju opo Twitter rẹ ni irọlẹ ọjọ Satide oni.
Gẹgẹ bi alaye ti Akande se, igbakeji aarẹ yoo se isẹ abẹ nitori irora oorekoore to n ni ni ẹsẹ rẹ.
- Olùkọ́ girama wọ gbaga ọlọ́pàá fẹ́sùn bíbá akẹ́kọ̀ọ́ lòpọ̀
- Ohun tóo ní láti mọ̀ nípa àwọn olùdíje Gómìnà Osun tí ẹnu ń kùn jù rèé
- 'Ó ń ṣe mi bíi kí n tètè parí sáà mi... Wo àwọn ǹkan tí Buhari ti sọ rí pé òun yóò máa ṣe lẹ́yìn sáà òun
- ‘’Ohun tó jẹ́ ìbànújẹ́ ọkàn fún mi jùlọ nipé mi ò lè rí ìyàwó tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́’’
O ni irora naa waye nitori bo se fi ẹsẹ pa lasiko to n se ere idaraya squash.
Agbẹnusọ fun igbakeji aarẹ naa fikun pe bi itọju ọjọgbọn Yemi Osinbajo ba se n lọ loni nile iwosan ni oun yoo maa bu aye gbọ.

Oríṣun àwòrán, Laolu Akande/Twitter
Bakan naa igbakeji aarẹ funra rẹ ti kede loju opo Twitter pe lootọ ni oun wa nile iwosan lati sisẹ abẹ.
Ikede naa to fisita ni deedee aago meje alẹ ọjọ Satide oni lo n fidi ohun ti agbẹnusọ rẹ ti kede saaju.
Osinbajo ni "Mo ti wa nile iwosan bayii fun isẹ abẹ nitori ẹsẹ to n dun mi eyi ti mo ni lasiko ti mo n gba ere idaraya Squash."
Bẹẹ ba gbagbe, kii se igba akọkọ ree ti wọn yoo kede pe igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo wa nile iwosan, loorekoore si ni ikede waye pe o maa n lọ se ayẹwo nile iwosan fun ilera ara rẹ.
Losu Karun ọdun to kọja, 2021, iroyin kede pe igbakeji aarẹ wa nile iwosan fun itọju ara rẹ.

Oríṣun àwòrán, Yemi Osinbajo/Twitter














