Association of Stingy Men: Akeugbagold ní àpẹẹrẹ wèrè díẹ̀díẹ̀ ni k'ẹ́ni tó lówó láhun sí obìnrin

Oríṣun àwòrán, Twitter/ITS DON JAZZY AGAIN
Ẹ lọ ṣọra yin o, gbogbo ẹyin ti ẹ n pe ara yin ni ẹgbẹ awọn ọkunrin alahun, Association of Stingy Men.
Onimọ nipa ẹsin musulumi Alhaji Taofeek Akeugbagold lo sọrọ yii lori ẹrọ amohun-maworan.
Laipẹ yii ni ọrọ ''Association of Stingy Men'' gba ori ayelujara pa ti awọn eeyan si n gba ọrọ naa bi ẹni n gba igba ọti.
- Ẹ wo ọba kan nílẹ̀ Yorùbá, tí kò ṣe ètùtù tàbí náwó ànájù, kó tó jọba
- Irọ́ ni pé ọba tuntun má a ń jẹ ọkàn ọba tó bá wàjà ní ìpèbí - Elebuibon
- Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ńlà lọ́sẹ̀ tó kọjá tó fi mọ́ bí Covid-19 ṣe gbẹ̀mí èèyàn 23 lọ́jọ́ kan ṣoṣo
- Èèyàn 1,598 míì tún ti lùgbàdì covid-19 ní Nàijíríà, 1,420 ló ti kú báyìí
- Mo ti ní ìyàwó àfẹ́sọ́nà, ayẹyẹ ìgbeyàwó mi ń bọ̀ láìpẹ́ - Lateef Adedimeji
- Ọwọ́ tẹ ènìyàn méjì tó ń ta ayédèrú aṣọ iṣẹ́ ikọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn
''O pa mi lẹrin nigba ti mo gbọ ọrọ awọn ọdọ ti wọn n pe ara wọn ni ẹgbẹ awọn ọkunrin to lahun,'' Akeugbagold lo sọ bẹẹ.
Aafa Akeugbagold ni apẹẹrẹ were diẹdiẹ ni ọrọ ẹgbẹ ''Association of Stingy Men'' ti awọn kan n sọ.
O ni ohun ti Ọlọrun sọ ni pe ki ọkunrin nawo fun obinrin, ki o si fi owo tọju rẹ.
Akewugbagold sọ pe ''ẹni to jẹ ọkọ ni ko ri owo na fun un yii, bẹẹ ale si ni o nawo fun obinrin yii, awọn kan wa ni awọn ni ọmọ ẹgbẹ ''Association of Stingy Men.''
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Aafa naa ni Ọba oke to da obinrin sọ pe ''owo ti ẹ n na fawọn obinrin, ọkan lara awọn ọna ti ọkunrin maa n fi ṣe idari obinrin ni gẹgẹ bi ọkọ rẹ, ayafi ti ẹ ko ba lowo lọwọ loku.''
Aafa Akeugbagold ni ṣiṣe ahun si awọn obinrin ko yatọ si ki eeyan ṣi ilẹkun fun ole.
Akeugbagold ni abamọ ni yoo gbẹyin iru awọn ọkunrin to ba lowo lọwọ ṣugbọn ti wọn n ṣe ahun si obinrin.


















