History of Osun-Osogbo grove: Mọ̀ síi nípa ìtàn ojúbọ̀ Osun-Osogbo tó ti wà láti bi ẹẹdẹgbẹrin ọdún

Unesco/getty images

Oríṣun àwòrán, Busayo James-Olufade

Gbajugbaja ni ojubọ oriṣa Ọṣun nilẹ Yoruba, ati kaakiri agbaye fun awọn to jẹ olufọkansin fun oriṣa naa.

Ilu Oṣogbo nipinlẹ Ọṣun ni igbo Ọṣun-Oṣogbo naa wa, ni agbegbe Eti Oso Ọṣun.

Odo Ọṣun

Oríṣun àwòrán, osunosogbofestival.com

Ibẹrẹ Igbo/ojubọ Osun

Awọn onimọ nipa ẹsin abalaye ni Naijiria sọ pe o ti le ni nkan bi ẹẹdẹgbẹrin ọdun ti awọn alaalẹ to tẹ ilu Osogbo do, bẹrẹ sii ṣe ọdun Osun Osogbo.

Ọdẹ nla kan, Olutimẹhin, lo jẹ adari awọn eeyan kan to n wa ọna abayọ si ìyàn to mu nibi ti wọn tẹdo si tẹlẹ.

Erongba wọn ni lati kọ ile ti wọn o maa gbe si eti odo Osun, ṣugbọn bi wọn ṣe bẹrẹ si ni ge awọn igi to wa nibẹ, itan sọ pe oriṣa odo naa, Osun, pariwo jade si wọn, o si le wọn kuro nibẹ.

Àkọlé fídíò, Osun Osogbo: Àtáója ní káwọn èèyàn má a bọ̀ wá bọ Ọ̀ṣun lónìí, torí kò ṣe é jígbé,

Lẹyin naa lo sọ fun ẹni to dari awọn eeyan naa, Olutimehin, pe ko ko awọn eeyan rẹ lọ si ibi pataki kan (to di ilu Osogbo).

Osun ṣeleri lati daabo bo wọn, ti yoo si fun wọn ni ọrọ pupọ. Kikii pe ki wọn ma a fun un ni ẹbọ lọdọọdun. Awọn eeyan naa gba lati maa ṣe bẹẹ. Ẹbọ ti wọn ma n fun un, lodi ọdun Osun Osogbo to n waye lọdọọdun bayii.

Ojubọ Ọṣun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lati igba naa si ni ibẹ ti di igbo mimọ nibi ti awọn olujọsin ti n korajọ lati sin jọsin fun.

Oun si ni igbo oriṣa to tobi julọ titi di ode oni ni ilẹ Yoruba.

Ẹgbẹẹgbẹrun eero lo ma n kopa nibi ọdun Ọṣun-Oṣogbo lọdọọdun.

Oríṣun àwòrán, osunosogbofestival.com

Àkọlé àwòrán, Ẹgbẹẹgbẹrun eero lo ma n kopa nibi ọdun Ọṣun-Oṣogbo lọdọọdun.

Ayẹyẹ ọdun Ọṣun-Oṣogbo

Lati mu ẹjẹ ti awọn to tẹ ilu Oṣogbo do, ṣe fun oriṣa Ọṣun ṣẹ, wọn bẹrẹ si ni ṣe ọdun irubọ fun un ni ọdọọdun.

Ẹgbẹẹgbẹrun eero lo ma n kopa nibi ọdun Ọṣun-Oṣogbo lọdọọdun.

Oríṣun àwòrán, osunosogbofestival.com

Ọsẹ meji gbako ni ayẹyẹ ọdun Osun-Osogbo fi ma n waye.

Bi eto ọdun Ọṣun-Oṣogbo ṣe ma n lọ

Àkọlé fídíò, Ọmọ méjì ò sọnù nínú àgbàrá òjò o! Ọ̀tọ̀ lọ̀rọ̀ táa ń pè yín sí - Aráa Ketu

Iwọpopo

Wọn o kọkọ bẹrẹ pẹlu ṣiṣe iyasimimọ ilu, ati ọna to lọ lati aafin Ataoja si igbo Ọṣun, ti wọn n pe ni Iwọpopo. Iya Ọṣun ati baba Ọṣun (Aworo) lo ma n ṣe eto yii.

Àkọlé fídíò, Osun Osogbo: Ọdọọdún ni Àtáója ń gbàlejò gbogbo arugbá lásìkò ọdún Ọ̀ṣun Òṣogbo

Atupa olojumẹrindinlogun

Lẹyin ọjọ mẹta ni wọn o tan atupa kan to ti wa fun ẹẹdẹgbẹta ọdun, ti wọn n pe ni atupa olojumẹrindinlogun.

