Sunday igboho: Ẹgbẹ́ Fulani fárígá pé kí wọn dá Seriki padà sí Igangan pẹ̀lú owó ìtanràn

Ẹgbẹ awọn ọmọ bibi Fulani kan, Gan Allah Fulani Developmet Association,GADFAN, ti kesi ijọba Naijiria, lati san owo itanran fun Seriki Fulani ti wọn si nipo pada kuro nilu Igangan.
Bẹẹ ni wọn sọ pe ki ijọba fofin mu Sunday Igboho, to ṣagbatẹru ikọlu si Seriki, eyiun Alhaji Salihu Abdulkadir nilu Igangan.
Ẹgbẹ GADFAN fi ọrọ yii lede lasiko ti wọn ṣe abẹwo si Seriki Abdulkadir lọjọ Abamẹta ni ilu Ilorin, nibi toun ati mọlẹbi rẹ fori pamọ si.
- Wo ohun tí BBC rí nílé Seriki Fulani ní Igangan
- Gbèǹdéke ku àsìkò díẹ̀, Seriki Fulani fohùn ránṣẹ́ sí Sunday Igboho
- Ta bá gba Seriki Fulani padà sí Igangan, a fi ọwọ́ ara wa, pa ara wa ni - Aráàlú
- Sunday Igboho wà lọ́nà Ibarapa, Seriki Fulani ní àwọn kó níbiì lọ, àrọ̀wà ló kù fúnwà
- Tó bá jẹ́ pé à ń gbé AK47, ìgbà táwọn àgbẹ̀ dáná sun ilé wa, ṣé aò ti ní pa wọ́n dànù? -Ọmọ Seriki Fulani
- Mo ń padà bọ̀ ní Ibarapa lọ́sẹ́ tó ń bọ̀- Igboho; Gbogbo dúkìá mi làwọn ọmọ Igboho jó tán- Seriki Fulani
Alaga ẹgbẹ naa Sulaiman Yakubu ati akọwe, Ibrahim Abdulahi sọ ninu atẹjade to tẹ BBC lọwọ pe, ki ijọba fi ọlọpaa mu Sunday Igboho, ko si foju wina ofin ni kiakia.
''O ya wa lẹnu pe titi di ba ṣe n sọrọ yii, fanda-fanda ni Igboho n rin kaakiri bi igba pe nkankan ko tiẹ ṣẹlẹ''
''Nitori naa ẹgbẹ GADFAN n kesi ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Oyo, lati ri pe wọn se deede pẹlu Alhaji Seriki ati awọn eeyan rẹ nipa mimu Igboho. ''
Wọn fi kun pe ki ijọba ri pe wọn tara san owo gba ma binu fun awọn to padanu dukia, ki wọn si jẹ ki wọn pada si ile wọn lalaafia nilu Igangan.
Atẹjade naa sọ bakan naa pe, ikọlu tawọn eeyan Igboho ṣe si ile Seriki ni Igangan lo mu ko padanu ''dukia ati awọn nkan ọsin ti owo rẹ wọ ẹẹdẹgbẹta miliọnu Naira''
Ẹgbẹ naa sọ pe, awọn yoo lo gbogbo ọna labẹ ofin lati ri pe awọn gba ẹtọ Seriki fun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àlàyé rèé lórí ikú tó pa ọmọ Ronke Oshodi Oke
- Wo ọ̀pọ̀ àǹfààní tó wà nínú eré ìdárayá Squash fún àgbéga ìlera àti ọrọ̀ ajé rẹ
- Òjò owó ń rọ̀ fún abilékọ ẹlẹ́sẹ̀ kan tó n ta pure water lójú pópó
- Ẹ wo ìdí tí omije fi bọ́ lójú Pasuma níbi ìgbéyàwó ọmọ rẹ̀ obìnrin
- Ikọ̀ aláàbò Ebube Agu bẹ̀rẹ̀ nílẹ̀ Igbo, tó túmọ̀ sí Amotekun
- Agbára ahọ́n ta fi n pe ara wa ní olóríire ló jẹ́ ká gba ẹ̀bùn ilé - Olorì Aláàfin méjì
- Ẹ̀tanú ní kó jẹ kí wọ́n gbé ipò ààrẹ fún MKO Abiola - Obasanjo
- Alaafin kọ́lé tuntun fún ọ̀kan lára Olorì rẹ̀ ní Ibadan, ariwo sọ
- Davido, Pasuma àti Yinka Ayefele dábírà lópin ọ̀sẹ̀, aráyé múgbe bọnu
- Yorùbá sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Arewa lórí bó ṣe fẹ́ àtúntò Nàíjíríà àmọ́ tó tako pínpín ipò ààrẹ
Wọn ni ''a ti n ba awọn agbẹjọrọ sọrọ, ti a ko si ni pẹ gbe ọrọ lọ si ile ẹjọ ti ijọba ko ba ṣe nkankan si''

Oríṣun àwòrán, GADFAN




















