Seyi Makinde: Wo ìdí tí gómìnà Oyo fi pàṣẹ ìdádúró iṣẹ́ fún kọmíṣọ́nà rẹ̀

Seyi Makinde: Wo ìdí tí gómìnà Oyo fi pàṣẹ ìdádúró iṣẹ́ fún kọmíṣọ́nà rẹ̀
Àkọlé àwòrán, Seyi Makinde: Wo ìdí tí gómìnà Oyo fi pàṣẹ ìdádúró iṣẹ́ fún kọmíṣọ́nà rẹ̀

Gomina ipinlẹ Oyo, amojuẹrọ Seyi Makinde ti paṣẹ idaduro lẹnu iṣẹ fun Kọmiṣọna iṣẹ ode, eto amayedẹrun ati irina, Ọjọgbọn Raphael Afonja.

Ninu lẹta ti o jade lati ọfiisi gomina Seyi Makinde eleyii ti akọwe rẹ, Arabinrin Olubamiwo Adeosun fọwọ si lọjọ kẹwaa oṣu kẹjọ ọdun 2020, gomina ni loju ẹsẹ ni idaduro naa bẹrẹ.

Ọrọ ti akọwe agba gomina, Ọgbẹni Taiwo Adisa sọ fihan pẹlu akọlee "Idaduro lẹnu iṣẹ" pe oun n ṣe ifitonileti aṣẹ to wa latọdọ gomina, Seyi Makinde pe iṣẹ rẹ gẹgẹ bi kọmiṣana ti wa sopin ki eyi si waye kiakia.

"Pẹlu igbesẹ tuntun to wa loke yii, ọrọ jade, aṣẹ tẹle e pe ki o ko gbogbo ohun ini ijọba to ba wa ni ikawọ rẹ silẹ fun akọwe ijọba".

Akọwe agba wa fi kun un lorukọ gomina pe awọn dupẹ fun gbogbo ipa to ko lasiko rẹ lẹnu iṣẹ awọn si gboriyin fun un, wọn ṣadura oriire fun un ninu ohun gbogbo to ba dawọle lọjọ iwaju.

Ẹwẹ, lọna miran, gomina tun ti fọwọ si ṣiṣe pasiparọ awọn kọmiṣọna meji mii ni ipinlẹ Oyo pe ki wọn parọ iṣẹ ara wọn.

Ninu iwe abẹnu ọfiisi ijọba eyi ti akọwe agba gomina fọwọ si fihan pe ki kọmiṣọna fun ọrọ akanṣe iṣẹ, Oloye Bayo Lawal, kuro nibẹ lọ si ileeṣẹ to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ gẹgẹ bii kọmiṣọna nibẹ nigba ti ẹni to wa nibẹ naa lọ si ileeṣẹ to n ri si akanṣe iṣẹ.Atẹjade naa tun fi lede pe ki pasiparọ yii ati bibẹrẹ iṣẹ waye ni kiakia.