Belarus: Ààrẹ orílẹ̀èdè Lukashenko tún wọlé lẹ́yìn ọdún 25 lórí oyè! Kí ló ń ṣẹlẹ̀ gangan?

BELARUS

Oríṣun àwòrán, EPA

Ọjọ aiku ni aarẹ Alexander Lukashenko jawe olubori fun saa ikẹfa lori ye lẹyin idibo tawọn eeyan n kun yunmu yunmu le lori eyi to si ru ibinu awọn afẹhonuhan soke ti wọn tu si gbogbo igboro jakejado orilẹede naa.Ṣugbọn ki lẹ tun mọ nipa Belarus?Ohun marun niyi ti ẹ le nifẹ lati mọ nipa rẹ.

Belarus ni orilẹede to gbona ju paapaa lasiko ogun agbaye keji.Iṣẹlẹ ogun naa lo da Belarus ru laarin ọdun 1941-1944 to bẹẹ ti wọn padanu ida mẹẹdọgbọn eeyan wọn lasiko ogun agbaye naa ti ilẹ Nazi Germany kogun ja USSR.Ẹẹdẹgbẹjọ miliọnu araalu ati Sọja ẹgbẹta miliọnu lo ku ni Belarus lasiko ogun naa to fi mọ o fẹrẹẹ to iye gbogbo awọn ẹya Juu.Nkan bii ida marundinlaadọrun olu ilu orilẹede naa, Minsk lo bajẹ ninu iṣẹlẹ ibugbamu ado oloro ti wọn si tun un kọ ni 1950s ati 60s.Aarẹ ibẹ ni aarẹ ilẹ Yuroopu to pẹ ju lori oye. Ṣe ni iroyin sọ pe aarẹ Alexander Lukashenko lo tun jawe olubori ninu idibo ọjọ Aiku pẹlu ibo to le ni ida ọgọrin.

Ẹwẹ, awọn oluwoye idibo ko si nikalẹ, eyi to si fa ibẹru ṣiṣe mago-mago idibo. Ohun si ni iditi oludije alatako gangan, Svetlana Tikhanovskaya ṣe yari pe irọ ni esi idibo naa.Wọn ṣapejuwe aarẹ Lukashenko gẹgẹ bi aarẹ apaṣẹwaa to ṣẹ tun wa nilẹ Yuroopu bayii. O bẹrẹ iṣejọba lọdun 1994.Ọgbẹni Lukashenko ti sọ ọ jade lẹnu ri pe ẹnikẹni to ba dara pọ mọ ifẹhonuhan alatako gẹgẹ bii adunkoko mọni, "a o yin in lọrun bii ti pẹpẹyẹ ni".Ọtọ tun ni ajoji kan, Lee Harvey Oswald to pa aarẹ Kennedy tan to wa ko wa si Minsk lati maa gbe nibẹ gẹgẹ bi ẹni tọwọ rẹ mọ.Nitori ọrọ ẹ ba mi sọ fisa igbelu mi dọtun - a o fun ọ, Oswald yii tun daran o ge ọrun ọwọ ọga ileeṣẹ to bẹẹ ṣugbọn ko ma baa si ija ilu si ilu, wọn dari ji i.O fẹ aya, o bimọ nibẹ koda o riṣẹ gidi kaakiri.Bakan naa nigba ti ina nla kan sọ ni ileeṣẹ ipese ina orilẹede ẹgbẹ wọn, Ukraine ati Chernobyl, Belarus fara gba gidi gan.Tori eyi, eeyan miliọnu meji ninu eyi ti ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta ara orilẹede Belarus pọ ju lo n gbe ni awọn agbegbe to lewu.Ẹwẹ, awọn naa ni ohun amuyangan lagbaye, Azarenka agbabọọlu ẹlẹyin tẹniisi to ṣoriire ju lorilẹede naa. Oun lọmọ Belarus to kọkọ gbe ogo wale to si kọkọ gba ipo akọkọ lagbaye gẹgẹ bi agbabọọlu tẹniisi.

BELARUS

Oríṣun àwòrán, EPA

Belarus

Oríṣun àwòrán, EPA

Ifẹ̀họ̀núhàn ń lọ lọ́wọ́ ní Belarus lẹ́yìn tí ìdìbò tùn gbé Ààrẹ̀ Lukashenko tó ti wà nípò fún ọdún 26 wọlé

Ifẹhọnuhan ti wọ ọjọ keji bayii lorilẹede Belarus lẹyin ti iroyin fihan pe Aarẹ Lukashenko to ti wa ni ipo fun ọdun mẹrindinlọgbọn tun ti wọle idibo aarẹ.

Awọn ọlọpaa ni olu ilu Belarus, iyẹn Minsk ti fẹ afẹfẹ gaasi tajutaju fun awọn to n fẹhọnu han pe idibo aarẹ naa ni magomago ninu.

Awọn oṣiṣẹ ijọba ni afẹhọnuhan kan ti ku nigba ti ado oloro to mu dani bugbamu mọ ọ lọwọ, to si gba ibẹ lọ.

