Recruitment Nigeria Army form: Wo àmúyẹ kí o tó lè di ọmọ ogun ilẹ̀ Nàìjíríà pẹ̀lú fọ́ọ́mù tó jáde yìí

Awon ologun

Oríṣun àwòrán, Nigeria army

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Fọọmu atigba ni si iṣẹ ologun ọmọ ogun ilẹ ni Naijiria ti jade.

Gbogbo ẹyin ti ẹ ro pe ẹ le tun ṣe ju bi awọn to n ṣe wa nibẹ yii, ẹ jade wa gba fọọmu lati darapọ mọ awon ọmọ ogun ilẹ ni Naijiria.

Saaju ni ọpọ ọmọ Naijiria ti n poungbẹ lori asiko ti fọọmu ati gba ni siṣẹ ọmọ ogun ilẹ yoo jade ki awọn le darapọmọ wọn maa fọ orilẹ-ede yii mọ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Wo amuyẹ ti o gbọ́dọ̀ ni ki o to le gba fọ́ọ́mù:

  • O ni lati jẹ ọmọ ọdun mẹtalelogun si mẹtadinlọgbọn nigba to ba maa fi di oṣu kinni ọdun 2021.
  • O ni lati jẹ akẹkọọ jade fasiti tabi ile iwe gbogboniṣe.
  • O ko gbọdọ ni ni ami kọkan lara tabi ya "tattoo."
  • O ko gbọdọ jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun Kankan.
  • O ti gbọdọ pari eto isinru ilu agunbanirọ pẹlu ojulowo iwe ẹri lọwọ..
Àkọlé fídíò, Akomolede ati asa Yoruba: Ẹ wá kọ́ nípa àpòtí ìṣura èdè wa lórí BBC Yorùbá

Awọn ohun ti o nilo lati fi orukọ silẹ niyii:

  • Aworan pelebe.
  • Awọn iwe ẹri pe o kawe.
  • Iwe ẹri ilu ti wọn ti bi ọ.
  • Iwe ẹri to n ṣafihan iye ọjọ ori rẹ.

https://recruitment.army.mil.ng/ oju opo yii ni o ti le fi orukọ silẹ gẹ́gẹ́ bii ọmọ ogun ilẹ.

Awọn igbesẹ yii nii o ni lati gbe lati fi orukọ silẹ:

  • Lọ si oju opo yii: https://recruitment.army.mil.ng, lẹyin naa, mu ipele tabi ẹka ti o ba fẹ darapọ mọ ninu SSC tabi DSSC.
  • Lẹyin naa ni o maa lọ ka awọn ohun amuyẹ to yẹ ki o ni lati darapọ mọ SSC tabi DSSC naa.
  • Tẹ "Apply now" lati fi orukọ silẹ fun SSC tabi DSSC gẹgẹ bi amuyẹ ti o ni.
Awon ologun

Oríṣun àwòrán, Nigerian army

Ọ̀fẹ́ ni iforukọsilẹ:

Lẹyin naa ni ki o ti ọwọ bọ fọọmu to wa nibẹ. Lati sisẹ lori fọọmu naa, o nilo foto pelebe, awọn iwe ẹri ileewe ti o lọ, ẹri idanimọ gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ akọṣẹmọṣẹ kankan ti o ba ni, iwe ẹri lati ipinlẹ ti o ti wa, iwe ẹri ọjọ ori tabi iwe ibura ọjọ ori rẹ.

Dandan ni fun gbogbo ẹni to ba fi orukọ silẹ lati tẹ ìwé pelebe to ni fọto jade, lẹyin ti wọn ba kọ akọsilẹ sori fọọmu naa tan.