Igun OPC: OPC ti sọnù, àwọn èèyàn ń sá fún wa láì fẹ́ darapọ̀ mọ́ wa

Àkọlé fídíò, Igun OPC: OPC ti sọnù, àwọn èèyàn ń sá fún wa láì fẹ́ darapọ̀ mọ́ wa

Omi alaafia ẹgbẹ ajijagbara OPC to n daru lati ọjọ pipẹ ko ti toro bayii nitori ipapoda oludasilẹ ẹgbẹ naa, Frederick Faseun.

Nigba ti wọn n ba ikọ BBC Yoruba sọrọ, Rasak Arogundade, to jẹ aarẹ fun igun OPC kan, New Era sọ pe, ti kii ba se ọjọ ori ti Ọlọrun fi kẹ Faseun ko to jade laye, awọn eeyan ko ba ni Ọshinbọtẹ Oodua, tii se aarẹ tuntun ti wọn yan lọjọ keji ti Faseun mi kanlẹ, lo seku paa, nitori iyansipo rẹ ti ya ju.

Lero ti Lanre Adesọpe, tii se aarẹ fun igun OPC Reformed, oun naa fara mọ pe, aarẹ tuntun ti wọn kede rẹ kii se ọmọ ẹgbẹ OPC.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni arijo-ariyọ lawọn eeyan maa n ki awọn ọmọ ẹgbẹ OPC tẹlẹ, amọ lasiko yii, nse ni aye n sa fun awọn, ti wọn ko si fẹ dara pọ mọ OPC mọ.

Wayi o, igbakeji fun aarẹ OPC, Ọtunba Wasiu Afọlabi ni, ojulowo ọmọ ẹgbẹ OPC ni Ọshibọtẹ, tii se aarẹ tuntun, ti iyansipo rẹ si jẹ asọtẹlẹ Faseun ko to jade laye.

Afọlabi salaye pe, ti awọn ko ba tete yan Ọshinbọtẹ sipo, o seese ki omi ti tẹyin wọ igbin lẹnu.