Mamman Daura: Ojú òpó ayélujára ń gbóná lórí ìlàkàkà ọmọ Nàíjíríà láti mọ́ ipò tí ìlera rẹ̀ wà

Muhammadu Buhari ati Mamman Daura

Oríṣun àwòrán, Others

Lowurọ ọjọbọ ni oju opo Twitter n gbona fẹlifẹli pklu ibeere awọn ọmọ ilẹ yii pe, ki ileesẹ aarẹ se alaye lori irinsi Daura.

Yoruba ni ti ko ba si ina, eefin kii ru, ibeere awọn ọmọ Naijiria ko sẹyin iroyin kan to jade laipẹ yii pe ara ibatan aarẹ naa ko da, ti wọn si ti gbe digbadigba lọ sile iwosan.

Idi ree ti BBC fi tiraka lati wa okodoro ọrọ nileesẹ aarẹ lati mọ ibi ti Mamman Daura wa, ati pe se lootọ ni o n se aisan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn eeyan kan to ba BBC sọrọ nileesẹ aarẹ amọ ti wọn ko fẹ darukọ wọn ni ibatan aarẹ naa rinrinajo lọ silu oyinbo lootọ, amọ kii se oun nikan lo lọ.

Mamman Daura

Oríṣun àwòrán, Others

Ohun ta gbọ nipa Mamman Daura lati ileesẹ aarẹ:

  • Wọn ni Daura lọ silẹ United Kindom pẹlu iyawo ati ọmọ rẹ meji, ọkan ọkunrin, ti ekeji si jẹ obinrin.
  • Bakan naa ni wọn ni baalu ọkọ adani ni wọn haya fi rin irin ajo ọhun.
  • Ko tan sibẹ o, onitọun tun fikun pe, saka ni ara Daura ya, ti ko si se ojojo kankan.
  • Bakan naa lo ni Daura bawọn peju sibi eto isinku agbẹnusọ tẹlẹ fun aarẹ Buhari to jade laye, Wada Maida lọjs Isẹgun.
  • Onitọun ni o ti pẹ ti awọn ẹbi rẹ ti n gbero lati rin irinajo si UK amọ ti Daura fi aake kọri pe oun ko lọ si ibi kankan nitori igbele Coronavirus to wa nita.

Sibẹ, sibẹ, lai naani awọn alaye yii, ẹnu si n kun Mamma Daura loju opo ayelujara nipa ilera rẹ, bo ba si se jẹ, BBC Yoruba yoo maa mu ẹkunrẹrẹ iwadi wa wa fun yin.