Police vs Gang clash in Kaduna: Ọlọ́pàá mẹ́rin kú, ọ̀kan dàwátì níbí ìkọlù tó wáyé ní Birnin-Gwari ní ìpínlẹ̀ Kaduna

Oríṣun àwòrán, @Nigeria Police
Awọn agbofinro ti fidiẹ mulẹ fun ileeṣẹ iroyin BBC pe o kere tan ọlọpaa mẹrin lo padanu ẹmi wọn nibi ikọlu ọjọ Ẹti.
Ikọlu naa waye larin awọn agbofinro ati awọn agbebọn ni agbegbe Birnin Gwari ni ipinlẹ Kaduna ni ariwa Naijiria.
Koda, alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa, Frank Mba ni awọn ṣi n wa ọlọpaa kan to dawati nibi iṣẹlẹ naa.
Mba ṣalaye pe awọn agbebọn naa dena de awọn agbofinro lọna ni nibi ti o le ni ọgọrun un wọn fi kọlu awọn agbofinro lasiko ti wọn n padabọ lati ibi ti wọn ti lọ ṣiṣẹ ni ipinlẹ Niger
Bakan naa ni awọn ọlọpaa ni irọ ni pe awọn agbebọn ti ji olopaa mejidinloguin gbe ni Kaduna.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn agbofinro mẹrindinlogun lo wa nibi ikọlu naa ati oku ọlọpaa mẹrin ni awọn ri gbe kuro nibẹ pẹlu ibọn wọn.
Ọlọpaa mọkanla ni wọn ye e nigba ti wọn ṣi n wa ọlọpaa kan to dawati nibẹ ni eyi ti awọn ko tii le sọ nipato ohun to ṣẹlẹ sii.
Ṣaaju ni awọn ọlọpaa ti fidi iṣẹlẹ mii mulẹ ni Kaduna to mu ẹmi eeyan marun un, o kere tan lọ.
Ikọlu yii lo mu ẹmi iya arugbo ẹni ọgọrin ọdun kan lọ ati olori ileto kan ati awọn miran.
Kọmiṣọnna fun aabo abẹlẹ nipinlẹ Kaduna, Samuel Aruwan ṣalaye pe awọn agbebọn naa dojule agbegbe Giwa, Igabi ati Chikun.
Sugbọn wọn ko tii le sọ nipato awọn ti wọn wa nidi ikọlu opin ọsẹ yii.
Ni ibẹrẹ ọsẹ to kọja ni wọn ji eniyan mejidinlogun gbe laiyọ awọn ọmọ ọwọ ati abiyamọ silẹ ni abule kani Birnin-Gwari ni Kaduna.
- Wo àwọn ìṣesí ojoojúmọ́ mẹ́wàá tó le ṣàkóbá fún ọpọlọ rẹ
- Opral Benson, ẹni ti oge ṣíṣe sọ di gbajúmọ̀ àti Yeye Oge ìlú Eko
- Ọjọ́ orí wo ló yẹ kí ikùn ẹ̀dá bẹ̀rẹ̀ sí tóbi?
- Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ńlà lọ́sẹ̀ tó kọjá tó fi mọ́ bí Covid-19 ṣe gbẹ̀mí èèyàn 23 lọ́jọ́ kan ṣoṣo
- Àbámọ̀ ni yóò gbẹ̀yin ẹgbẹ́ ''Association of Stingy Men'' tí kò fẹ́ náwó f'óbìnrin- Akeugbagold




















