Peter Adeeko helping military widows: Wo bí ọkùnrin ọmọ òrukàn yìí ṣe ń ran àwọn opó tí ọkọ wọn kú sójú ogun lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Wo bí ọkùnrin ọmọ òrukàn yìí ṣe ń ran àwọn opó tí ọkọ wọn kú sójú ogun lọ́wọ́
Kekere ni Peter Adeeko wa ti ibọn fi ba baba rẹ loju ogun, eyii to sọ baba rẹ di ẹni ti ko le e dide kuro lori ibusun rẹ ko to di pe o dagbere faye lẹyin ọdun diẹ si.
Ko pe si asiko yii ti iya rẹ naa dubulẹ aisan, ti oun naa si dagbere faye.
Iya to jẹ Adeeko kii ṣe diẹ, ọpọ igba si ni kii ri ounjẹ alẹ jẹ, ṣugbọn ni igbẹyingbẹyin, o ru u la o si kawe gboye.
Nigba to di ọdun 2015, o kọwe fi ipo rẹ silẹ nibi to ti n ṣiṣẹ lati maa ṣetọju awọn eeyan ti iya n jẹ nitori awọn ẹbi wọn ba ogun lọ.
Ni ọdun 2015, o gbe ajọ kan ti kii ṣe ti ijọba kalẹ, eyii to pe "Soulace Africa" pẹlu afojusun lati ṣadinku ipa ti ogun n ko ninu aye awọn eeyan, paapaa ni Naijiria.
Laarin ọdun meji si asiko naa, Adeeko ti tun igbe aye awọn opo bii gba ati aadọta ti ọkọ wọn ku soju ogun ṣe, to pa wọ́n lẹ́rin ayọ̀ pẹlu iranlọwọ.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, o ni ohun to wu oun lọkan lati ṣe ni lati kọ ileegbe fun awọn opo ti ọkọ wọn ti ba ogun lọ.
O ni "Mo n fẹ awujọ ti awọn eeyan ko ti ni maa ta awọn opo awọn akọni to ti ba ogun lọ sẹyin."
"Ṣaaju ọdun 2018, mo ri pe awọn eeyan maa n ta wọn sẹyin, idi ree ti mo ṣe fi ara mi jin lati maa gbọ tiwọn."
Adeeko ni pupọ ninu awọn opo ọhun ni ko rọwọ họri tẹlẹ, ṣugbọn oun ti gba lati yi igbe aye wọn pada.
O ṣalaye nipa obinrin kan ti ọkọ rẹ ti di awati lati nnkan bi ọdun mẹsan an sẹyin, ṣugbọn lẹyin ti ajọ to gbe kalẹ ṣabẹwo si obinrin ọhun, ti wọn kọ ọ niṣẹ ọwọ, igbe aye rẹ ti yipada,

Oríṣun àwòrán, NIGERIAN ARMY
Adeeko ni iru awọn iriri bayii lo maa n dun oun ninu, to si maa n ru oun soke lati tẹsiwaju nipa ṣiṣe iranlọwọ fun awọn eeyan naa.















