‘’Ohun tó jẹ́ ìbànújẹ́ ọkàn fún mi jùlọ nipé mi ò lè rí ìyàwó tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́’’

Aworan SAIFULLAH MUKHTAR

Oríṣun àwòrán, SAIFULLAH MUKHTAR

Arakunrin Saifullah Mukhtar ti sọ iriri rẹ lẹyin ọdun mẹtala ti o di ẹni ti ko ri iran mọ.

Ọdun mẹrindinlogun ni Muktar wa ti oju rẹ fi dede kọ lati riran mọ, to si wa ni ileẹkọ girama nigba naa ni ilu Kano, ni ariwa orilẹede Naijiria.

Lasiko to n ba BBC Pidgin sọrọ lo ni oun ko jẹ ki ipenija oju oun to fọ naa da oun duro lati gbe nkan rere ṣe ni ile aye.

Saifullah ko lọ si girama nikan, o kẹkọ jade ni fasiti Bayero University Kano, to si ti ri iṣẹ pẹlu ileeṣẹ ọrọ ofurufu lorilẹede Naijiria, Nigeria airspace management agency (NAMA).

O ni nigba ti oun di adọju, o da bi aye pari fun oun, ti awọn pẹlu awọn obi oun si n kaakiri lati ibi kan de omiran.

‘’Amọ nigba ti ẹmi ati awọn obi mi lọ si ọdọ arakunrin ara India kan ni o sọ fun wa pe, mi o le ri iran mọ lailai.’’

‘Ibànújẹ́ ọkàn nípé mí ò le rí ìyàwó tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́’

Arakunrin Saifullah Mukhtar ti ni lẹyin ti ayẹwọ ọhun fihan pe oun ko le riran mọ ni oun mu aya le, ti oun si pinnu lati ka iwe bi awọn akẹgbẹ oun.

‘’Lẹyin ti mo kuro ni fasiti BUK, ni mo lọ ka iwe fun Masters mi, ti mo si ri iṣẹ pẹlu Nigeria Airspace management agency’’

Bakan naa lo fikun un pe oun figagbaga pẹlu awọn to ni oju mejeeji lati ri iṣẹ naa, ti oun si tun fakọyọ.

‘’Amọran mi fun awọn to ni ipenija oju ni lati maṣ€ ro ara wọn pin ni agbaye nitori pe, bio tilẹ ma n dun eniyan pe oju rẹ ko ṣiṣẹ lati ri oun to n ṣẹlẹ ni agbaye.’’

Arakunrin Saifullah Mukhtar ni ki ẹni to ba da bi oun lọ si ileewosan lati lọ wo awọn to n la ipọnju ati aisan kọja to fi mọ awọn ti ko mọ ara mọ.

Nitori naa ki a maa dupẹ ninu ohun gbogbo.

Ọmọ Naijiria 50 Milion lo ni aisan ati ipenija oju

Ajọ to n risi iwosan oju lorilẹede Naijiria, Nigeria Optometrist Association ti kede pe iye awọn ọmọ Naijiria to ni aisan oju kii ṣe kekere.

Wọn sọ eyi lasiko ipade ajọ naa ti ọlọdọọdun, nibi ti wọn ti kede pe o kere tan ẹẹdẹgbẹta miliọnu awọn eniyan lo ni ipenija oju lagbaye, ti miliọnu meje ninu wọn si jẹ awọn ọmọ Naijiria.

Lara aisan to si n fa oju fifọ naa ni aisan Cataract, eleyii ti wọn si n ṣiṣẹ le lori lati wa ọna abayọ fun un, amọ iṣẹ abẹ lo ṣi wa lọ̀wọlọwọ.