BELARUS

Oríṣun àwòrán, EPA

Aarẹ Alexander Lukashenko ni esi idibo gbe jade pe, o ti bori ida ọgọrin ninu ọgọrun ida ibo ti awọn oludibo di.

Ọkan gboogi ninu awọn to dije dupo aarẹ naa, Svetlana Tikhanovskaya kọ lati gba esi idibo naa wọle, to si sọ wi pe oun lo bori idibo naa.

Aisi eto aabo ati awọn onwoye idibo lasiko idibo naa ti fi agbara fun ẹsun magomago lasiko idibo ti wọn fi kan ijọba.

Orilẹ-ede Amerika ati Ajọ Iṣọkan ilẹ Yuroopu, EU ti kọ ẹsi idibo naa.

Aarẹ Lukashenko bori pẹlu ida 80.23%, nigba ti oludije Svetlana Tikhanovskaya gba ida ibo 9.9% ninu idibo sipo aarẹ naa.

Arabinrin Svetlana Tikhanovskaya lo dije dipo ọkọ rẹ to wa ni atimọle, ti o si dari ifẹhọnuhan ọlọgọọrọ.

Nibayii, Tikhanovskaya ti sa kuro lorilẹede Belarus lọ si Lithuania, ti minisita fun ọrọ ilẹ okeere ni Lithuania si sọ wi pe alaafia ni arabinrin naa wa.

Belarus

Oríṣun àwòrán, Reuters

Amọ, Aarẹ Lukashenko to ti wa ni ipo lati ọdun 1992 sọ wi pe awọn ijọba lati oke okun lo n ṣe agbatẹru fun awọn alatako oun ati awọn afẹhọnuhan.

Asiko ti ipolongo ibo bẹrẹ ni Arabinrin Tikhanovskaya, ẹni ọdun mẹtadinlogoji, to ti fi igba kan jẹ olukọ, di oloṣelu.

Eyi waye lẹyin to pinnu lati rọ́pò ọkọ rẹ ti wọn mu si atimọle, ti wọn ko si jẹ ko fi orukọ silẹ lati díje.

Sugbọn, ọwọ yẹpẹrẹ ni Aarẹ Lukashenko fi mu ọrọ rẹ, to si fi ṣe awada pé àwọn kan lo n dari rẹ lati ilẹ okeere.

Àkọlé fídíò, Alaafin: Olori Aanu Adeyemi ṣàlàyé ìdí tó ṣe gẹ́ Oba Lamidi Adeyemi ti ìlú Oyo

Gẹgẹ bi ajọ Viasna ṣe sọ, eeyan to le ni ẹgbẹrun meji, ni wọn ti fi si ahamọ, lati igba ti ipolongo ibo ti bẹrẹ.

Koda, ni alẹ ọjọ ti idibo ku ọ̀la, Arabinrin Tikhanovskaya, sọ pe awọn ọlọpaa mu olori ikọ ipolongo òun.

Arabinrin Svetlana Tikhanovskaya ni alatako gboogi to koju Aarẹ Lukashenko

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Arabinrin Svetlana Tikhanovskaya ni alatako gboogi to koju Aarẹ Lukashenko

Ileesẹ ayelujara NetBlocks tí ẹ sọ pe ayelujara ko ja geere lọjọ Aiku, bí awọn eeyan ṣe n dibo.

Awọn alatako sì sọ pe eyi mu ki o ṣòro lati ko ẹri jọ pé mago-mago ibo waye.

Belaruz
Àkọlé àwòrán, Ọpọlọpọ eeyan ni awọn ọlọpaa mu lasiko iwọde to waye lọjọ Aiku

Bakan naa, ikunsinu ti n waye nitori bi wọn ko ṣe pe awọn oluwoye lati tọ pinpin idibo naa, ìdá bi ogoji ibo si ni wọn ti di saaju ọjọ idibo.

Kii ṣe Tikhanovskaya nikan lo díje tako Aarẹ Lukashenko. Awọn mẹta yooku ni ọmọ ile aṣofin nigba kan, Anna Kanopatskaya, Sergie Cherechen, ati Andrei Dmitriyev.

Lara awọn nkan to fa tí tako ijọba Ọgbẹni Lukashenko, ni bo ṣe fi ọwọ yẹpẹrẹ mu itankalẹ aarun coronavirus.

Ọgbẹni Lukashenko lasiko to lọ dibo nilu Minsk

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Ọgbẹni Lukashenko lasiko to lọ dibo nilu Minsk

Nise ni Aarẹ gba awọn ara ilu ni imọran pe ki wọn o ma a mu ọtí lile vodka, ati ìwẹ̀ saunas, fi gbogun ti aarun naa.

Eeyan bi ẹgbẹrun lọna aadọrin lo ti ni coronavirus ni Belarus, ninu miliọnu mẹsan aabọ to n gbe nibẹ. Ẹgbẹta si ti ku.