DNA Paternity: Tó bá wáyé pé ẹ kò mọ ẹni tó lọmọ, ohun tí àwọn àgbààgbà Yorùbá máa ń ṣe rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Araba awo ilu Osogbo, Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn ti da si Ọrọ DNA to gba igbooro kan lori iṣẹlẹ ka gbọmọ ọba fun Oṣun to n waye laarin lọkọlaya .
Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC agbaọjẹ ede ati aṣa Yoruba yi ti lawa lọyẹ lori oun taa ṣe nilana ti Yoruba ti a ba fura si pe awọn ọmọ to wa lọọdẹ wa kii ṣe ojulowo ọmọ ọkọ.
Elebuibon ṣalaye pe lootọ ni obinrin maa n mọ ẹni to bimọ fun ṣugbọn to ba ṣẹlẹ pe irin ẹsẹ obinrin ko mọ, awọn mọlẹbi tabi ọkọ fun ara rẹ le fi tibilẹ tọ pinpin ẹni to lọmọ.
Ti a ba ti n fi eeyan kukuru se awo ẹni to gun, awo maa n ya ni
Owe yi ni Baba Elebuibon fi kin ọrọ wọn lẹyin ti o si ba wa ṣide alaye lori iṣẹlẹ ki a maa gbe ọmọ ọlọmọ fun ọkọ ẹni.
Wọn sọ pe pupọ iru iṣẹlẹ yi ko yọ awọn obinrin lẹsẹ silẹ botilẹjẹ pe awọn ọkunrin naa ọwọ wọn ko mọ tanyanyan
''Ọwọ awọn obinrin lọrọ ti maa n wọ.Ti ọkọ tabi iyawọ ko ba ṣeke si ara wọn, ko yẹ ko si nkan ti yoo mu ki wọn fẹ mọ boya emi ni mo lọmọ tabi emi kọ''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lara ọna ti Elebuibon ṣalaye pe awọn Yoruba fi maa n mọ boya ọmọ ọkọ ni wọn gbe fun ree:
Nigba ti obinrin naa ba bimọ tan wọn a ni ko gbe ọmọ wa ko si wọle lọ. Lẹyin to ba wọle, wọn a da omi si ori orule ti iya ọmọ naa yoo si sa wọle lẹẹmeje.
Elebuibon sọ pe wọn a maa ṣe eleyi ''lati mọ boya ọmọ ọkọ ni ọmọ naa ni tootọ''
Ọna keji ti agba awo yi ṣalaye ni nipa ṣiṣe oosa idile.

Alagba Yemi Elebuibon ṣalaye pe wọn a tun maa ''gbe ọmọ lọ si ọdọ ooṣa lati mọ boya idile ọkọ naa lo ni ọmọ ọ́hun ni tootọ''
Oro yi gẹgẹ bi alaye ko papọ ni ilu si ilu tabi ni idile si idile.Lati laelae lo si ti maa n wa
''Ẹlọ mii wọn a ni ki iya rẹ jẹ nkankan fun ọjọ meloo kan, ẹlo mii wn a gbe ọmọ yẹn lọ si idi ooṣa ti wọn a fi sibẹ fọjọ meloo kan''
Yatọ si awọn oro idile yi, Araba tun sọ pe awọn oro idile mii yoo niṣe pẹlu ki wọn gbe ọmọ si eti odo tabi ki o sun ti ere ejola mọjumọ.
Nigba ti a beere pe ki wa ni yoo ṣẹlẹ ti wọn ba ri wi pe ọmọ yi kii ṣe ọmọ ọkọ, wọn fesi pada bayi:
''Yoruba kii ṣaba fẹ gba ọmọ ale.Wọn ni ti ile baa n toro ọmọ ale ibẹ ni ko ti dagba ṣugbọn nigba mi ọkọ maa n gba lati tọju iru ọmọ bẹ bi tiẹ''
Lakotan ọrọ alagba Elebuibọn, wọn ni ti ọkọ ba dariji iyawo tabi to gba lati tọju ọmọ tiu iyawo ba gbe wa lati ile ọkọ mii, ko si aburu nibẹ.













