US Presidential Election: Ṣé ìrànwọ̀ ni Kamala, ìgbákejì tí Biden yàn yóò jẹ́ fún un tàbí ìpalára?

Biden ati Harris

Oríṣun àwòrán, @CryptographyAC_

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Nigba mii, yiyan eeyan fun nkan maa n nidi.

Kamala Harris lo leke ju lati jẹ igbakeji Joe Biden ọkan lara awọn oludije ipo aarẹ Amẹrika to wa lẹgbẹ oṣelu Democrat latinu oṣu kẹta to ti kede pe obinrin ni oun yoo yan gẹgẹ bi igbakeji oun.

Nisisiyii to ti wa di igbakeji Biden ti wọn yoo jọ dije, o tun ti di ẹni ti ipo aarẹ tọ si yala lẹyin ọdun mẹrin bi Joe Biden ba fidirẹmi tabi ti ko gbapoti ibo lẹlẹẹkeji ninu oṣu kejila ọdun naa fun atunyan gẹgẹ bii aarẹ tabi lẹyin ọdun mẹjọ bi Biden ba ṣe saa ijọba meji.

Eyi gan an lo fa a to dabii pe wọn gbiyanju lati ja Harris walẹ tabi yan oludije mii lati oṣu melo kan sẹyin.

Ṣugbọn nibayii, ẹsẹ Harris ti baba wa lori afara idije naa.

Ẹwẹ, ohun to mumu lookan aya ẹgbẹ Democrat bayii ni boya Harris yoo jẹ oluranlọwọ fun Biden lati jawe olubori.

Ta ni Kamala Harris yii?

Harris ti baba rẹ jẹ ara Orilẹ-ede Jamaica ti iya rẹ si wa lati India lo di obinrin ẹya alawọdudu Asia akọkọ lati wa lorii tikẹẹti ẹgbẹ oṣelu pataki fun aarẹ.

Ati pe lẹni ọdun marunlelaadọta, ko fibẹẹ kere bi a ba wo o si Joe Biden ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin, oun ṣi kere jọjọ.

Lara Iṣẹ igbakeji aarẹ ni lati maa koju awọn alatako, itan si fihan pe Harris to gbangbaa sun lọyẹ niruu nkan bayii.

Àkọlé fídíò, Alaafin: Olori Aanu Adeyemi ṣàlàyé ìdí tó ṣe gẹ́ Oba Lamidi Adeyemi ti ìlú Oyo

Biden ranti pe Harris lo gba ti oun lẹyin pẹlu gusto lasiko ifọrọwerọ abẹle ti Democratic ninu oṣu keje ọdun 2019 to tako bi oun (Biden) ṣe lodi si iwa iyanisọtọ lawọn ileewe ijọba.

Bakan naa, Harris jẹ ẹni ti ẹ o le wa ọrọ ti lẹnu ẹ koda Donald Trump gan ti gbọ iṣẹẹ rẹ wo ri.

Bo tilẹ jẹ pe ati dije ipo aarẹ Harris lọdun 2020 ko yọri si rere to si juwọọlẹ ṣaaju ọpọ awọn ti wọn jọ n du u, o ṣi mọ itumọ wiwa labẹ iru ayẹwo bẹẹ.

O ti la ina yẹn kọja daadaa tori naa to ba tilẹ lẹbọ lẹru gẹgẹ bii oludije, yoo ti hande bayii.

coronavirus

Toripe o ti wa du ipo aarẹ ri, ko jẹ aiṣeeṣe bi ọpọ ara Amẹrika ba ri i bi aarẹ lọjọ ọjọ kan.

Oun gẹgẹ bii Sẹnetọ ilu California, bi ko tilẹ tii ṣaṣeyọri lawọn idije rẹ kọọkan, nibayii o ti di ilumọọka.

coronavirus

'Ọlọpaa ni Harris'

Ju ọpọlọpọ oludije igbakeji aarẹ lọ, Harris ni ibẹrẹpẹpẹ gẹgẹ bii agbofinro eyi si jẹ jade daadaa ninu awọn ibeere ti wọn bi i lasiko ifọrọwerọ. Koda o ṣiṣẹ agbofinro de bi oye Attorney niSan Francisco ati Attorney general ni California.

Biden ati Harris

Oríṣun àwòrán, @Ostrov_A

Joe Biden kéde Kamala Harris, obìnrin aláwọ̀ dúdú gẹ́gẹ́ bí igbákejì rẹ̀ nínú ìdíje sípò Ààrẹ Amẹrika

US elections: Joe Biden kéde Kamala Harris, obìnrin aláwọ̀ dúdú gẹ́gẹ́ bí igbákejì rẹ̀ nínú ìdíje sípò Ààrẹ Amẹrika

Oludije sipo Aarẹ ilẹ Amẹrika ninu ẹgbẹ oṣelu Democrat, Joe Biden ti yan obinrin alawọ dudu, Kamala Haris gẹgẹ igbakeji rẹ ti wọn yoo jọ dije.

Bo ti tilẹ jẹ pe ipo Aarẹ ni oju Kamala wa tẹlẹ oun ni aṣayan awọn agba ẹgbẹ ninu oṣelu naa yan gẹgẹ bi i igbakeji.

Arabinrin ọhun ni adajọ agba ipinlẹ California tẹlẹ, nibi to ti n lọgun atunṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa lataari oriṣiriṣi iwọde to waye lodi si iwa ẹlẹyamẹya.

Joe Biden ni yoo gbena woju Aarẹ Donald Trump ninu idibo sipo Aarẹ ilẹ naa ti yoo waye lọjọ kẹta, oṣu Kọkanla, ọdun 2020.

Kamala yoo koju igbakeji Donald Trump, iyẹn Mike Pence lọjọ keje, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 kan naa ninu itakurọsọ awọn oloṣelu ti yoo waye ni ilu Salt Lake, ni Utah.

Biden ati Harris

Oríṣun àwòrán, @CryptographyAC_

Obinrin meji pere ni wọn tii fa kalẹ lati dije sipo igbakeji Aarẹ ninu itan ilẹ Amẹrika.

Ẹni akọkọ ni Geraldine Ferraro lati inu ẹgbẹ Democrats lọdun 1984, ti ẹnikeji si jẹ Sarah Palin lati inu ẹgbẹ oṣelu Republican lọdun 2008.

Ko si ninu awọn ẹgbẹ oṣelu mejejeji to lamilaaka l'Amẹrika to tii yan obinrin alawọ dudu lati dije du ipo Aarẹ.

Bakan naa ni obinrin kọkan ko tii jaweolubori ninu idibo sipo Aarẹ ninu itan Amẹrika.

Àkọlé fídíò, Alaafin: Olori Aanu Adeyemi ṣàlàyé ìdí tó ṣe gẹ́ Oba Lamidi Adeyemi ti ìlú Oyo

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Aàre Donald Trump pàrọwà pé kí wọ́n sún ọjọ́ ìdìbò dí ọjọ́ míràn nítorí Covid 19

Trump

Oríṣun àwòrán, @GeigerNews

Aare Donald Trump to n tukọ orilẹ-ede America ti parọwa fun awọn ikọ to n seto idibo naa lati sun un siwaju kuro ni osu kọkanla, ọdun 2020 to yẹ ko waye.

Trump ni o yẹ ki wọn sun ọjọ idibo naa siwaju sii nitori ajakalẹ arun coronavirus to n ab gbogbo agbaye finra lati ibẹrẹ ọdun yii.

O tun salaye pe o yẹ ko waye lọ́jọ mii ọj ire nitori pe ki magomago kankan ma baa wa ye lataari awọn to maa fẹ dibo nipa ifiransẹ si awọn to n seto idibo naa.

O ni ti wọn ba sun idibo naa siwaju, America yoo ti fẹ́ bọ́ tan lọwọ isoro Covid 19 to n jẹ ki awọn eeyan maa gbe ni ewu ati pelu ifura.

Ẹ̀rí diẹ wa lara ibeere Aare Trump lasiko yii nitori pe Orilẹ-ede America ti fẹ́ safikun si ọna idibo nipa fifi ransẹ nitori Covid 19 ninu idibo osu kọkanla naa.

Labẹ ofin America, Aare Donald Trump ko lasẹ lati yi ọjọ idibo naa pada siwaju tabi ko sun un sẹyin rara.

Ayipada to ba fẹ de ba eto idibo gbọdọ wa lati ọdọ awọn ile igbimọ asofin ni pelu ifọwọsi gbogbo awọn asoju ni eyi ti aarẹ Trump ko lasẹ le lori.

Kíni Donald Trump sọ gangan?

Ninu oju opo ikansira ẹni twitter ni Aare Donald Trump ti sọ pe lilo ọna ifi idibo ẹni ransẹ lapapọ le sakoba fun nini iye nọmba idibo to jẹ tototọ nitori o le mu kudiẹkudiẹ dani.

O ni awọn aisedeede to le mu dani losu kọkanla yii le pada fa idojuti fun America ko si ba itan idibo to dara jẹ́ ni America

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

O ni awọn ẹgbẹ oselu Democratic le lo awọn irinsẹ idibo ti ko tọna nipasẹ eto idibo fifi ran sẹ nitori pe eto idibo yii ti kuna ni awọn agbegbe ti wọn ti loo sẹyin.

Trump de sibi gbagede ipolongo idibo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Saaju isẹlẹ yii ni Aarẹ Donald Trump ti sọrọ̀ pe...

Donald Trump ti gbà pé Coronavirus yóò burú jáì kí ǹkan tó dára fún Amẹ́ríkà

Coronavirus yóò burú jáì kí nkan tó dára fún Amẹ́ríkà- Donald Trump

Aarẹ ilẹ Amerika Donald Trump ti fi ikilọ sita pe ajakalẹ aarun Coronavirus ni ilẹ Amẹrika yoo buru ju bo se wa yii lọ ki nkan to dára.

Trump sọrọ yii lasiko to pada si eto ijabọ lori Coronavirus to maa n ṣe, o si paṣẹ pe ki gbogbo eniyan ilẹ Amẹrika maa lo ibomu

O ni Ibomu ni iṣẹ to n ṣe, bakan naa ni eyi tun tumọ si pe wọn wa ni isọkan.

Aarẹ o lo ibomu lasiko ijabọ rẹ yii, nitori o woye pe ko pọndandan.

Awọn alabaṣiṣẹ pọ aarẹ ti sọ fun un pe ko fi oju miran wo ọrọ Coronavirus nitori awon to ni aarun naa n peleke sii ni nilẹ Amẹrika.

Lati inu oṣu kẹrin ni aarẹ dawọ le ijabọ ojoojumọ, lasiko naa lo ni oun yoo maa fun awon eniyan ni bẹrẹ ti o le wo aarun Coronavirus

Aarě Trump to maa n pe aarun Coronavirus ni aarun China yọ ibomu kuro lapo ṣugbọn ko fi bo imu.

Ni bayii aarẹ Trump ni awọn idojukọ bi o se n gbiyanju lati tubọ di aarẹ ilẹ Amẹrika ni ẹlẹẹkeji ni inu oṣu kọkanla ọdun yii, yoo ma koju Joe Biden ti ẹgbẹ Democrat.

O din diẹ ni miliọnu mẹrin eniyan lo ti ni aarun Covid-19 ti eniyan to le ni ogoje si ti ku ni ilẹ Amẹrika, eyi lo ga julọ lagbaye.

Àkọlé fídíò, Funmi Adewara: Tele Medicine' ní a fi ń ṣàyẹ̀wò èèyàn ìdá ọgọtá láti dènà ìtànkálẹ̀ Covid

Donald Trump: Wo àwọn tí ìpinu ààrẹ Amẹrika lórí físà yóò kan jùlọ

Ààrẹ ilẹ̀ Amẹrika Donald Trump, tún ti fi kún àṣẹ láti dá fífún àwọn ènìyàn ni ìwé ìgbélùú àti ìwé ìrìnà dúró títí di òpin ọdún 2020.

Trump ti gbe awọn ofin to nira lélẹ̀, èyí sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ ìpòlongo ìdìbò rẹ

Oríṣun àwòrán, @BrianKarem

Awọn onímọ̀ ẹ̀rọ, àwọn ti kò ní ohun ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ ọ̀gbìn àti àwọn ti wọ́n máa ń ràn ẹbi lọ́wọ́ fun ìtọ́jú ọmọ tàbi ìtọ́jú ilé, tó fí mọ́ àwọn ọ̀gá ilé iṣẹ́ ńlańlá ni ọ̀rọ̀ náà yóò kan.

Ilé ìjọba Amẹrika sàlàyé pé, èyi yóò fún àwọn ojúlówó ọmọ ilẹ̀ Amẹrika tí ó n kójú ìṣòrò nítori ìtànkálẹ̀ àrùn Coronavirus ní ààfàní láti rí iṣé ṣe.

Súgbọ̀n àwọn onímọ̀ ti bẹ̀nu àtẹ́ lú nǹkan ti Trump sọ yìí, wọ́n ní ó kàn n lọ́ ọ̀rọ̀ àrùn Coronavirus lọ́rùn láti gbé èrò rẹ̀ jáde lórí òfín láti dènà àwọn arìnrìn àjò tó ń wá sí ilẹ̀ Amẹrika ní.

Àkọlé fídíò, Kid boxer: Ọmọọba 'The Buzz' Larbie rèé, ọmọ ọdún méje tó ń fi ẹ̀ṣẹ́ dá bírà

Àwọn wo ni yóò pa lára?

Lásìkò táwọn aláṣẹ pe ìpàdé àwọn oníròyìn, ìjọba Trump sọ pé, òfin náà yóò múlẹ̀ títí di òpin ọdún 2020, èyí yóò sì kan àwọn ènìyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà márùnẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lé márùn dínlọ́gbọ̀n tí ó fẹ́ gba ìwé ìgbélùú.

Èyí tún kún àwọn ènìyàn tó lé ni ègbẹ̀rún lọ́nà ààdọ́jọ́ tí kò ní ni ààfàní láti gba ìwé ìgbelùú tẹ́lẹ̀ ti wọ́n sì ti forúkọ silẹ̀ - ìwé yìí (Green Card) ló máa n fún àwọn alèjo nílẹ̀ Amẹrika ni àànfàní láti maa gbé ilẹ̀ Amẹrika láì sí wàhàlá.

