Osun election 2022: Ohun tóo ní láti mọ̀ nípa àwọn olùdíje Gomina Osun
Oríṣun àwòrán, OTHERS
Kaakiri Naijiria ati awọn orilẹede agbaye ni wọn ti n reti igberasọ ati aṣekagba idibo ti yoo waye lọla ọjọ Abamẹta ọjọ Kẹrindinlogun Oṣu Keje ọdun 2022 ni Osun.
Awọn ara ipinlẹ Osun yoo maa tuyaya tuyaya jade lọ si awọn ibudo idibo wọn lati lọ yan ẹni ti wọn fẹ gẹgẹ bii gomina ninu gbogbo awọn oludije to gbe apoti ibo.
Ẹwẹ, eyi ni awọn koko ọrọ to yẹ kẹẹ mọ nipa awọn àwọn tí nu n kun lori wọn ju laarin awn oludije to gbe igba idibo yii. Tẹ orukọ eeyan kọọkan lati ka nipa wọn.
Awọn oludije sipo gomina l'Osun
Gómìnà, onímọ̀ nípa ìsúná ni Ọjọ́ orí
ẸnI ọdún méjìdínláàdọ́rin ni
Adegboyega Oyetola ni gómìnà lọ́wọ́lọ́wọ́
Ọmọ bíbí ìlú Iragbiji ní ìjọba ìbílẹ̀ Boripe.
Nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ adójútòfò àti àmójútó ọrọ̀ ajé ni Oyetola ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè onípò kìíní àti ìkejì ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì Eko, UNILAG.
Kí Oyetola tó di gómìnà lọ́dún 2018, òun ni olórí òṣìṣẹ́ ilé ìjọba ìpínlẹ̀ Osun lábẹ́ àkóso Rauf Aregbesola, ẹni tó gba ipò lọ́wọ́ rẹ̀.
Oníṣòwò Ọjọ́ orí
Ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́ta
Ní ọdún 2021 ló kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nípa ìmọ̀ ìdàjọ́ ìwà ọ̀daràn ní ilé ẹ̀kọ́ Atlanta Metrolitan State College, US.
Ní ọdún 2017 ló díje dupò sílé aṣòfin àgbà láti ṣojú ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Osun lẹ́yìn ikú ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Isiaka Adeleke tó sì gbégbá orókè.
Ó tún díje sípò gómìnà ní ọdún 2018 níbi tó ti ṣepò kejì.
Ọmọ bíbí ìlú Ede ni.
Onímọ̀ nípa àwòrán ìkọ́lé.
Ọjọ́ orí: Ọmọ ọdún méjìdínlọ́gọ́ta
Ọmọ bíbí ìlú Osogbo tó wáyé lọ́jọ́ Kẹtàlélógún, oṣù Kejì ọdún 1964 ni.
Ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Obafemi Awolowo ló ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè kìíní nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ nípa àwòrán ìkọ́lé. Bákan náà ló kẹ́kọ̀ọ́ gboyè kejì nípa ìmọ̀ owò ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ilorin àti nípa ìmọ̀ agbègbè ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ibadan. Ó fi ìgbà kan jẹ́ igbákejì alága àpapọ̀ fún ẹgbẹ́ òṣèlú SDP.
Iṣẹ́: Oníṣòwò
Ọjọ́ orí: Ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́ta
Ní ìlú Ile-Ogbo ni wọ́n ti bi.
Ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Obafemi Awolowo ló ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè kìíní nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ okoòwò ètò ọ̀gbìn. Lẹ́yìn èyí ló kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìmọ̀ ìṣàkóso okoòwò ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Navarra, Barcleona, Spain.
Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ètò adójútòfò ní London.
Ó ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Infrastructure Bank Plc, Mutual Benefits Assurance Plc àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀
Iṣẹ́: Onímọ̀ ẹ̀rọ
Ọjọ́ orí: Ọmọ ọdún méjìlélọ́gọ́ta
Ní ìlú Ilobu, ìjọba ìbílẹ̀ Irepodun ni wọ́n ti bí Yusuf Sulaimon Lasun.
Ìmọ̀ ẹ̀rọ Mechanical Engineering ní Lasun kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ibadan fún ẹ̀kọ́ onípò kìíní àti ilé ẹ̀kọ́ fasitì Obafemi Awolowo fún ẹ̀kọ́ onípò kejì.
Óun ni agbẹnusọ ẹgbẹ́ òṣèlú AD lábẹ́ ìṣèjọba Bisi Akande. Bákan náà ló di ipó alága àjọ tó ń rí sí ìdàgbàsókè olú ìlú ìpínlẹ̀ Osun, OSCTDA mú láàárín ọdún 2004 sí 2005.
Láàárín ọdún 2011 sí 2019 ní Lasun ṣojú ẹkún Irepodun/Olorunda/Osogbo/Orolu ní ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin níbi to ti jẹ igbákejì abẹnugan ilé lọ́dún 2015 SÍ 2019.
Lapapọ, orukọ ati ẹgbẹ oṣelu gbogbo awọn oludije naa lọlọkan o jọkan niyii: