Sunday Igboho vs Fulani : IG pàṣẹ pé kí Kọmísọ́nnà Oyo mú Igboho wà sí Abuja láti fojú bá ilé ẹjọ́

Aworan ọga ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, NIGERIA POLICE

Ọga patapata ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti paṣẹ pe ki Kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Oyo, arabinrin Ngozi Onadeko mu Sunday Igboho to l'oun n ja fun ẹtọ ati isọkan ilẹ Yoruba.

Agbẹnusọ aarẹ Buhari, Garba Sheu lo fidi ọrọ yi mulẹ lasiko to n sọrọ lori eto BBC Hausa kan ti wọn pe ni: ''Ra'ii Riga ''.

O ni oun ṣẹṣẹ ba ọga ọlọpaa, Mohammed Adamu sọrọ tan ni to si ni oun ti paṣẹ ki kọmiṣọnna Oyo mu Igboho wa si Abuja.

Lẹnu ọjọ mẹta yi ni orukọ Sunday Igboho ti gbode kan paapa lori ayelujara lẹyin to ṣabẹwo si ilu Igangan to si fi gbendeke ọlọjọ meje lelẹ fawọn Fulani ilu naa lati kuro nibẹ.

Bẹẹ lo kesi gbogbo awọn Yoruba ni Oyo ati ipinlẹ mii lati gberasọ tako awọn Fulani ọdaran ajinigbe to n da omi alaafia ilẹ Yoruba ru.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

Malam Garba Shehu ṣalaye pe igbesẹ awọn to n da omi laafi ilu ru jẹ ipenija fun ijọba nitori bi awọn ti wọn lawọn n ja fun ẹtọmọniyan yi ṣe n kọdi ijọba.

O ni aṣẹ to wa nilẹ lati ọdọ ọga agba ọlọpaa ni pe ki wọn gbe Sunday Igboho lọ si Abuja ki wọn si lọ ṣẹjọ rẹ nibẹ.

Saaju ni ọṣẹ yi ni Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu naa ti fun awọn darandaran Fulani lọjọ meje ki wọn kuro ninu igbo ipinlẹ naa.

Ọrọ yi da fakinfa silẹ ti aarẹ Buhari si kilọ fun un lati ma ṣe danwo.

olye sunday igboho at gomina Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, BBC/Seyimakinde

Ìjọba Oyo korò ojú sí ìròyìn tó ń jáde pé káwọn èèyàn Ibadan ó gbélé nítorí Igboho

Ninu atẹjade kan ti kọmiṣọna feto iroyin ati ọrọ aṣa ni ipinlẹ Ọyọ, Ọmọwe Wasiu Ọlatunbọsun fi sita ṣalaye pe wọn kan fẹ fi ohun akasilẹ naa ko awọn eeyan laya jẹ ni.

Ohun akasilẹ naa, ninu eyi ti arabinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Rẹmi lati ilu London to n ke sawọn eeyan ilu Ibadan lati joko si ile wọn ti n lọ kaakiri.

Amọṣa kọmiṣọnna feto ẹkọ nipinlẹ Ọyọ ni ara ọna lati ta ẹrẹ si aṣọ ala ijọba to wa lode ni ipinlẹ Ọyọ ni, ati pe ọgbọn ati ba igbesẹ ati ilakaka ijọba lori ọjọ abo loju jẹ ni.

O wa rọ awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ, paapaa julọ awọn olugbe Ibadan lati maa ba iṣẹ oojọ wọn lọ laisi wahala tabi ibẹrubojo rara.

Ijọba ipinlẹ Oyọ ti rọ awọn eeyan lati keti ọgbọin si iroyin ati ohun akasilẹ to n lọ kaakiri.

Ohun naa kilọ pe ki awọn olugbe ilu Ibadan o joko sile ni ọjọ Ẹti ọjọ kejilelogun nitori gbendeke ọjọ meje ti Sunday Igboho fun awọn Fulani lagbegbe Ibarapa, eleyi to pari lọjọ naa.

Àkọlé fídíò, LASTMA Yesufa: Àwọn dókítà gbìyànjú lórí ojú mi ṣùgbọ́n...

Seyi Makinde pàṣẹ fún àwọn ọlọ́pàá láti wádìí Sunday Igboho lórí gbèǹdéke tó fún àwọn Fulani

Ọ̀rọ̀ n ba ọ̀rọ̀ bọ́ lori Fulani ati Igboho.

Pẹlu bi ariwo ṣe n lọ lọtun losi lori gbendeke ọjọ meje ti Oloye Sunday Adeyẹmọ, fun awọn Fulani lagbegbe Ibarapa oke ogun lati kuro lori ilẹ nibẹ:

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa: Alagba Ajibola láti Fakunle ní olùkọ́ wa lórí ètò ìró lónìí

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde ni oun ko mọ nipa igbesẹ tabi ọrọ ti eekan ọmọ Yoruba naa sọ.

Oloye sunday Adeyemọ yii ti ọpọ mọ si Sunday Igboho lo ni iṣẹ ibi ti awọn Fulani n ṣe ni Oke ogun ti pọ ju.

Igboho ni o to gẹ, ki onikaluku gba ilu ẹ lọ.

Gomina Makinde ni oun si ti paṣẹ fun awọn agbofinro lati bẹrẹ si nii wadi oloye Sunday Igboho lori ọrọ to sọ naa.

Gomina Makinde ṣalaye pe ko si ẹni to fi iṣẹ ran Oloye Sunday Igboho lati lọ jẹ fun awọn fulani naa.

O ni pe gẹgẹ bi iṣejọba to ko akoyawọ, gbogbo ẹya ati ede ni aye gba labẹ ofin ni ipinlẹ Ọyọ ati pe ẹfọ ko lee le ẹfọ lawo.

Nigba ti BBC kan si ijọba ipinlẹ Oyo lori ọrọ yii, agbẹnusọ Seyi Makinde sọrọ ilẹ kun.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, agbẹnusọ fun gomina Seyi Makinde, Ọgbẹni Taiwo Adisa ṣalaye ipo gomina Makinde lori ọrọ naa.

Àkọlé fídíò, America Inauguration Joe: Wo àwọn eré orí ìtàgé tí Donald Trump ṣe kó tó fi ipò aàrẹ sílẹ̀

O ni pe Gomina Makinde ti ran ikọ kan lọ si Gaa awọn Fulani naa lati lọ fi wọn lọkan balẹ pe ko si mimi kan to lee mi wọn lẹsẹ ni ipinlẹ Ọyọ.

Makinde ni ipinlẹ Oyo wa fun tẹrutọmọ to fẹ lati gbe igbe aye alaafia.

Bakan naa lo kilọ fun awọn Fulani ati Yoruba pe irẹpọ lo ṣe pataki lasiko yii ni Naijiria.

Àkọlé fídíò, BBC findings on lekki shooting: Ẹ wa wo àwọn tó ṣì ń wá ẹbí wọn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ End SARS 2020

O ni ijọba ipinlẹ Ọyọ ko wa lẹyin iwa ẹlẹyamẹya

" Yatọ si pe ijọba ipinlẹ Ọyọ ko lọwọ sii, wọn ti paṣẹ ki awọn agbofinro waa kan lati beere ohun to ri lọbẹ to fi waaru ọwọ. Lẹyin ti wọn ba ti fọrọ waa lẹnuwo yoo lee sọ ohun to ri to fi dan iru iwa bẹẹ wo."

O ni Oloye Sunday Igboho fẹ da wahala silẹ lagbegbe Oke Ogun ati ẹkun Ariwa ipinlẹ Ọyọ ni, ti ijọba ko si gbe lẹyin rẹ tabi mọ si awọn igbesẹ rẹ naa.