Sáájú ni ìjọba ti kéde pé òun kò ni fún àwọn ènìyàn ni físà láti inú oṣù kẹrin ọdún.

Ikédé ìjọba tó wáyé lọ́jọ́ ajé yìí kò kan àwọn tó ti ni físà ilẹ̀ Amẹrika lọ́wọ́ tẹ́lẹ̀.

Àṣẹ yìí kan àwọn tó n gba físà H-1B, èyí ni wọ́n sábà máá n fún àwọn òṣìṣẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ láti ilẹ̀ India.

Àwọn alátakò ní, àwọn físà yìí wà fún àwọn ilé ìṣẹ́ Silicon Valley láti gbé iṣẹ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ amẹrika fáwọ́n míràn láti ilẹ òkèrè kí wọ́n ó le san owó péréte fún wọn pẹ̀lú.

Ní ọdún tó kọjá, ó lé ni ẹgbẹ̀run lọ́na ìgba tó fẹ́ gba físà H-1B ti ó wà fún ènìyàn ẹgbẹ̀run lọ́na ọgọ́rin lé díẹ̀ péré.

Àkọlé fídíò, Funmi Adewara: Tele Medicine' ní a fi ń ṣàyẹ̀wò èèyàn ìdá ọgọtá láti dènà ìtànkálẹ̀ Covid

Bákan náà ni àṣẹ yìí yóò kan àwọn oní físàH-2B, eyí ni àwọn òṣìṣẹ ìgbà dé ìgbà tó fi mọ́ àwọn tó ń ṣiṣẹ nílé ìtura àti ibi ìgbáfẹ́, yàtọ̀ sí àwọn tó ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀, àti àwọn tó wà ni ẹ̀ka ètò ìlera.

Àṣẹ náà yóò dàmú àwọn oní físà J-1 èyí túmọ̀ sí ètò pàsípàrọ̀ ti wọ́n máa n ṣe fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásitì pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ orílẹ̀-èdè AU.

Ní ti físà L tó wà fún àwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ ńlá ńlá náà yóò fara káásá, nítori òfin de àwọn náà.

Àkọlé fídíò, Olofa ina: ẹ parí òwe yìí pé ìgbà tí ara bá tu ìgbẹ́ láà ri eṣú....

Ìhà wo ni àwọn ènìyàn kọ síi?

Ìpinu yìí jẹ́ eyí tó "dára jùlọ tó sì mọ́gbọ́n dáni" "eyí tó níye lórí gidi fún ètò ọ̀rọ̀ ajé wa " èyí ni ọ̀rọ̀ ọ̀gá àgba alásẹ ìjọba ti a pè.

Mark Krikorian, tó jẹ́ ọ̀gá àgbà àti adarí àjọ tó n rí sí ìmọ̀ nípa ìwọlé àti ìjáde àlejò nílẹ̀ Amẹrika sọ fún ilé iṣẹ́ ìròyìn AP pé " Èyí jẹ́ ìgbésẹ̀ tó lààmì-laaka nínú àwọn ìpinu ìjọba ààrẹ Trump, nípa fífún àwọn ọmọ ilẹ̀ Amẹrika ní iṣẹ́ òòjọ́."

Sùgbọ́n, àwọn àjọ Civil Liberties Union tí ilẹ̀ Amẹrika sọ pé: " Ìjọba kàn n lo ààrùn Coronavirus lati ṣe àtúnto àwọn òfin bí àwọn arìnrìnàjò ṣe ń wọ ilẹ̀ Amẹrika ni."

Ìlànà tuntun ìjọba yìí kó bá àwọn oníṣòwò míràn wí, tó jẹ́ pé nínú àwọn òṣìṣẹ́ láti ilẹ̀ òkèrè ni iṣẹ́ òòjọ́ wọ́n fi n tẹ̀ síwájú.

" Bí ètò ọ̀rọ̀ ajé ìlú ṣe ń padà bọ̀ sípò, ètò ọ̀rọ̀ ajé ilẹ̀ Amẹrika ńilò ọ̀rọ̀ ìwúnilórí láti ṣe alábapade nǹkan ti àwọn òṣìṣẹ́ wọ́n ń fẹ́, èyí ni ọ̀rọ̀ ẹgbẹ́ àwọn oníṣòwò nínú àtẹ̀jáde kan lósù yìí, ti wọ́n sì ń kìlọ pé kí ìjọba máá gbé awọn òfin tuntun jáde mọ́ lórí àwọn arìnrin àjò.

" Nítorí ìdí èyí, ó ṣe pàtàkì láti ni àwọn onímọ labẹ́ ilé àti jákèjádò gbogbo àgbáyé.