Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ni ọwọ́ tẹ̀ lórí ìjínígbé ní Oke Ogun- Seriki Fulani
Kii ṣe pe mo n da si ọrọ ti ko kan mi, ọrọ ijinigbe yii kan mi pupọ- Oloye Sunday Adeyemo

Wọn ni mi o si ni ijọba, bẹẹ mo n da si nkan ti ko kan mi ṣugbọn ọrọ awọn ẹbi mi to jẹ Yoruba yii kan mi gbọngbọn.
Oloye Sunday Adeyemọ ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho ba BBC Yoruba sọrọ ilẹ kun lori gbendeke to fun awọn iran Fulani ni Oke Ogun.
- Ẹ wo ohun tí Seriki Fulani sọ fún gómìnà Makinde nípa Sunday Igboho
- Gbogbo ẹ̀yin Fulani darandaran tó wà ní ìgbó ìjọba ní Ondo, ọjọ méje lẹní láti pòórá - Gomina Akeredolu
- Iyaafin Fọlakẹ Arẹmu, Orisabunmi ti wọ káà ílẹ̀ sún
- Ọkọ̀ agbépo bẹ́ntiról kankan kò gbọdọ̀ gun afárá nípínlẹ Ogun mọ́ - Gomina Dapo Abiodun
- Seyi Makinde pàṣẹ fún àwọn ọlọ́pàá láti wádìí Sunday Igboho lórí gbèǹdéke tó fún àwọn Fulani
Ti ijọba ti awọn eeyan dibo yan ko ba dide lati pese aabo fun wọn, nigba to ba ya, awọn ara ilu a jijangbara lati gba ara wọn silẹ.
Sunday Igboho ni o to gẹ fun awọn Fulani to n pa awọn ara ilu to tun gba owo gọbọi lọwọ wọn leyin ijinigbe.
O mẹnuba awọn bii dokita Fatai ti awọn Fulani ti pa lori oko baba rẹ ni Ibarapa.

Seriki Fulani ni Oke Ogun, alhaji Saliu Abdulkadir naa sọrọ ilẹ kun.
O ni awọn ti ọwọ tẹ lori ijinigbe wa lati ipinlẹ Zamfar ati Kebbi pe kii ṣe awọn gangan.
O tun sọ nipa ibudo iwakusa to wa ni Oke Ogun to yẹ ki ijọba mojuto lai faaye gba awọn ti ko yẹ nibẹ.

Alhaji Sallu ni koda, wọn n ji maalu awọn gbe, wọn tun n ji awọn fulani gan gbe lai ki n ṣe Yoruba nikan lagbegbe naa.
Sunday Igboho ni inu awọn Oba Alade gan dun si igbese oun yii nitori pe ẹru n ba wọn ṣugbọn o ti su awọn Ọba naa ni.
- Fulani kìí ṣe ajínigbé! Akeredolu kò ní ká pòórá nínú igbó ìjọba l'Ondo, ohun tí Gómìnà sọ rèé...- Miyetti Allah
- Ta ni Mohammad Buba Marwa tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọ̀gá àgbà àjọ NDLEA?
- Kíní Kọmíṣọ́nnà Ọlọ́pàá, mẹ̀kòó ṣe tí wọ́n fi rí ẹ̀wọ̀n gbére he ní Ekiti?
- Bí ẹ bá tó bẹ́ẹ̀ ẹ pàdé mi l'Òjé- Makinde; Wọ́n ń tàn Ẹ́ bí àbẹ́là- APC


