Lizzy Anjorin: Ẹ̀yin tẹ bímọ fún ọkọ mi, ẹ kó ọmọ wa ká ṣe àyẹ̀wò DNA fún wọn

Oríṣun àwòrán, lizzyanjorin_original
Ilumọọka osere tiata lobinrin to tun gbajumọ lawọn oju opo ayelujara rẹ, Lizzy Anjorin Lawal ti kede pe igbe aye to dakẹ rọrọ ko wu oun.
Anjorin-Lawal, ẹni to sẹsẹ se igbeyawo laipẹ yii sisọ loju ọrọ yii lasiko to n ba akọroyin kan sọrọ.
Lizzy ni igbe aye alariwo lo n mu owo wọle fun oun, nitori naa, oun ko fẹ lati gbe igbe aye to tutu rọrọ rara.
- Lizzy Anjorin: Mi ò bẹ Toyin o! Ẹ̀yin olólùfẹ́ mi àti ẹbí ni mo bẹ̀
- Kemi Olunloyo dá sí ìjà Toyin Abraham àti Lizzy Anjorin
- Kò sí ọkùnrin tí yóò fún obìnrin tó halẹ̀ bíi tèmi lówó - Lizzy Anjorin
- Lizzy Anjorin gbàgbé ọ̀rọ̀ àná, ó kí Iyabo Ojo kú ọjọ́ ìbí, Femi Adebayo kọ ọmọ l'áṣà
- Toyin Abraham kìí bá èmi náà yọ̀, ni kò jẹ́ kí ń gbé e lárugẹ fún ayọ̀ ọmọ - Lizzy Anjorin
"Mo nifẹ igbe aye mi bo se n lọ yii, ti emi ati ẹnikan ba si tahun sira wa, amọ ti ipenija ba de ba a, maa pe onitọun, ti maa si tun se iranwọ fun to ba nilo rẹ.

Oríṣun àwòrán, lizzyanjorin_original
Eyi jẹ ọkan lara awọn asiri aseyori mi, nitori ọkan mi mọ si gbogbo eeyan, bẹẹ ni ariwo ọja kii se idiwọ fun ontaja ati onraja, sugbọn bi ariwo ba se pọ si ninu sja ni ọja yoo se maa ya si."
Lizzy fikun pe ibẹrẹ igbe aye oun nira diẹ, ẹni to ba si n se oriire ni awujọ, ko le e jẹ ọrẹ awọn ti ko se daadaa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọkọ̀ tírélà epo forí sọ ọkọ̀ tírélà tó kó ẹja l‘Osun, ẹ̀mí èèyàn méjì sọnù
- Ọkọ̀ rélùwéè 16 yóò ná Eko sí Ibadan láti oṣù tó ń bọ̀ lọ - Iléeṣẹ́ Rélùwéè kéde
- Àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Mali ń fò fáyọ̀ pé ológun gba ìjọba mọ́ alágbádá lọ́wọ́
- Ìròyìn ayọ̀! Kùrù-kẹrẹ Coronavirus ṣeéṣe kó dópin láàrín ọdún méjì - WHO
- Géńdé agbébọn yabo àgọ́ ọlọ́pàá n‘Ibadan, ẹ̀mí ọlọ́pàá kan bọ́
- Ọba Ilorin ló pàṣẹ pé kí ń padà sọ́dọ̀ ọkọ mi - Risikat olójú búlúù
- NCDC kéde èèyàn 340 míràn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lùgbàdì Covid-19 ní Nàìjíríà
- A fí ara mọ́ ìdájọ́ ikú Sharia tó tọ́ sí Olórin Yahaya- ẹgbẹ́ Amòfin Mùsùlùmí ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Kano
O ni ohun kii kọkọ tọ ẹnikẹni amọ ẹni to ba tọ oun rugi oyin, bẹẹ si ni oun ko gbagbe ipilẹ oun, ti oun si maa n ranti akoko toun kiri ọja.
Gbajumọ osere tiata naa ni oun ti gbe ninu ile alapa ri, ti iya oun si tun lo akisa lati fi wo oun, ọpọ eeyan si ni ko lee ye igbe aye ti oun ti la kọja sẹyin.
Nigba to n sọrọ lori igbeyawo to sẹsẹ se, Lizzy ni "ọrẹ mi ni mo fẹ lọkọ, awọn obinrin ti wọn si ni awọn ti bimọ fun ọkọ mi, wọn ko ti kan si wa tabi ko ọmọ wọn wa sinu ile wa.
Mo ti pe wọn nija loju aye,gbogbo wọn kan n lo anfaani pe ọkọ mi jẹ eeyan gidi ni, mo n pe wọn lati ko smọ wọn wa fun ayẹwo DNA."
Lizzy wa yan pe lootọ ni awọn mejeeji ti bimọ fun ẹlomiran tẹlẹ saaju igbeyawo awọn, amọ ọkọ oun ko se igbeyawo pẹlu ẹnikẹni ninu awọn obinrin to bimọ fun.













