Tọkọ-taya Aràrá: Àwọn èèyàn máa ń wò wá, ta bá fa ọwọ́ ara wa ní títì

Àkọlé fídíò, Tọkọ-taya Aràrá: Àwọn èèyàn máa ń wò wá, ta bá fa ọwọ́ ara wa ní títì

John Adewuyi, ẹni to jẹ arara, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni, aye ti ro pe oun ko lee ri aya fẹ́, amọ oun dupẹ pe Ọlọrun fun oun ni aya rere, ti o n tọju oun daada.

Adewuyi ni ifẹ maa n tan isoro, ẹkun, pẹlu isẹlẹ aidaa to ti waye sẹyin, ti yoo si tun mu ayọ̀, ibukun ati igbega wọnu ile wa.

Ninu ọrọ ti aya rẹ, o ni kii se owo ni ọkọ oun fi fa oju oun mọra, tori inu yara kansoso ni o n gbe ti oun fi fẹ, ti ko si ni kẹkẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fikun pe inu oun maa n dun lati ba ọkọ oun rin ni titi, tawọn yoo si fa ara awọn lọwọ, bi o tilẹ jẹ pe awọn eeyan yoo maa fi ọwọ tọ̀ ara awọn lasiko tawọn ba n kọja ni popo.