Ibidapo Obe: Nǹkan márùn ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa Ọ̀gá Àgbà fásitì UNILAG tẹ́lẹ̀rí, Ibidapo Obe tó jáde láyé

Ibidapo Obe

Oríṣun àwòrán, Google

Iku doro, iku ni igbẹyin gbogbo ẹda, awaye ma lọ kan o si.

Yoruba bọ wọn ni baa ku laa dere, eniyan o sunwọn laaye, bi o se jẹ pe ọpọ lo n gbọ nipa ọjọgbọn Oyewusi Ibidapo Obe fun igba akọkọ lati ana ti okiki ti kan pe o d'oloogbe.

Eyi lo mu ki a se agbeyewo awọn nkan marun ti o ko mọ nipa ọjọgbọn naa.

1. Ọjọgbọn Oyewusi Ibidapo-Obe ni a bi ni ọjọ karun osu keje ọdun 1949, o jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Osun, o si lọ ile iwe alakọbẹrẹ Ebute Metta laarin ọdun 1955 si 1961, o tẹ siwaju lọ Obokun High school ati Ilesha Grammar School, o si tun lọ Igbobi college laarin ọdun 1962 si 1968.

Bakan naa lo lọ fasiti ilu Eko laarin ọdun 1968 si 1971 nibi to ti gba oye imọ nipa imọ isiro gẹgẹ bi ẹni to pegede julọ ni ọdun naa (first Class in mathematics).

2. Ọjọgbọn Obe jẹ giwa Fasiti Unilag laarin ọdun 2000 si 2007 ti o si gba oye OFR, FAS, FAEng, FNCS, FNIM, F.ASCE, F.AAS, FTWAS, o gba oye ọjọgbọn ninu imọ Ẹrọ.

3. Ọjọgbọn Ibidapo jẹ alaga igbimọ awọn giwa fasiti to si gba ami ẹyẹ Giwa fasiti to pegede julọ ni ẹẹmeeji ọtọọtọ ni ọdun 2004 ati 2005.

4. O ti kọ apilẹkọ iwadii to le ni aadọjọ, wọn yan gẹgẹ bi "Fellow of African Academy of Science (AAS) ati The World Academy of Science (TWAS) ni ọdun 2010 bakan naa lo gba ti American Society of Civil Engineers (ASCE) lọdun 2015. Awọn ifoye danilọla yii lo gba ni fasiti Texas Southern, Houston, New York ati ilu Eko.

5. Ọjọgbọ Oyewusi Ibidapo-Obe fẹ Olusola Ibidapo-Obe ni iyawo Eedua si fi ọmọ mẹrin tawọn lọrẹ.

Okiki iku ọjọgbọn Obe tankalẹ duniyan lẹyin to gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra lọjọ Aiku, ọjọ kẹta osu kini ọdun 2021, iroyin sọ pe o lugbadi aarun Coronavirus.

Ọ̀gá Àgbà fásitì UNILAG tẹ́lẹ̀rí, Ibidapo Obe tí jáde láyé

Olukọ Agba ati Ọga Agba fasiti ilu Eko tẹẹri, Oye Ibidapo-Obe ti jade laye.

Arakunrin Ibidapo-Obe ni Ọga Agba ati Alaga ile iwe giga First Technical University, ni Ibadan.

Ninu iwe atẹjade ti ileewe First Technical University, Ibadan fi lede ni wọn ti jẹ ko di mimọ fun awọn eniyan pe Ọjọ Isinmi, Ọjọ Kẹta, Oṣu Kini, ọdun 2021 ni ẹmi bọ lara Ibidapo Obe.

Bi o tilẹ jẹpe ileewe giga naa ko fi lede iru iku to pa, amọ ọpọlọpọ iwe iroyin lo gbe e pe arun Coronavirus lo mu ẹmi eniyan nla naa lọ.

Awọn iwe iroyin naa fikun wi pe Ọjọgbọn naa ti n gba iwosan ni ileewosan kan nipinlẹ Eko fun bi ọjọ mẹwaa, ko to di wi pe o jade laye.

Ẹni ọdun mọkandinlaadọrin ni Arakunrin Ibidapo-Obe ko to di wi pe o jade laye.

Ọjọgbọn onimọ nipa Applied Mechanics and Systems Engineering, to si tun jẹ adari ileewe giga Fasiti Eko, Unilag ni ọdun 2000 si 2007.

Ile ife ni wọn ti bi ni ipinlẹ Osun, to si lọ si ileewe Girama ni Ilesha ati Igbobi College laarin ọdun 1962 si 1971.

Bakan naa ni ọpọ ọrẹ ati ojulumọ lo ti n ṣe idaro rẹ lori ẹrọ ayelujara, ti wọn si n kii pe odigba ose.