Moesha Boduong: Gbogbo obìnrin nílò ọkùnrin tí yóò máa tọ́jú wọn

Oríṣun àwòrán, Moesha Boduong/Facebook
Òsèré ọmọ Ghana kan to sọ wípé gbogbo obìnrin nílò ọkùnrin tí yóò máa tọ́jú wọn ti dá àríyànjiyàn mi sílẹ̀ nílu tó sì ti fẹ ọ̀rọ̀ fifi ipá bá ni lò pọ̀ lójú káàkiri orílẹ̀èdè.
Moesha Boduong ní ètò ọrọ̀ ajé burú jáì ní orílẹ̀èdè náà tó bẹ́ẹ̀ tó fi jẹ́ wípé wọ̀n fi ipá mú u ní àjọsepọ̀ pẹ̀lú odidi baálé ilé kan kó lè báà r'ówó ná.
Boduong sọ fún akọ̀ròyìn kan wípé "o sáà nílò ẹnìkan láti máa tọ́jú rẹ. Oò lè pa owó púpọ̀ gẹ́gẹ́ bí obìnrin níbí".
Láti ìgbà náà ni àwọn èèyàn ńlá ní Ghana ti ńtàbùkù bá Boduong tí àwọn ènìyàn sì ńfojú rẹ̀ wò ó.
Ó ti wá tètè tọrọ àforíjì wípé, ìrírí òun kìí se àpẹẹrẹ ohun tó ńsẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ idílé.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Sùgbọ́n èyí ńta ni lára ní irú orílẹ̀èdè ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà níbi tí fífi ipá bá ni lopọ̀ ti fẹ jú síbẹ̀ síbẹ̀, wọ̀n kìí fibẹ̀ẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀.
Láìpẹ́ yìí ni orílẹ̀èdè Nàìjíríà ńsọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sùn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin kan tó ká ọ̀rọ̀ láàrín òun àti olùkọ́ fásitì sílẹ̀ nígbà tó mbèrè fún ìbálòpọ̀ gẹ́gẹ́ bíi pàsípàrọ̀ máàkì dáradára.
Akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ wípé ó já òun kulẹ̀ nínú ẹ̀kọ́ nígbà tí òun kò gbà fún un.
Ní orílẹ̀èdè Ghana, wọ́n ti se ìfilọ́ọ́lẹ̀ ìwádìí tí yóò máa se ọ̀fintótó àwọn ọmọ̀ ilé ìwé girama ní ààrin gùngbùn Ashanti tí àwọn olùkọ́ wọ́n ńfipá bá lò pọ̀.
Asojú ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ́ ọmọnìyàn kan tó ńjẹ́ Pepper Dem, Maame Akua sọ wípé àgbára àìdọ́gba ọkùnrin s'óbìnrin wà ní orílẹ̀èdè Ghana tí wọ́n gbùdọ̀ wá ojútùú sí.
Ó ní ìwa yíì ti wọ́pọ̀ jù tí àwọ́n olùkọ́ wọn sì ńbá wọn lò pọ̀.
Ẹ̀wẹ̀, George Ossom Batsa tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀sìn ní fásitì Ghana sọ wípé ó yẹ kí wọ́n gbóríyìn fún Boduong fún òtítọ́ rẹ̀ nítorí nípa èyí ni wọ́n fi lè kojú àwọn àìdáa tó wà láwùjọ́.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:












