Blasphemy against Mohammed: Olórin Kano Yahaya Shariff-Aminu tí wọ́n dájọ́ ikú fún ti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn

Protesters

Oríṣun àwòrán, Idris Ibrahim

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 12

Yahaya Shariff-Aminu ti wọn dajọ iku fun pe o sọrọ odi si Mohammed ni ilu Kano ti pe ẹjọ kotẹmilọrun niwaju ile ẹjọ giga kan niluu Kano.

Ẹni ọdun mejilelogun olorin naa sọ pe bi ile ẹjọ Sharia ṣe n ṣe ẹjọ ni ipinlẹ naa ko tọna ko si ba ofin ijọba awarawa mu.Shariff-Aminu ni ile ẹjọ giga Sharia da ẹjọ iku fun lọjọ kẹwaa oṣu kẹjọ ọdun 2020 ṣugbọn ti wọn fun un ọgbọn ọjọ lati ẹjọ tirẹ bi idajọ wọn o ba tẹ ẹ lọrun.

Koda gomina ipinlẹ Kano ni oun ti ṣe tan lati tọwọ bọwe iku rẹ ni kete ti ọgbọn ọjọ naa ba ti pe.Ẹwẹ ninu iwe ipẹjọ kotẹmilọrun to fi ṣọwọ eyi ti agbẹjọro rẹ, Kola Alapinni kọ, ọdaran naa fi ẹsun kan amofin agba ipinlẹ Kano ati gomina.Ipẹjọ rẹ da lorii pe ẹjọ Sharia ti wọn da fun un ko tọna rara ko si ba ofin mu.

Aworan Femi Falana

Oríṣun àwòrán, FEMI FALANA FACEBOOK

O ni o ti tapa si ofin ijọba orilẹede Naijiria ti ọdun 1999 eyi ti wọn si ti ṣe atunṣe rẹ ni ti ẹtọ ọmọniyan.

Bakan naa o ni ọran ti wọn ni oun da ko si ninu ofin rara.

aworan idanimo ẹgbẹ amofin NBA

Oríṣun àwòrán, Nba

O fi kun un wipe "ofin Sharia lee jẹ ojulowo ninu ilana ẹsin Islam tabi ni orilẹede ti ofin wọn fi aaye gba iru nkan bẹẹ amọ o ni ilu to lofin ijọba awarawa ni Naijiria eyi si ni ofin to ba lori ohun gbogbo.Yahaya ni ipinlẹ Kano ti kanju da oun lẹbi ti wọn ko si faaye gba oun lati sọ toun pẹlu bo ṣe jẹ pe ilana ofin wa nipinlẹ Kano.Olorin naa wa rọ ile ẹjọ pe ki wọn gbe ẹjọ ati idajọ naa ti ile ẹjọ Sharia da fun un ti sẹgbẹ kan ki wọn si bẹrẹ ẹjọ eyi ti yoo ṣe oun loore.

aworan idajo ododo

Oríṣun àwòrán, others

A fí ara mọ́ ìdájọ́ ikú Sharia tó tọ́ sí Olórin Yahaya- ẹgbẹ́ Amòfin Mùsùlùmí ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Kano

Ẹgbẹ́ musulumi ti wọn jẹ amofin, ẹ́ka ti ipinlẹ̀ Kano ti ọ̀rọ̀ olorin Yahaya Sharif Aminu ti sele ti sọ̀rọ̀ lori idajọ iku naa.

Won ni ofin Sharia wa fun awon musulumi nikan ni eyi ti wọn si gbọdọ tẹle asẹ idajo re gẹgẹ bi o se tọ Sunah ẹ̀sin Islam.

Egbe yii ti oruko won n je Muslim Lawyers' Association (MULAN) ẹ̀ka ti ipinlẹ̀ Kano salaye ipo ti asẹ ofin Sharia wa ninu eto ilana ofin Naijiria.

Won ni enikeni to ba jẹ́ musulumi ni Naijiria ni ilana ofin wa fi aaye gba ki wọ́n gbe lọ sile ẹjọ́ Sharia ki wọ́n si tẹle asẹ́ ti Adajọ Sahria ba pa bii ti Yahaya ti adajo Sharia da ẹjọ́ iku fun yii.

Won ni ayafi ti Yahaya ba je elesin omiran ti kii se musulumi ti wọ́n yoo fi Sharia da ejo rẹ.

