Osun Accident: Èèyàn méjì pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé ni Osun

Fire

Oríṣun àwòrán, @FedfireC

Ko din ni eeyan meji to jẹ Ọlọrun nipe ninu ijamba ọkọ to waye lẹyin ti ọkọ agbepo kan fori sọ ọkọ to ko ẹja ni ipinlẹ Osun.

Iṣẹlẹ ọhun waye ni ni nnkan bi aago mọkanla owurọ lọjọ Ẹti loju ọna marosẹ Gbogan si Ife, ni ijọba ibilẹ Ayedaade, ni ipinlẹ ọhun.

Iroyin ni iṣẹlẹ naa da sunkẹrẹ-fakẹre ọkọ silẹ loju ọna naa nigba ti ina ọhun bẹrẹ si n jo.

Gẹgẹ bi ohun ti awọn oṣoju mi koro sọ, awakọ epo naa ati ẹnikeji rẹ gbẹmi mi nigba ti awakọ ẹja ti wọn fori sọra moribọ.

fire

Oríṣun àwòrán, @FedfireC

Agbẹnusọ ileeṣẹ panapana to wa ni ilu Osogbo, Adijat Basiri, sọ fun awọn akọroyin pe, ni kete ti awọn ara ilu fi ọrọ naa to wọn leti ni awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọhun lọ sojuko naa ti wọn si pa ina ọhun.

Basiri sọ pe bi awọn awọn ọkọ memeji ṣe fori sọra lo fa ṣababi ina to ṣeyọ.

O ni "Eeyan meji lo padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ naa ṣugbọn a ko tii le sọ awọn ileeṣẹ to ni awọn ọkọ mejeji."

Àkọlé fídíò, Jude Chukwuka: Wọ́n yóò fi ojú ọlọgbọ́n wo akúrí tó bá sọ ojúlówó èdè Yorùbá