Amotekun Oyo: Ọwọ́ tẹ ènìyàn méjì tó ń ta ayédèrú aṣọ iṣẹ́ ikọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn

Amotekun

Oríṣun àwòrán, AMOTEKUN

Ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Oyo ti fi lede pe ọwọ awọn ti ba afurasi meji to n ṣe aṣọ iṣẹ Ikọ Amọtẹkun ti wọn si n ta wọn.

Adari ikọ Amotẹkun ti Agency 2'C, Comrade Kazeem Babalola lo fi lede wi pe awọn mẹfa ti awọn gbamu lo jẹwọ wi pe awọn kii ṣe oṣiṣẹ ikọ Amọtẹkun, ati wi pe ayederu aṣọ ni awọn wọ.

Eleyii lo jẹ ki wọn tẹ pinpin ayederu aṣọ naa, ti ọwọ si tẹ Alhaja Oluwakemi Akehusola ni agbegbe ijọba ibilẹ Ido ni ipinlẹ Oyo.

Amotekun

Oríṣun àwòrán, Amotekun

Lẹyin naa ni iwadii fihan pe ẹni to n ṣe aṣọ naa wa ni arakunrin Mathew Aderanijo ni agbegbe Challenge ni ilu Ibadan.

Ẹ má ṣùn àṣùnpiyè o! Àwọn àjèjì darandaran ń wọ ìpínlẹ̀ Oyo àti Ogun lọ́gọ́ọ̀rọ̀ - Amotekun

Ikọ alaabo nilẹ Yoruba, Amọtẹkun ti ke gbajare lori awọn darandaran ti wọn n wọle si ipinlẹ Ọyọ ati Ogun ni ọgọọrọ.

Awọn ajeji agbegbọn to n ya wọ Naijiria

Oríṣun àwòrán, @Worldstagegroup

Alaga ikọ Amọtẹkun ni iha Iwọ Oorun Naijiria, Kunle Togun lo fi lede pe awọn Fulani darandaran yii kii ṣe ọmọ Naijiria.

Togun ni agbegbe ila orun Saki ati ijọba ibilẹ Atisbo ni wọn n gba wọle si ipinlẹ Ọyọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni wọn fikun wi pe ,ikọ Amọtẹkun ko ni koju wọn pẹlu ibọn, amọ awọn yoo lo ohun ija ibilẹ lati fi koju awọn Fulani Darandaran naa.

'Iye awọn Fulani darandaran to n wọle si ilẹ Yoruba ko lonka, paapaa ni ilu Ọyọ ati Ogun'

Amotekun Oyo: Ikọ Amọtẹkun ṣeṣi yinbọn pa akẹkọọ ni Ibadan

Oríṣun àwòrán, Oyo amotekun

'Nitori naa awọn ikọ Amọtẹkun to mọ iṣẹ wọn ati awọn ogboju ọde ni yoo koju awọn Fulani darandaran yii, ki wọn ma ba a ṣe awọn eniyan ni ijamba.'

'Ọpọlọpọ ohun ija awọn ajoji wọnyii ni a ti gba, to fi mọ olonde, majele ati oogun abẹnugọngo ti wọn ko wọ ilẹ Yoruba.

'Iwadii naa fikun wi pe, pupọ ninu awọn ajoji wọnyii kii ṣe ọmọ Naijiria.'

Àkọlé fídíò, Ado Ekiti Blind Couple: Tọkọ-taya Oke ní Ọ́ba òkè ló fi àwọn dá àrà tó wù ú

Amọ, ikọ Amọtẹkun naa fikun wi pe, o da awọn loju wi pe awọn baalẹ ati awọn olori ilu kereje-kereje lo n pe awọn Fulani darandaran yii wa si agbegbe wọn.

Amotekun ni oun ti gbe igbesẹ lati se ipade pẹlu awọn lọbalọba ni ẹkun naa lati dena iru iwa bayii.

Ikọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn ṣèsì yìnbọn pa akẹ́kọ̀ọ́ nílùú Ibadan

Amotekun Oyo: Ikọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn ṣèsì yìnbọn pa akẹ́kọ̀ọ́ nílùú Ibadan

Oríṣun àwòrán, Oyo

Ikọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ọyọ ti ṣeṣi pa arabinrin, Tosin Thomas ni ilu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Gbenga Fadeyi lo fi idi ọrọ naa mulẹ ni ilu Ibadan.

Fadeyi ni iroyin ti awọn kojọ ni wi pe arabinrin Thomas Tosin n lọ si ile nigba ti awọn ọmọ Yahoo-yahoo bẹrẹ ariyanjiyan lori ọrẹbinrin wọn.

Ọkan ninu awọn ọmọ Yahoo yii pe ikọ Amọtẹkun lati wa pẹtu si aawọ.

