Coronavirus Update in Namibia vs elephant: Ṣé òótọ́ ni pé ìgbẹ́ erin le è wo arùn Covid-19 sàn?

Oríṣun àwòrán, others
Ibeere nla to gab ọkan awọn eeyan orilẹ̀-ede Namibia ni ilel Afrika ni yii
Minisita eto ilera orilẹ-ede Namibia, Kalumbi Shangula ti kilọ fun awọn ọmọ orile¬̣-ede naa pe ki wọn sọra fun lilo igbẹ erin fun iwosan arun Covid-19.
Ṣaaju ni awọn oniwosan ibilẹ kan ti kọkọ sọ pe igbẹ erin le e koju aisan ọfinkin, ori fifọ ati lati dawọ ẹjẹ to n ṣan lati imu duro ti wọn ba le e gbe igbẹ naa gbona ki wọn si fi imu.
Ṣugbọn ko tii si ẹni to tii fi idi igbesẹ naa mulẹ ninu imọ sayẹnsi pe o lagbara lati wo ikọkan ninu awọn aisan ọhun.
Shangula ni omi inu n kan oun pe awọn kọlọrọsi kan le e gba owo lọwọ awọn eeyan fun awọn oogun tabi iwosan ti ko ṣiṣẹ.
- Adamu Adamu, Minista ètò ẹ̀kọ́ ti fi òfin àátẹ̀lẹ́ síta kí àwọn ilé ìwé lè wọlé
- Ikú Williams Aanuoluwa lágbo òṣèré hú ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ síta
- Boko Haram ṣọṣẹ́ ní Borno, wọ́n sé àwọn èèyàn mọ́lé ní Kukawa
- Wo ìdí tí Osun fi kede ìsinmi fún ọdún ìṣẹ̀ṣe, tàwọn ìpínlẹ̀ yókù kò dáhùn,
- Ilé ẹjọ́ yá lórí òfin CAMA tó fẹ́ gba àkóso ilé ìjọsìn, tẹ ẹ̀tọ́ aráàlú mọ́lẹ̀ - SERAP
Lọwọ yii, eeyan 4,464 lo ti lugbadi arun Coronavirus ni Namibia, ti awọn mẹtadinlọgbọn si ti jẹ Ọlọrun nipe.
Ọ̀rọ̀ coronavirus to je ajakale arun yii ni awọn oirlẹ-ede kan ti n bọ lọ́wọ́ re ti awọn mii si n ba jagun bayii

Oríṣun àwòrán, others
Titi di asiko yii ni ajọ eleto ilera agbaye WHO ni ko tii si oogu ati abẹrẹ ajẹsara kan ni pato ti iṣẹ ti pari lori é to le wo ajakale arun Covid 19 san bayii
- Mo fẹ́ kí Ọlọ́run fún wa ní ọmọ olójú búlúù si lẹ́yìn yìgì - Ọkọ olójú búlúù
- Afurasí lórí ikú Tolulope Arotile ti dé ilé ẹjọ́, èyí ni ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án
- Ẹ̀yin gómìnà, Ifá nìkan ló le tọ yín sọ́nà láì kùnà lórí Amotekun - Babaláwo
- Kí ló ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ sí Mamman Daura àti ìlera rẹ̀?
- Ọdún Hijri mùsùlùmí tuntun wọlé dé, ẹ wo kókó pàtàkì nípa rẹ̀