Egbẹ́ MULAN sọ pe sisọrọ lodi si Anabi Muhammed ti Olorin Yahaya se yii ko tọ suna ninu ẹsin Islam rara ati pe idajọ Sharia tẹ̀ awọn lọrun ninu ilana ofin.

Koda, wọ̀n se akawe awọn idajo ile ejo Supreme Court to jọ eyi.

Ati pe ofin Sharia wa fun musulumi nikan ti o si gbọdọ tẹ́le e.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati asa Yoruba: Ẹ wá kọ́ nípa àpòtí ìṣura èdè wa lórí BBC Yorùbá

Ẹgbẹ́ MULAN wa parọwa fun awọn Aafa Islam pe ki wọ́n maa kọ́ awọn eeyan wọ́n sii nipa ofin, ilana ati ikọni ẹsin Islam gẹ́gẹ́ bi o se tọ suna lasiko yii ki iru idajọ Sharia bayii ma baa maa sẹlẹ̀.

Ni ipari won ni ki awọn musulumi tubọ maa gbe ni alaafia ninu atejade naa ti Amofin Muhammad Sani Garba fọwọ si gẹ́gẹ́ bii alaga MULAN.

Iwe atẹjad e awọn amofin naa

Oríṣun àwòrán, others

Iwe atẹjad e awọn amofin naa

Oríṣun àwòrán, others

Iwe atẹjad e awọn amofin naa

Oríṣun àwòrán, others

Protesters

Oríṣun àwòrán, Idris Ibrahim

Kini o ti sẹlẹ̀ sẹ́yin?

Àwọn ẹgbẹ́ Tijjaniyya ti yọwọ́ kílàńkó Yahaya Sharif kúrò láwo ẹgbẹ́ wọn ní Kano

Ẹgbẹ́ Tijjaniyya ní ó tako ìkọ́ni Sheikh Ibrahim Inyas

Ẹgbẹ Musulumi Tijjaniyya ti yọ ara wọn kuro ninu ọrọ olorin ni ti wọn dajọ iku fun ni Kano.

Wọn ni ohun ti Yahaya Sharif Aminu ṣe ti ileẹjọ Sharia fi ni ko gba idajọ iku nipasẹ isọrọ lodi si Anabi Muhammed ko ba igbagbọ ẹgbẹ ẹlẹsin Islam Tijjaniyya mu.

Wọn ni nitootọ ni o bani ninujẹ pe ọdọmọkunrin ẹni ọdun mejilelogun naa gba iru idajọ.

Ṣugbọn sisọ ọrọ odi si Anabi Muhammed ko tọna rara ninu ẹsin Islam.

Alaga igbimọ Tijjaniyya ni ipinlẹ Kano, Mallam Muhammed Nura Arzai lṣalaye fun BBC pe ohun ti ọdọkunrin olorin naa ṣe yii tako ikọni ati igbagbọ Sheikh Ibrahim Inyas to jẹ olori wọn,

O ni: Awa ọmọ ẹyin Shehu Inyas gbagbọ pe idajọ Sharia tọna ninu ẹsin Islam.

Nigeria Sharia law: Àwọn òbí ní Kano dunú sí ìdájọ́ ikú fún bàbá ẹni ọdún 61

Oríṣun àwòrán, Others

Ki lo tun ti ṣẹlẹ lori idajọ Sharia ni Kano?

'Inú mi dùn pé wọ́n dájọ́ sísọ̀kò pa bàbá arúgbó tó fipá b'ọ́mọ lòpọ̀'

Nigeria Sharia law: Àwọn òbí ní Kano dunú sí ìdájọ́ ikú fún bàbá ẹni ọdún 61

À ń dúró de ìgbẹ́jọ́ mìí tó tún n bọ̀ láti pinu bí ẹjọ́ náà yòó ṣe yọrí".

Bi wọn ba n pa awọn to n ṣe ọmọde baṣubaṣu pẹlu iwa nọbi, iṣoro yii yoo dinku.

Lara awọn obi awọn ọmọ ti wọn ti fipabalopọ ni ipinlẹ Kano ni iha Ariwa Naijiria ti fi atilẹyin wọn han si ipinu ile ẹjọ giga julọ ti ẹsin Islam ti wọn dajọ iku fun baba agbalagba kan fun ẹsun ifipabanilopọ.

Awọn obi naa woye pe ipinu ileẹjọ yii yoo nipa pataki lati mu adinku ba bi iwa ọdaran ṣe n pọ sii, ṣugbọn wọn ni ijọba gbudọ jara mọ iṣẹ lori idajọ ileẹjọ fun awọn oniṣẹẹ laabi ọhun.

"O dara fun wa gẹgẹ bii Musulumi ati tori bi ilu ṣe n lọ bayii tori bi wọn ba sọ pe nile aye yii, nkan bii ifipabanilopọ lee gbilẹ to bayii, iyẹn nipe eniyan ko wulo.

Lakọkọ bi ẹ ba wo o daadaa, o lee da ẹmi ọmọde legbodo".

Ọkunrin kan ti ko fẹ ka darukọ rẹ sọ fun BBC pe, ọọ idajọ iku yii fun awọn afipabanilopọ yo ṣeranwọ lati mu adinku ba bi iwa ọdarsn ṣe n pọ sii.

Ọkan lara awọn baba awọn ti wọn fipabalopọ sọ pe "mo funpe si ijọba ki wọn jọwọ bojuto iṣẹlẹ naa ki wọn si ri i daju pe awọn to ba rufin foju wina ofin niruu iṣẹlẹ bẹẹ ki ijọba si rii pe wọn gbe igbesẹ kiakia.

"Niwọn igba ti wọn ba ti lo ipa tabi ti wọn lo ohun ija, ofin yii fẹsẹ mulẹ ninu Suratuk Ma'idah ẹsẹ kẹtalelọgbọn".

Àkọlé fídíò, Risikat Moromoke Azeez: Inú èmí àti Òbí mi dùn nígbà ti Risi bí ọmọ olójú búlù- Wasiu

Emi naa jẹri fun ọmọbinrin mi nile ẹjọ Baba kan naa sọ fun BBC pe wọn fipa ba ọmọ ohun to jẹ ọmọ ọdun mejila lopọ ni ọdun meji sẹyin ti ọrọ naa ko si tii kuro nile ẹjọ latigba naa di bayii.

"A n duro de igbẹjọ mii to tun n bọ lati pinu bi ẹjọ naa yoo ṣe yọri".

O ni nigba ti wọn fipa ba a lopọ, nkan ri bakan bakan fun un titi tọmọ rẹ ko ṣe lọ ileewe mọ torii idẹyẹsi ladugbo.

"Bo ba jade, awọn ọmọde a pe tẹle e lẹyin wọn a maa kigbe le e lori bi oromadiyẹ. Inu wa ko dun si eyi rara. Aye ọmọ wa ko lalafia a si wa ninu ibanujẹ."

Baba naa ni nigba ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ, ọmọdebinrin naa ko le da pa itọ mọra afigba to dero ileewosan lori eyi, ṣugbọn Alhadulilah o lee gbe itọ duro fun ọpọ akoko bayii. Ati pe o ti pada si ileewe".

Sharia Law in Nigeria: Wọ́n dájọ́ ikú nípa sísọ̀kò pa ẹni ọdún 70 ni ìpińlẹ̀ Kano

Oríṣun àwòrán, Others

Sharia Law in Nigeria: Wọ́n dájọ́ ikú fún Baba 61 tó fipá b'ọ́mọdé kan lò pọ̀ ni Kano

Iléẹjọ́ Sharia kan ní Kano ti ní kí wọ́n lọ sọ̀kò pa bàbá ẹni ọdún mọ́kanlélọ́gọ́ta kan.

Adájọ́ Ibrahim Sarki Yola ni bàbá náà jẹ̀bi ẹ̀sùn fífi ipá bá ọmọ ọdún mẹ́wàá kan lò pọ̀.Adájọ́ Ibrahim Sarki Yola ni bàbá náà jẹ̀bi ẹ̀sùn fífi ipá bá ọmọ ọdún mejila kan lò pọ̀.

Bàbá naa tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mati Audu ni ìròyìn sọ pé ó wá láti ìjọba ìbílẹ̀ Tsanyawa ni ipinlẹ Kano.

Agbẹnusọ ilé ẹjọ́, Sharia ní ìpińlẹ̀ Kano, ni ilé ẹjọ́ náà ri pé lẹ́yìn gbogbo ẹ̀ri to wà níwájú rẹ̀, ọkùnrin náà jẹ̀bi ẹ̀sùn ti wọ́n fi kàn.

O ní ó fipa bá ọmọ ọdún méjìlá lòpọ̀ ni abúlé Farsa ni ọdún 2019.

Àkọlé fídíò, Alaafin: Olori Aanu Adeyemi ṣàlàyé ìdí tó ṣe gẹ́ Oba Lamidi Adeyemi ti ìlú Oyo

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìrú ìdájọ lórí ẹ̀ṣùn ìfipábanilòpọ̀ kìí sábà wáyé, sùgbọ́n ọkùnrin náà tó ni ìyàwó nílé ni wọ́n ti ni o jẹ̀bi ikú àti pé wọ́n ni láti sọ ọ́ lókuta pa ni gẹ́gẹ́ bi ìlànà òfin Sharia lórí irú ìwà bẹ́ẹ̀.

Ẹ̀wẹ̀, agbẹnusọ náà ni, bàbá náà ni ẹ̀tọ́ láti lọ sí ilé ẹjọ kòtẹmilọ́run lórí ọ̀rọ̀ náà láàrín ọgbọ̀n ọjọ́.

Èyí ni ìdájọ ikú ẹlẹ́keejì ti ilé ẹjọ́ Sharia yóò dá láàrín ọ̀sẹ̀ kan ní ìpińlẹ̀ Kano.

Mo ti kọ Yusuf Aminu (Baban Gona) tẹ́lẹ̀, Mo ṣetan láti wa fàá le yin lọ́wọ́ funra mi

Oríṣun àwòrán, Others

Mo ti kọ Yahaya-Shariff Aminu (Baban Gona) lọ́mọ tẹ́lẹ̀- Bàbá Yahaya

Bàbá ọmọ ti ilé ẹjọ́ Sharia ní ìpińlẹ̀ Kano dájọ́ ikú fún sọ pé, òun ti kọ ọmọ òun lọ́mọ́ nítorí, òun ko fara mọ́ ki ènìyàn máá ri orúkọ ọlọrun fin.

O sàpèjúwe ìwà to hù gẹ́gẹ́ bi èyí ti kò bá ìlànà ẹ̀kọ́ Islaamu mu.

Ìròyìn sọ pé, ọgbẹ́ni Shu'aibu ṣe àbẹ̀wòsí ilé iṣẹ ọlọ́pàá Hisbah nípìnlẹ̀ Kano lásìkò ti ìṣẹ̀lẹ̀ náà kọ́kọ́ jẹyọ ó ní ọmọ òun Yahaya Shariff Aminu (Baban Gona) kò si nínú ilé òun lásìkò tó hùwà ọdaran.

O fi kún-un pé, òun pẹ̀lú kò faramọ́ ìwà ti ọgbẹ́ni Baban Gona hù pàápàá nílànà ẹ̀sìn.

Bákan náà ni bàbá rẹ̀ dúpẹ lọ́wọ́ àwọn Hisbah fún ìgbésẹ̀ oní wàrànsesà ti wọ́n gùnlé láti dáàbò bo ẹmí òun àti àwọn ẹbí òun lásìkò ti àwọn ọdọ́ wa kógun bá òun nílé ti wọ́n si dána su ilé òun.

Sharia Law: Àwọn ǹkan tí ó yẹ kí o mọ̀ nípa 'Sharia Law' í Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Others

Àwọn ọmọ Nàìjíríà kò sinmi láti ànà lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ Sharia kan ní ìpínlẹ̀ Kano dá ẹjọ́ ikú fún ọdọ́mọkùnrin ẹni ọdún méjìlélógún kan lórí ẹ̀sùn pé ó sọ̀rọ̀ ódì sí ẹ̀sìn Islam.

Àwọn ọmọ Nàìjíríà sì ti ń gba ọ̀rọ̀ náà bí ẹni gba igbá ọtí.

Ìdí rèé tí a fi ni kí a tan ìmọlẹ̀ sí àwọn ǹkan ti o yẹ kí ẹ mọ̀ nípa òfín Sharia.

Ní ọdún 1999 ni òfin Sharia bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà nígbà ti gómìnà ìpińlẹ̀ Zamfara nígbà náà lọ́hùún, Ahmed Sanni Yerima pè fún lílo òfin Sharia láwọn ìpińlẹ̀.

Ṣùgbọ́n nígbà ti ó di ọdún 2000, àwọn ìpínlẹ méjìlá ní ìhà Àríwá ló ti darapọ̀ mọ́ ètò ọ̀hún, bákan náà ni wọ́n ṣe àfikún láti maa fi òfin Sharia dá ẹjọ́ tó bá níṣe pẹ̀lú ìwà ọ̀daràn.

Láti ìgbà yìí si ni ọ̀pọ̀ àwọn égbẹ́ ajàfẹ́tọ́ ọmọniyan ti ń rọ ijọba láti dá sí ìgbésẹ̀ àwọn to ṣe àgbékalẹ̀ yìí nítori ní ọ̀pọ̀ ìgbà ní ìdájọ Sharia máa n tẹ òfin ẹtọ ọmọniyan lójú mọ́lẹ̀.

Ìpínlẹ̀ méjìla tó di òpó ìhà aárèwá mu ní wọ́n ti ń lo òfin Sharia, àwọn musùlùmí to sì wà ni àwọn ìpínlẹ̀ yìí nikan ni òfin Sharia le báwí.

Báwo ni wọ́n ṣe ń lo òfin Sharia?

Sáájú àsìkò yìí, ẹsẹ tó bá niṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ara ẹni tí a sì gbé ẹjọ́ náà wá sọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ Islam nìkan ní wọ́n ń lo Sharia fún.

Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ bíi kí ènìyàn ṣe àgbere (Zina), èyí túmọ sí pé tí wọ́n bá ka ọkùnrin tàbi obinrin mọ́ níbi ìbálòpọ̀ ti kìí sì ṣe pẹ̀lú ọkọ tàbi aya wọ́n.

Bákan náà ni bí ènìyàn bá muti tabi jale, ìdájọ Sharia ni wọ́n yóò dájọ́ fún irú ẹni bẹ́ẹ̀.

Bakan náà àwọn ìjìyà ti òfin Sharia mú daní lé jẹ́ sísọ ènìyàn ni okúta pa.

Wọ́n máa ń lo òfin Sharia láti sàmójútó ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó àti ogún pínpín láàrín àwọn Musulumi.

Kíni ìpílẹ̀ òfin Sharia?

•Kurani

•Sunna (ìyẹn ojúlówó hadiit)

•Qiyas (Èrò pípé àwọn onímọ)

•Ijma ( eyi ni ìfẹnukò èròngbà àwọn onímọ òfin )

•Àwọn ilé ẹkọ́ ìmọ̀ òfin bi Hanafi, Mailki, Shafi'i Hanbali àti Jafari, àwọn yìí ni wọ́n ń ṣètò bi wọ́n ṣe mú àwọn ìlàna tí wọ́n fi n lo òfin Sharia jade nínú Kùránì

•Mu amalat ( ìbásepọ àwujọ

•ibadat (etutu)

Àkọlé fídíò, jkkkkk

Báwo ni òfin Sharia ṣe n ṣiṣẹ́ ni Naijiria?

Ìpínlẹ̀ méjìlá ni Sharia tí ń ṣiṣẹ́ ni Naijiria, àwọn musùlùmí nìkàn ní wọ́n le ṣe ìdájọ́ wọ́n níbẹ̀.

Àṣà Sharia ní ilé ẹjọ́ kòtẹmilọ́rùn tirẹ̀, ti wọ́n si máa n gbọ́ ẹjọ́ to níṣe pẹ̀lú ẹsìn, ìwà ọ̀daran àti láàrìn àwọn mùsùlùmí síra wọ́n.

Bákan náà ni ẹni ti wọ́n bá dá lẹ́jọ́ ní ilé ẹjọ́ Sharia le pé ẹjọ́ kòtẹmilọ́run tàbi ilé ẹjọ́ tọ ga jùlọ ní àwọn ilé ẹjọ́ ìjọba orílẹ̀-èdè Naijiria.

Àkọlé fídíò, Sextuplet: Àdúrà Ìbùkún ló kú lẹ́yìn ọmọ mẹ́fà yìí- Ifeoma Thelma àti Onyemaechi Chiaka

Adájọ́ ilé ẹjọ́ Sharia ti wọ́n ń pe ni Alkali maa n ni ẹkọ ìmọ̀ Islam àti ti ìgbàlódé.

