Russia Covid 19 Vaccine: Ẹ wo ohun tó yẹ kí ẹ mọ̀ nípa oògùn 'Sputnik V' Russia tó ń wo àrùn Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Reuters
Aarẹ orilẹ-ede Russia, Vladimir Putin ti kede oogun 'Sputnik V' gẹgẹ bi oogun tuntun to n sawotan arun Coronavirus.
Lẹyin Oṣu meji ti wọn ṣe ayẹwo oogun naa ni ara eniyan lo gba ontẹ ijọba gẹgẹ bi oogun to n sawotan arun Coronavirus.
Aarẹ Putin ni oogun 'Sputnik V' lo ti gba gbogbo ontẹ ijọba lẹyin ọpọlọpọ ayẹwọ ti wọn ṣe, ti o si fihan pe, a jẹ bi ewe ni oogun naa.
Orilẹ-ede Russia ri eyi gẹgẹ bi aṣeyori nitori awọn ni wọn kọkọ pese oogun to n se iwosan fun aarun Coronavirus ni agbaye.

Oríṣun àwòrán, Reuters
- Sextuplet: Àdúrà Ìbùkún ló kú lẹ́yìn ọmọ mẹ́fà yìí- Ifeoma Thelma àti Onyemaechi Chiaka
- Joe Biden kéde Kamala Harris, obìnrin aláwọ̀ dúdú gẹ́gẹ́ bí igbákejì rẹ̀ nínú ìdíje sípò Ààrẹ Amẹrika
- Wo ìdí tí Risikat Moromoke Azeez n'Ilorin fi ní "Blue Eyes" - Dókítà
- NCDC kéde èèyàn 423 míràn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lùgbàdì Covid-19 ní Nàìjíríà, 263 gbàwòsàn
Ohun tí a mọ̀ nípa òògùn 'Sputnik V' tí Russia tó ń wo àrùn Coronavirus
Ọsẹ to kọja ni ijọba orilẹ-ede Russia fi lede wi pe awọn n pese abẹrẹ ajẹsara ọlọgọọrọ lati koju arun Coronavirus, bẹrẹ lati Oṣu Kẹwaa.
Awọn onimọ sayẹnsi ni orilẹ-ede Russia ni ayẹwo ti awọn kọkọ ṣe fun oogun naa fihan pe oogun naa yoo ṣiṣẹ fun arun Coronavirus.

Oríṣun àwòrán, EPA
Ajakalẹ arun ''adenovirus'' ti o maa n sokunfa ikọ hihu ati otutu ni wọn lo lati fi ṣe oogun naa ti yoo mu ki eroja 'immune' ara ko gbokun sii.
- Coronavirus: Ewu wo làwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlèra ń kojú ní Nàìjíríà?
- Báwó ni òògùn dexamethasone ṣe ń ṣiṣẹ́ lára
- Wo ìdí tí Risikat Moromoke Azeez n'Ilorin fi ní "Blue Eyes" - Dókítà
- Asojú ìjọba orílẹ̀-èdè Lebanon ti kọ̀wé fipò silẹ̀ nítorí ìbágbàmù tó gbẹ̀mi ènìyàn 200
- Àjọ JAMB kéde ìlànà ìgbà ni wọlé tuntun fún àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga
- Link
Amọ, Ajọ Eleto Ilera lagbaye, WHO ni oogun 'Sputnik V' ko i tii si lara awọn oogun arun Coronavirus mẹfa lagbaye, ti wọn ti kọja ipele ikẹta ayẹwo rẹ lara awọn eniyan.












