OPC: Àwọn àgbà ilẹ̀ Yoruba ní OPC àti Boko Haram kò jọra, kí wọn má fi ewúrẹ́ wé ẹkùn

Awọn ọmọ ẹgbẹ OPC gbe asọ idamọ wọn lọwọ

Oríṣun àwòrán, OPC

Awọn agbagba ilẹ Yoruba kan ti sọ pe, bi ẹni fi ewurẹ we ẹkun ni ki eeyan maa fi ẹgbẹ OPC we ẹgbẹ agbesumọmi Boko Haram jẹ, nitori wọn ko jọ ara wọn.

Ṣaaju ni olórí àwọn ọmọ ogun Naijiria tẹlẹ, Abdulrahman Dambazau ti kọkọ sọ pe ọkan naa ni ẹgbẹ IPOB, OPC ati Boko Haram nitori afojusun awọn ẹgbẹ naa ni lati da ogun abẹle silẹ ni Naijiria.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Ọmọwe Taye Ayorinde to jẹ alaga ẹgbẹ Yoruba World Assembly sọ pe, agbesumọmi gan ni Dambazau funra rẹ fun afiwe to ṣe ninu ọrọ to sọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ayorinde ni ko yẹ ki ẹni to jẹ ologun maa fi OPC we Boko Haram nitori awọn eeyan to n bọwọ fun ofin ni awọn ọmọ ẹgbẹ OPC jẹ.

O ni "Nigba miran eeyan a maa ba ọrọ agọ nibi ti yoo ti ro pe oun yoo ba ọrọ ọgbọn, bawo ni eeyan ṣe maa fi ewurẹ we ẹkun?"

Taye Ayorinde

Oríṣun àwòrán, Taye Ayorinde

"Awọn ọmọ wa lo wa ninu ẹgbẹ OPC, ṣugbọn ni ti Boko Haram, awọn Dambazau yii lo mọ awọn to wa nibẹ nitori awọn naa lo lo wọn lasiko eto idibo."

Ayorinde ṣalaye pe ko mu ọgbọn dani ki eeyan maa fi OPC to n ṣiṣẹ abo we awọn Boko Haram to n wu iwa ipaniyan ati ijinigbe.

Ẹwẹ, Alagba Sehinde Arogbofa naa da si ọrọ ọhun nigba to sọ fun BBC pe, iyatọ gedegbe lo wa laarin ẹgbẹ OPC ati Boko Haram.

O ni ilu Kano ni ẹni to da ikọ agbesumọmi Boko Haram ti bẹrẹ, ki wọn to le lọ ilu Maiduguri nibi to ti gbilẹ.

Sehinde Arogbofa

Oríṣun àwòrán, Sehinde Arogbofa

Arogbofa ṣalaye pe, Boko Haram lodi si iwe kika ati iwa ọlaju, ṣugbọn OPC ko ṣe bẹẹ, niṣe ni wọn n ja fun igbala awọn ti wọn n fi iya jẹ lawujọ.

O tẹsiwaju pe iwa jagidijagan pẹlu ibọn ni awọn Boko Haram fi n ṣọṣẹ, ko si ṣe ṣafiwe awọn OPC to jẹ pe awọn ọmọwe lo da ẹgbẹ ti wọn silẹ.

Alagba naa fi kun pe "Boko Haram atawọn ti ko fẹ itẹsiwaju Naijiria lo jọ n ṣiṣẹ papọ, ṣugbọn niṣe ni OPC n wa ilọsiwaju Naijiria."

Arogbofa pari ọrọ rẹ pe "awọn ẹlẹsin Musulumi lo kun ẹgbẹ Boko Haram nigba ti OPC ko ni nnkan ṣe pẹlu ẹsin, idi ree ti awọn Musuli, Kristeni atawọn ẹlẹsin abalaye ṣe wa nibẹ."

Àkọlé fídíò, Female Car Painter: Èmi ní obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò máa ṣiṣẹ́ akunmọ́tò ní Ibadan

O ni "eyii ti ẹ ni Dambazau sọ yẹn kii ṣe ara ẹ o, ko sọ daa o, ẹ o le fi aja we ẹkun o."

Ẹwẹ, onimọ nipa eto abo kan, Arákùnrin Akin Adeyi sọ pe Dambazau ko ni imọ lo jẹ ko maa fi OPC we Boko Haram nitori wọn jina si ara wọn.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ara iṣoro ti Naijiria ni niyẹn nitori wọn ko sọ oju abẹ niko.

Adeyi sọ pe idojuti nla ni ọrọ naa jẹ fun Dambazu gẹgẹ bii ologun ati ipo to di mu ni Naijiria nitori ibi ti OPC ati Boko Haram ti n bọ ati iwa wọn kii ṣe ọkan naa.

Amin iyasọtọ kan

Ìjà parí! Ẹgbẹ́ dókítà dáwọ́ ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ mẹ́wàá dúró

Aworan awọn dokita Naijiria

Oríṣun àwòrán, United States Africa Command

Ẹgbẹ awọn dokita lorileede Naijira ti so iyanṣẹlodi ti wọn gunle rọ lẹyin ọjọ mẹwaa.

Dokita Uyilawa Okhuaihesuyi, tii se aarẹ ẹgbẹ awọn Dokita lo fidi ọrọ yi mulẹ fawọn akọroyin.

O ni ''ni nkan bi wakati kan sẹyin (lọjọ Abamẹta) la so iyanṣẹlodi naa rọ ni idahun si ẹbẹ awọn ọmọ Naijiria.''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O tẹsiwaju pe ''ijọba ti dahun sawọn ibeere kọọkan ninu ohun taa beere lọdọ wọn''

Ṣaaju ni ijọba Naijriia ti buwọlu iwe adehun kan pẹlu awọn ẹgbẹ dokita Naijira-igba keji ree ti wọn yoo buwlu iwe adehun laarin ọsẹ meji.

Aworan ile ìwòsan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn Dokita ati awọn osise ilera miran ko gba dede iye owo kannáà.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan, Minisita feto igbaniṣiṣẹ ni Naijiria, Dokita Chris Ngige sọ pe ''ipade taa ṣe lọjọ Abameta waye ki a baa le ṣe atunse si adehun taa kọkọ buwọlu pẹlu awọn Dokita''

O ni nitori eleyi awọn ti gbe igbimọ ẹlẹni marun un kan kalẹ, ti yoo mojuto awọn oṣiṣẹ ti ọrọ yii kan, taa si fun wọn ni ọjọ mẹta lati gbe orukọ wọn jade.

Lọjọ kinni oṣu Kẹrin lawọn ẹgbẹ dokita wọn yi gunle iyanṣẹlodi.

Àkọlé fídíò, Cattle Ranching: Ẹ wo Fulani darandaran to tako àṣà dída màálù kiri lójú pópó

Ohun ti ẹgbẹ naa n beere lọwọ ijọba pọ, to fi mọ pe ki ijọba san owo oṣu ti wọn jẹ awọn dokita lai da ẹnikankan si.

Wọn tun beere fun afikun ida aadọta lori iye owo ajẹmọnu gbogbo oṣiṣẹ ilera, to fi mọ sisan gbese owo moriya iṣẹ Covid-19 fawọn to n ṣiṣẹ ni ile iwosan ipinlẹ to fi mọ awọn nkan miran.