Fásitì OAU ní ohùn ọ̀jọ̀gbọ́n Richard Akindele ni wọ́n ká sílẹ̀
Àwọn aláṣẹ fásitì Ọbafẹ́mi Awólọ́wọ̀ ní Ìlú Ilé ifẹ̀, OAU ti ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ohùn un ọ̀jọ̀gbọ́n Richard Akindele, ti ẹ̀ka ìmọ̀ nípa ìṣirò owó tí wọ́n ní, o ń bèèrè fún ìbálòpọ̀ ìgbà máàrún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ́wọ́ ọ̀kan
lára àwọn akẹ́kọ́bìnrin tó fìdírẹmi nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ kan ní ó wà nínú fọ́nrán ohùn àkásílẹ̀ tó ń jà ràìn-ràìn káàkiri báyìí.
Àkásílẹ̀ àjọsọ ọ̀rọ̀ láàárín akẹ́kọ́bìnrin ọ̀hún àti ọ̀jọ̀gbọ́n Richard Akindele pẹ̀lú ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ lori bí ọ̀jọ̀gbọ́n náà ṣe ń bèèrè fún ìbálòpọ̀ lọ́wọ́ akẹ́kọ́bìnrin náà ti di èròyà wá wòó lóríi ìkànnì ayélujára.
Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ oríi ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lú BBC lórí ètò oríi redio kan nilu London, alukoro fásitì Ọbafẹ́mi Awólọ́wọ̀ ní Ìlú Ilé ifẹ̀, OAU, Ọ̀gbẹ́ni Abíọ́dún Ọláńrewájú ni àwọn aláṣẹ fásitì náà ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ohùn rẹ̀ ni.

Oríṣun àwòrán, @OfficialOAU
Bákannáà ló tún ṣàlàyé rẹ̀ pé wọn tí kọ ìwé 'wá wí tẹnu rẹ' sí ọ̀jọ̀gbọ́n Akíndélé lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ọ̀gbẹ́ni Abíọ́dún Ọláńrewájú ni àwọn aláṣẹ fásitì náà yóò gbé ìgbésẹ tó bá yẹ lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ tí wọ́n gbé kalẹ̀ bá ti jáde pẹ̀lú àbọ̀ ìwádìí rẹ̀.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Richard Akindele tilééwé fásitì OAU Ile-Ife, ni ariwo rẹ̀ gbòde kan pé ó bèèrè láti bá akẹ́ẹ̀kọ́ obìnrin lájọṣepọ̀ fún ìgbà máàrún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti fún ní máàkì.

Oríṣun àwòrán, Facebook/@OfficialOAU
Ní báyìí, àwọn aláṣẹ fásitì náà ti gbé ìgbìmọ̀ ẹlẹni-márùn ún kalẹ̀ láti ṣèwaàdí sí ọ̀rọ̀ náà.
Ọ̀sẹ̀ kan ni ìgbìmọ̀ náà ní láti fi jábọ̀ iṣẹ́ rẹ̀.