Itan abalaye sọ pe atupa oloju-mẹrindinlogun naa ti pe ẹgbẹta ọdun laye

Oríṣun àwòrán, osunosogbofestival.com

Àkọlé àwòrán, Itan abalaye sọ pe atupa oloju-mẹrindinlogun naa ti pe ẹgbẹta ọdun laye

Ina atupa yii yoo wa ni titan laarin aago meje irọlẹ si meje owurọ, ti Ataoja ati awsn iyawo tẹ, pẹlu babalawo yoo si jo yiika lẹẹmẹta loju gbogob ara ilu to ba peju si aafin.

Ataoja to ba wa lori oye yoo wure fun ilu Oṣogbo, ati gbogbo awọn to ba kopa nibi ọdun naa
Àkọlé àwòrán, Ataoja to ba wa lori oye yoo wure fun ilu Oṣogbo, ati gbogbo awọn to ba kopa nibi ọdun naa

Iboriade

Lẹyin eyi ni 'Iboriade', to jẹ asiko ti wọn o to ade gbogbo awọn ọba to ti jẹ nilu Osogbo, fun ìre lati ẹnu Ataoja ilu Oosgbo, Arugba Osun, Yeye Osun, ati awọn iya oloriṣa.

Awọn to ba lọ fun ọdun Ọṣun-Oṣogbo ma n lo asiko naa lati gbadura lori ẹdun ọkan wọn
Àkọlé àwòrán, Awọn to ba lọ fun ọdun Ọṣun-Oṣogbo ma n lo asiko naa lati gbadura lori ẹdun ọkan wọn

Arugba Osun, ni omidan ti ko ti ni ibalopọ ri, to ma n ru igba Osun ti wọn ko ẹbọ ti wọn fẹ ẹ gbe fun oriṣa Osun.

Ojuṣe Arugba ju gbigbe igba nikan lọ. O jẹ alarina laarin awọn eeyan ati Osun.

Arugba Ọṣun ko gbọdọ kọsẹ tabi ṣubu, bibẹẹkọ, apẹẹrẹ buruku ni fun un, ati ilu Osogbo.

Oríṣun àwòrán, osunosogbofestival.com

Àkọlé àwòrán, Arugba Ọṣun ko gbọdọ kọsẹ tabi ṣubu, bibẹẹkọ, apẹẹrẹ buruku ni fun un, ati ilu Osogbo.

Lasiko to ba ru igba naa, wọn ma n fi orogbo meji si ni ẹnu, ko ma ba a le sọ awọn nkan to wa ni ọkan rẹ nipa wiwọ igbo Osun.

Ko tan sibẹ o, omidan naa ko gbọdọ kọsẹ tabi ṣubu, bibẹẹkọ, apẹẹrẹ buruku ni fun un, ati ilu Osogbo.

Itan sọ pe nkan buruku ni yoo ṣẹlẹ ni ilu ninu ọdun to ba tẹle.

Arugba Ọṣun ko gbọdọ kọsẹ tabi ṣubu, bibẹẹkọ, apẹẹrẹ buruku ni fun un, ati ilu Osogbo.

Oríṣun àwòrán, osunosogbofestival.com

Sussane Wenger to di Adunni Oloriṣa

Ni nkan bi ọdun 1950, itan sọ pe nkan dẹnu kọlẹ ninu igbo oriṣa Osun-Osọgbo, nitori pe awọn eeyan ko fi bẹ ẹ lọ si awọn ojubọ oriṣa mọ, awọn alawo naa fi ojuṣe wọn silẹ.

Ṣe oju to ba dilẹ ni rorẹ n sọ - bi nkan ṣe ri mu ki awọn eeyan kan bẹrẹ si ni mu ẹja ninu odo naa, wọn ṣe ọdẹ ẹran, koda wọn n ge igi, eyi to jẹ ewọ tẹlẹ.

Adunni Olorisha lo fi opin si awọn iwa ibajẹ to n waye ni inu igbo naa ni nkan bi ọdun 1950.

Oríṣun àwòrán, osunosogbofestival.com

Àkọlé àwòrán, Adunni Olorisha lo fi opin si awọn iwa ibajẹ to n waye ni inu igbo naa ni nkan bi ọdun 1950.

Bayii ni nkan ṣe ri titi ti oyinbo alawọ funfun, ọmọ orilẹ-ede Austria, Sussane Wenger to pada di Adunni Olorisha, fi de si ilu Oṣogbo, to si fi opin si awọn iwa ibajẹ to n waye ni inu igbo naa.

Àkọlé fídíò, Igi Ọ̀pẹ abàmì tó dá ní orí 42 l'Ekiti rèé o, 'bí mo ṣe ríi l'orí mi ń dìde fììì'

Pẹlu iranlọwọ Ataoja ilu Oṣogbo, ati awọn ara ilu, Wenger bẹrẹ eto kan to fi sọri gbigbogun ti awsn to n lo igbo naa lọna aitọ, to si tun ṣe atunṣe ibi mimọ naa.

Lọdun 2005, ajọ UNESCO kede igbo Ọṣun-Oṣogbo gẹgẹ bi ibudo iṣẹmbaye ajogunba, ti pe ni World Heritage Site.