Osun Osogbo: OSUCCIMA ní òun yóò lo ọdún Ọṣun Osogbo pèsè iṣẹ́ àti àgbéga okoòwò aládàáni

Awọn eeyan n lọ si ojubọ Ọsun Osogbo

Oríṣun àwòrán, Osun Osogbo Festival

Nibayii ti ajọdun Ọsun Osogbo n bẹrẹ loni ọjọ Aje pẹlu eto 'Ìwọ́ Popo', ti wọn fi n fọ ilu mọ ni ilana ibilẹ wa, wọn ti gba awọn ileesẹ nlanla nimọran lati fi ọwọ sowọpọ nidi sise agbelarugẹ ajọdun naa.

Adele oludari agba fun ajọ to n ri si eto okoowo, ileesẹ nlanla, eto iwakusa ati ọgbin nipinlẹ Ọsun, OSUCCIMA, Oloye Jide Falọdun lo rawọ ẹbẹ bẹẹ, to si tun woye pe ko si orilẹede to lee goke agba laisi agbega asa rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Falọdun ẹni to woye ọrọ yii lasiko to n gbalejo ileesẹ to n fọnrere ajọdun Ọsun Osogbo fun tọdun yii, Esquire Global, tun fọwọ gbaya pe ajọ naa ti setan lati sugba ijọba ipinlẹ Ọsun ati igbimọ to wa fun agbega asa ni Ọsun lọna ati jẹ ki ajọdun ọdun yii kẹsẹ jari.

Awọn eeyan ninu asọ funfun n lọ si ojubọ Ọsun Osogbo

Oríṣun àwòrán, Osun Osogbo Festival

Atẹjade kan ti Tunde Muraina, tii se oludari ileesẹ naa salaye pe ajọ OSUCCIMA tun ti se agbekalẹ ajọdun miran ti wọn pe ni Community Day Cultural Festival eyi ti yoo wa fun ipese isẹ ati agbelarugẹ awọn olokoowo aladani.

Bakan naa ni Muraina kede pe, gbogbo awọn ileesẹ to ba kopa ninu ajọdun tuntun yii ni yoo ni anfaani fun afihan awọn ọja ati isẹ ọwọ wọn.

Muraina wa rọ ajọ OSUCCIMA lati pese awọn ohun eelo ibaraẹnisọrọ igbalode feto idokowo fun awọn ileesẹ ti yoo fọwọsowọpọ pẹlu ajọ naa, ki wọn lee ba ilana katakara lagbaye fun saa onka ẹgbẹrun ọdun ta wa yii mu.

Arugba ati awọn eeyan to n lọ si ojubọ Ọsun

Oríṣun àwòrán, Osun Osogbo Festival

O ni eyi yoo seranwọ fun awọn asaaju awujọ, asaaju ẹgbẹ oselu, awọn ọmọ Naijiria loke okun, awọn onileese nlanla atawọn olokooowo aladani ti ko lee wa sibi ajọdun Ọsun Osogbo lọdun yii, ni anfaani lati kopa latipasẹ awọn ẹrọ igbalode naa eyi ti yoo dena ẹnawo ati fifi akoko sofo.