Amọ, ọkan lara ikọ Amọtẹkun naa ṣeṣi yinbọn to si pa Tosin Thomas lasiko ti wọn fẹ pari ija to n ṣẹlẹ.

Ikọ ọlọpaa ni wọn gbe ọmọbinrin naa digba-digba lọ si ile iwosan Fasiti Ibadan, amọ arabinrin naa papoda ni owurọ ọjọ keji ni ileewosan.

Lẹyin iṣẹlẹ yii ni ẹgbọn oloogbe naa wa gbe oku aburo rẹ wa si ibi ti wọn ti yinbọn pa lati bere idajọ otitọ.

Eleyii fa rogbodiyan ni agbegbe naa, ti awọn ọlọja si palẹ ọja wọn mọ fun ọjọ naa.

Igba karun niyii ti wọn n fi ẹsun kan ikọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ọyọ wi pe wọn n yinbọn pa araalu lati igba ti wọn ti bere iṣẹ nipinlẹ naa.

Ènìyàn méje kú lásìkò tí àwọn Fulani àti ikọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn kojú ara wọn ni Oyo

Ìdí tí ikọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn àti Fulani fi wọ̀yá ìjà nípìnlẹ̀ Oyo

Oríṣun àwòrán, Amotekun

Àwọn ọmọ ikọ̀ Àmọtẹ́kùn àti àwọn Fulani kan ni ìròyìn sọ pé wọ́n wọ ìyá ìjà ní àgbègbè Aiyete ní ìjọba ìbílẹ̀ Ibarapa North nípínlẹ̀ Oyo .

Gẹ́gẹ́ bi ìròyìn ṣe sọ, abúlé Okebi ni ìjà náà ti bẹ̀rẹ́ ni òwúrọ̀ ọjọ́ Àbẹ́mẹ́tà, sùgbọ́n kò sí ẹni to le fi ìdí ǹkan to fa èdè àìyedè náà títí di àsìkò tí à ń kọ ìròyìn yìí.

Ọkùnrin kan, Saliu ti o jẹ́ olùgbé agbègbè náà ló sọ fún oníròyìn pé, ènìyàn méje ló ti jẹ́ ọlọrun nípe nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, tí wọ́n sì tí dáná sun ilé bíi méje pẹ̀lú.

Oyo Amotekun: Ìdí tí ikọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn àti Fulani fi wọ̀yá ìjà nípìnlẹ̀ Oyo

Oríṣun àwòrán, Lateef

Saliu ni "Alhaji Usman Okebi àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjì pẹ̀lú bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn, sùgbọ́n à kò mọ ǹkan ti ó fa ìjà," àwọn míràn farapa pẹ̀lú.

" Àwọn míràn tí wọ́n yìnbọn mọ́ tí wọ́n sì sá lọ pada lọ kú sínú igbo"

Bákan náà ni ẹlòmíràn tí sọ pé, ààrin àwọn ikọ̀ àmọ̀tẹ́kùn àti àwọn Bororo ni ìjà náà ti wáye. Ó ní wọ́n pa àwọn ènìyàn sùgbọ́n òun ko le fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, àpá ibi ti ó fì sí jù.

Ọ̀gá àgbà ikọ̀ àmọtẹ́kun Col. Olayinka Olayanju nígbà ti àwọn oníròyìn kàn sí ló sàlàyé pé òun yóò yọjú síbẹ̀ láti mọ ìdí ǹkan tó ṣẹlẹ̀ ni pàtó, sùgbọ́n pàbó ló jásí pẹ̀lú gbogbo ìgbìyànjú BBC lati gbọ abábọ ìṣẹ̀lẹ̀ náàbi àgbẹnusọ ikọ̀ àmọtẹ́kùn ko ṣe gbé aago wọ́n mọ́.

Agbẹnusọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo náà kọ̀ láti gbé aago rẹ̀ títí di àsìkò tí à n kọ ìròyìn yìí

Oyo Amotekun: Ìdí tí ikọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn àti Fulani fi wọ̀yá ìjà nípìnlẹ̀ Oyo

Oríṣun àwòrán, Lateef

Kílo ṣẹlẹ̀ gan?

Gẹ́gẹ́ bi Seriki Fulani ìpińlẹ̀ Oyo Alhaji Salihu Abdulkadir ṣe sọ àwọn Amọtẹ́kùn já wọ bùba àwọn ajínígbe ní ìbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ méjì ní agbègbè náà.

Èyí sì ló fàá tí wọ́n fi kójú ìjà sí ara wọ́n.

Adari àwọn ajínigbé náà tí wọ́n pè ní Umoru na pápábora pẹ̀lú ìbọn , tí àwọn ọmọ ikọ̀ àmọ̀tẹkun náà si farapa.

Mẹ́ta nínú àwọn ajínigbé Fulani náà bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ ti wọ́n sì gba ìbọn wọn