Ẹjọ́ to bá pa mùsùlùmí àti ẹni ti kìí ṣe musulumi pọ̀, mùsùlùmí náà ni àṣẹ láti sọ ibi ti ó fẹ́ ki ìgbẹ́jọ́ náà ti wáyé.

Àwọn ìdájọ́ ti ilé ẹjọ́ Sharia máa n ṣe ni Fífún ènìyàn lẹ́gba, Gígé apá tabi ẹsẹ̀ ènìyàn, idájọ́ ikú tàbí kí wọ́n sọ ènìyàn lókuta pa.Gbogbo ìdájọ dá lórí irú ẹ̀ṣẹ tí ènìyàn bá ṣẹ̀.

Protesters

Oríṣun àwòrán, Idris Ibrahim

Wo ohun tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń sọ lórí dájọ́ ikú Yahaya Sharif-Aminu tó gba ìdájọ́ ikú lórí ẹ̀sùn ọ̀rọ̀ òdì sí Ànọ́bì

Awọn ọmọ Naijiria ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori itakun agbaye lẹyin ti ile ẹjọ Sharia kan ni ipinlẹ Kano ṣedajọjọ iku fun Yahaya Sharif-Aminu lori ẹsun pe o sọrọ odi si Anọbi.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe ile ẹjọ Sharia ko lagbara lati ṣedajọ iku fun eeyan ni Naijiria nitori ofin ijọba apapọ ni Naijiria n lo, lawọn miran n sọ pe ile ẹjọ naa ko ṣe daadaa to.

Bẹẹ lawọn eeyan mii naa n sọ pe ko si ẹnikẹni to lẹtọọ lati sọrọ odi si Anọbi.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Bashir Ahmad to jẹ oluranlọwọ fun aarẹ Buhari lori ọrọ ayelujara ti fi soju opo twitter rẹ pe oun faramọ idajọ iku fun Yahaya Sharif.

O ni oun ko ni dakẹ lori igbagbọ oun nitori olorin naa gbe Imaamu ga ju anabi Muhammed lọ, o yẹ fun ikú ni.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Awọn kan tilẹ ti n tọwọ bọwe lori itakun chanage.org pe ko kan an nipa fun ijọba apapọ lati da ẹsun ọrọ odi ni Naijiria.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Muhsin Ibrahim ni ko si Musulumi ododo to yẹ ko sọrọ odi si Anọbi labẹ bo ti wu ko ri.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Àkọlé fídíò, BBC Africa Eye: ìwádìí ìkọ̀ks BBC fihàn pé àwọn kan ń jí ohun èèlò ìdáàbòbò ìjọba tà nígbo

Uloma ni tirẹ sọ pe iwa iṣerubalu ni ki wọn maa mu eeyan fun ẹsun isọro odi.

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

Ninu ero Ava, o ni ẹnikẹni to ba fi ọwọ si pe ki wọn yẹgi fun arakunrin ọhun ko yẹ ni ẹni to yẹ ko maa gbe papọ pẹlu awọn ọmọ Naijiria tootọ.

Skip X post, 6
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 6

Ẹ wo awọn ohun miran ti awọn ọmọ Naijiria n sọ nipa idajọ Ọhun.

Skip X post, 7
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 7

Skip X post, 8

End of X post, 8

Skip X post, 9

End of X post, 9

Skip X post, 10

End of X post, 10

Skip X post, 11

End of X post, 11

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa olórin tí wọ́n dájọ́ ikú fún ní Kano

Protesters

Oríṣun àwòrán, Idris Ibrahim

Ọjọ Aje, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹjọ, ọdun 2020 ni ile ẹjọ kan ni Kano se idajọ iku fun ẹnu ọdun mejilelogun kan lori ẹsun pe o bá orúkọ Anọbi Muhammed jẹ́.

BBC ṣe agbeyẹwo igbeaye arakunrin naa, ohun ti mọ nipa rẹ ree:

Wọn bi Yahaya Sharif-Aminu sinu ẹbi Mallam Aminu Sha'aibu Sharifai to jẹ onimọ nipa ẹsin Musulumi lagbegbe Sharifai, ni ilu Kano.

O bẹrẹ ileewẹ alakọbẹrẹ ni Goat Primary School, to wa lagbegbe Koki, lẹyin naa lo ṣe idanwo onipele ikẹta akọkọ ni GATC ni Gwale.

