Lagos schools resumption: Dókítà Faduyile ní ewu ń bẹ tórí coronavirus táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ba wọlé padà báyìí

Oríṣun àwòrán, Twitter/Babajide Sanwo-Olu
Ewu n bẹ loko Longẹ, Longẹ gan an ewu.
Aarẹ ẹgbẹ awọn dokita oyinbo ni Naijiria tẹlẹ, Ọjọgbọn Francis Faduyile lo kilọ pe ewu wa nibẹ tawọn akẹkọọ ileewe alakọbẹrẹ ati girama ba fi le wọle bayii pẹlu bi ọwọja coronavirus lẹẹkeji ṣe ṣoro.
Ṣaaju ijọba ipinlẹ Eko kede pe o ṣeeṣe kawọn akẹkọọ ileewe alakọbẹrẹ ati girama pada sile iwe lọjọ kejidinlogun oṣu kinni ọdun 2020 yii.
- Ìpínlẹ̀ Eko yí ohùn padà, Ó kéde ọjọ́ tuntun fún ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́
- Èèmọ̀ wọ̀lú, Ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ gbé ọmọ ọ̀gá rẹ̀ àti káàdì ìgbowó ATM sálọ l'Ondo!
- Ẹ̀gbọ́n baba Barakat ṣàlàyé bí ó ti gbé e lọ sílé kọmísọ́nà Ogun tí wọ́n ní kó lọ rọ́kún nílé
- Wo ọ̀nà tí Yoruba ń gbà dá ọmọ àlè mọ̀ nínú ìdílé- Elebuibon
- A kò ṣé àfikún ìdá 50% lórí owó iná, àmọ́ tàríìfú N2 sì N4 báyìí- NERC
- Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé rèé lórí àyẹ̀wò DNA
Ṣugbọn Ọjọgbọn Faduyile to ba BBC Yoruba sọrọ lori atiwọle pada awọn akẹkọọ nipinlẹ Eko ṣalaye ko si ẹni to le sọ bi ajakalẹ arun covid-19 ṣe maa ri lasiko ti ijọba da pe awọn akẹkọọ le wọle.
O ni agbeyẹwo bi arun naa ṣe n tan kalẹ ni bii ọsẹ meji si asiko yii lo maa sọ bo ya awọn akẹkọọ le pada sile iwe wọn bayii.

Ọjọgbọn Faduyile ni o ṣe pataki fawọn eeyan lati maa ṣọra ṣe, ki wọn maa lo ibomu wọn, ki wọn si maa fọwọ wọn deedee.
Iroyin ti a n gbọ ni pe awọn ile iwosan ti kun fọfọ nipinlẹ Eko pẹlu awọn to ṣẹṣẹ lugbadi arun coronavirus.
Wo ìgbà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò wọlé ní ìpínlẹ̀ Eko
Ijọba ipinlẹ Eko ti Kede pe ile Ekọ alakobẹrẹ ati girama ko le pada senu EkọIjọba ipinlẹ Eko ti kede pe gbogbo ilé iwe aladani ti kii ba ti se ile Eko giga fasiti, ile ẹkọ olukoni agba tabi ile ẹkọ gbogbonise si wa ni titi pa titi di asiko ti ijọba yoo kede asiko iwọle tuntun nitori owoja ajakalẹ aarun Coronavirus to tun wọle fun igbakeji yii.
Ninu atẹjade ti olori eto ara ilu nile isẹ to n ri si eto ẹkọ nipinlẹ Eko Kayode Abayomi fọwọsi salaye pe eyi mu ki gbogbo ile iwe to ti pinu lati wọle lọjọ ni kẹrin osu kini ọdun 2021 si wa ni titi pa.
Abayomi rọ awọn obi, alagbatọ ati awọn akẹkọọ lati tẹle ilana ipara ẹnimọ lati dena itankalẹ arun COVID-19, bi wiwọ ibomu, ijina sira ẹni, fifọwọ deede ati lilo sanitisa loorekoore.












