Lekki Toll Gate: Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó fajúro lórí ìpolówó tó ṣe àfihàn obìnrin ní ìhòòhò

Oríṣun àwòrán, @LASAAONLINE
Ijọba ipinlẹ Eko ti bẹnu atẹ lu bi ọlọkọ kan ti ṣe afihan awọn obinrin to n jo ni ihoho nitagbangba.
Ọga agba ileeṣẹ to n dari ọrọ to ni ṣe pẹlu sisẹ ipolowo ọja nitagbangba, Bolaji Sanusi lo sọ ọrọ yi ninu atejade kan .
Ọrọ yi ko ṣẹyin fọnran fidio kan to gbode lori ayelujara, nibi ti awọn obinrina kan ti ko wọ aṣọ tin jọ ninu ọkọ kan lopopona ibode Lekki si Ikoyi.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Sanusi ni labẹ akoso Gomina Babajide Sanwo-Olu, ijọba lodi si iwa kankan ti yoo tapo si aṣọ ala ilu Eko, labẹ pe wọn fẹ polowo ọja
''Ko si ẹni ti yoo sa pamọ si abẹ ika kan pe oun n ṣe ipolowo ọja lati ṣe afihan ihoho eleyi ti o lodi si aṣa wa.''
''Ijiya to tọ la o fi jẹ ẹni to ba ni ọkọ yi gẹgẹ bi ofin ti ṣe laa kalẹ.''
Ẹwẹ, Ileeṣẹ ipolowo ọja loju opo Twitter wọn lawọn ti wọgile iwe aṣẹ ileeṣẹ Provision Media System to ni ọkọ naa. Loju opo Facebook wọn ni wọn fi ọrọ yi si.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Kini awọn eeyan n sọ nipa fọnran fidio yi?
Lojuopo Twitter,orisisisi iriwisi lo ti tẹle fọnran fidio yi to ṣe afihan awọn obinrin to n jo ni ihoho ninu ọkọ kan.
Bi awọn kan ti ṣe n ṣe n bu ẹnu atẹ lu iwa yi lawọn miran n ni kii ṣe oun toju o riiri.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2

End of X post, 3

End of X post, 4
Labẹ ofin ipinlẹ Eko, ẹni kẹni to ba kopa ninu afihan ti ko bojumu yala pẹlu ẹlomiran, tiṣẹ si ofin, ti ẹni naa si le ṣẹwọn ọdun mẹta ti ile ẹjọ ba ni o jẹbi ẹsun naa.