Ko tẹsiwaju ẹkọ rẹ mọ lẹyin to kuro nile iwe girama, ṣugbọn o bẹrẹ si n ṣiṣe sobata.

Yahaya tun kẹkọọ nipa imọ ẹsin Islam, o si sọ pe baba oun lo kọ oun gẹgẹ bii Shaykh.

O jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ Faira ni Tijjaniya, o si maa n gbadura nigba marun un lojumọ.

Yahaya da ẹgbẹ kan silẹ lori ikanni WhatsApp fun awọn eeyan to ni ifẹ Anọbi Muhammed, o pe orukọ ẹgbẹ naa ni "Umma Abiha."

Matasa na zanga-zanga

Oríṣun àwòrán, IDRIS IBRAHIM

Ṣugbọn lọjọ Abamẹta, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2020, ni ọkunrin kan bu ẹnu atẹ lu awọn ọmọ ẹgbẹ Tijjaniya ti Yahaya jẹ ọkan lara wọn lori ikanni WhatsApp ọhun lẹyin ti Yahaya sọrọ abuku si Anọbi, o si tun ka ọrọ Yahaya silẹ lor tẹlifoonu rẹ.

Ọrọ odi to sọ yii lo sọ ọ di ẹni to n kawọ pọn rojọ niwaju adajọ ile ẹjọ Sharia ki wọn to dajọ iku fun un.

Àkọlé fídíò, Alaafin: Olori Aanu Adeyemi ṣàlàyé ìdí tó ṣe gẹ́ Oba Lamidi Adeyemi ti ìlú Oyo

Agbẹnusọ ile ẹjọ giga ilu Kano sọ fun BBC pe, arakunbrin ọhun lẹtọ lati pe ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ iku naa.

Oṣu kẹta ọdun 2020 ni awọn ọdọ kan ni Kano ti kọkọ ṣe ifẹhonuhan lori iru ijiya to yẹ Yahaya nitori ọrọ odi to sọ si Anọbi.

Wọn si tun dana sun ile awọn obi rẹ lagbegeb Sharifa ni Kano nitori ẹsun kan naa.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Olórin ọmọ Nàìjíríà kan gbà ìdájọ́ ikú fún bíba orúkọ Anọbi Muhammed jẹ́

Idajọ Iku

Ilẹ́ ẹjọ́ Sharia kan ni ìpińlẹ̀ Kano ti dájọ ikú fún olórin kan to jẹ́ ẹni ọdún méjìélógún nítori pé o bá orúkọ Anọbi Muhammed jẹ́ nipa gbigbe orukọ Imaamu kan ga ju ti Anọbi Muhammed lọ ninu orin rẹ.

Igbẹ́jọ́ ilé ẹjọ́ Sharia náà sọ pé Yahaya Sharif-Aminu jẹ̀bi ẹ̀sùn pé orúkọ Anọ́bi Muhammed lọ́nà àìtọ́ nínú orin rẹ̀ tó ń jà rànyìn lóri "Whatsapp" nínú oṣù kẹta ọdún yii.

Olórin náà tó ti wà látìmọ́lé báyìí ti pé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lòdì sí ìgbẹ́jọ́ náà.

Àkọlé fídíò, Teach your children Yoruba: Wo àwọn òyìnbó tó ń kẹ́kọ̀ọ́ èdè Yorùbá ní Michigan, America

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lẹ́yìn ti orin náà jáde ni wọ́n ti mu ọmọkunrin olórín ọhun.

Ọ̀pọ̀ àwọn afẹ̀hónúhàn ló ti lo dáná sun ilé ẹbi àwọn ọmọkùnrin náà ti wọ́n sì ń péjọ síwájú ilé iṣẹ́ ọlọpàá Islam ti a mọ sí Hisbah pé a fi ti wọ́n bá ṣe ìdájọ́ to yẹ lórí ọmọkùnrin ọ̀hún.

Àwọn alátakò olórín náà ni pé, ó fi Anọ́bi wọlẹ̀ ni nítori pé ó gbé orúkọ Imamu kan ga jú orúkọ Ànọ́bì Muhammed lọ`

Àkọlé fídíò, Ìdílé tí ọkọ da ọmọ síta tóríi ojú Búlùú tí wọ́n ní bá BBC sọ̀rọ̀