New date for School resumption: Ìjọbá àpapọ̀ tún yíhùn padà lórí ọjọ ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́

Oríṣun àwòrán, Ogun govt
Ijọba apapọ lorilẹede Niajiria ti paṣẹ ki gbogbo ileewe wọle pada ni Ọjọ Kejidinlogun, Oṣu Kini, Ọdun 2021.
Eyi ko ṣẹyin ipade to waye laarin Minisita fun eto Ẹkọ,Malam Adamu Adamu ati awọn kọmisọnna fun eto Ẹko ni ilu Abuja.
Iroyin ni aṣẹ naa ko ṣẹyin ipade ati atilẹyin lati ọdọ awọn gomina ipinlẹ, adari ileewe, awọn adari awọn akẹkọọ ati awọn akẹkọọ.
Wọn ni gbogbo wọn fi ọwọ si wi pe ki awọn ileewe ṣi pada kaakiri Naijiria.
Akọwe agba fún ilé iṣẹ́ eto Eko ni Naijria lo fi idi ọrọ naa mulẹ
Amọ, ijọba ni gbogbo awọn akẹkọọ ati olukọ lo gbọdọ tẹle awọn ofin to rọmọ didẹkun itankalẹ arun Coronavirus lorilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Min edu

Oríṣun àwòrán, Ministry of edu
À ó ṣe àtúngbéyẹ̀wò àsìkò ìwọ́le àwọn akẹ̀kọ̀ọ́-Ìjọba apapọ̀

Oríṣun àwòrán, Adamu Adamu
Ìjọba àpàpọ̀ ni ni òun yóò ṣe àtúngbéyẹ̀wò àsìkò ìwọ̀lé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní Nàìjíríà.
Sáájú ni ìjọba ti ní àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò padà sílé ìwé ni ọjọ́ kejìdílógun, oṣù kíní ọdún 2021, sùgbọ́n ojoojúmọ ni ààrùn Coronavirus n péleke sí.
Mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́, Adamu Adamu ló sọ èyí di mímọ lásìkò tó n dáhùn ìbéèrè àwọn akọròyìn níbi ìpàdé àwọn oníròyìn ti ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ ṣe lórí Covid-19 ti ààrẹ yan nílùú Abuja.
Mínísítà ní " Lórí ìwalé ọjọ́ kejìdílógún, a ó ṣe àtúngbéyẹ̀wò rẹ̀."
A tí sọ níbi ìpàdé PTF tí a ṣe lónìí, tó bá di ọ̀la, ilé iṣk ètò ẹ̀kọ́ yóò mọ ìgbésẹ̀ tó kù."
Sáájú àsìkò yìí ni ìjọba ti kéde pé, kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní gbogbo ipele padà sí ilé ẹ̀kọ́ ni ọjọ́ kejìdínlógún , oṣù kíní ọdún 2021.
Lagos School resumption: Ìpínlẹ̀ Eko kéde ọjọ́ tuntun Jan. 18 fún ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́

Ijọba ipinlẹ Eko ti pada kede ọjọ kejidinlogun oṣu kini ọdun 2021 gẹgẹ bii ọjọ iwọle tuntun fun awọn akẹkọọ fun saa eto ẹkọ keji.
Atẹjade kan ti ileeṣẹ eto ẹkọ ni ijọba ipinlẹ Eko, fi sita ṣalaye pe kọmiṣọna eto ẹkọ nipinlẹ Eko Arabinrin Fọlaṣade Adefisayọ lo kede eyi ni "ibamu pẹlu aṣẹ ati idari ijọba apapọ ati ọwọja ọwọ keji ajakalẹ aarun COVID-19 to n ja lọwọlọwọ."
- Lóòótọ́ obìnrin ló mọ ẹni tó loyún, ṣùgbọ́n tó bá rújú, ohun tí Yorùbá ń ṣe rèé-Elebuibon
- Ọlọ́pàá Oyo n wa afurasí tó ṣekú pa oníṣòwò àti ọmọ ọdún mẹ́sán án méjì ní Ibarapa
- Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé rèé lórí àyẹ̀wò DNA
- Wo ìgbà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò wọlé ní ìpínlẹ̀ Eko
- Kí ló mú kí Baba Barakat tó fẹ̀sùn ìyọnilẹ́nu torí ìbálòpọ̀ kan kọmísọ́nà àyíká ìpínlẹ̀ Ogun pàlù ẹnu dà?
- Nǹkan márùn ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa Ọ̀gá Àgbà fásitì UNILAG tẹ́lẹ̀rí, Ibidapo Obe tó jáde láyé
ni opin ọsẹ to kọja ni ijọba ipinlẹ Eko ti kọkọ kede pe gbogbo awọn ileewe alakọbẹrẹ ati girama ko ni lee wọle bayii ayi pe iwọle wọn di ọjọ mii ọjọ ire.
O wa rọ awọn ileewe lati ṣeto aye to tọ fun awọn akẹkọọ tabi olukọ ti ara wọn ko ba ya lati maa kọ ẹkọ tabi ṣiṣẹ wọn lati ile nipasẹ ayelujara iyẹn, "Virtual learning" tabi "Virtual work"













