Risikat Azeez: Ìyàwó Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, Risikat tí bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́sẹ́ aṣojú lóge

Oríṣun àwòrán, Facebook/ajikecentre
Arabinrin iya awọn ọmọ oloju buluu Risikat Azeez ti bẹrẹ si ni kọṣẹ iṣaraloge latari iranwọ iyawo Gomina ipinlẹ Kwara.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba, Risikat fidi ọrọ yi mulẹ pe lootọ ni pe oun ti bẹrẹ si ni kọ iṣẹ aṣojuloge yi.
O ni iyawo Gomina Kwara to ti kọ́kọ́ ṣe adehun iranlọwọ fun oun ti mu ileri naa ṣe bayii.
Ati pe laipẹ oun naa a di ẹni to niṣẹ lọ́wọ́ gẹgẹ bii obinrin rere.
''Lọjọbọ ọṣẹ to kọja ni a bẹrẹ ikọṣẹ yi ti a o si pari lọṣẹ to n bọ.Ọsẹ kan laa fi kọṣe yi.''
Loju opo ajọ aladani iyawo Gomina Ajike Support Centre ni Facebook,wọn fi aworan ibi ti Risikat ti n gba idanilẹkọ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/ajikecentre
Nigba ti BBC beere lọwọ Risqot nipa yiyanju gbọnmi si omi ooto to wa laarin oun ati ọkọ rẹ o ni ''wọn yanju fun wa''
Ọpọ eeyan lo ti ṣe ileri iranwọ yala nipa owo tabi riran awọn ọmọ rẹ lọ si ileẹkọ fun Risikat.
Ninu eyi ti a o ri apẹrẹ pe o di ootọ ni iranwọ iṣẹ kikọ ti iyawo Gomina arabinrin Olufolake Abdulrazaq ṣe fun yi jẹ.

Oríṣun àwòrán, Others
Risikat Azeez: Ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ ní Ilorin ti fi iṣẹ́ Emir jẹ́ fun Risikat àti ọkọ rẹ̀
Yoruba ni agba kii wa lọja, ki ori ọmọ tuntun wọ, bẹẹ si ni aye ko gbọdọ toju awọn agba bajẹ.
Eyi lo mu ki Emir tilu Ilorin, Alhaji Ibrahim Zulu Gambari, fi da si ọrọ aawọ to wa laarin tọkọtaya Abdulwasiu ati Risikat Azeez, ti iyawo ni oju buluu , to n ja ranin-ranin nilẹ lẹnu ọjọ mẹta yii.
Emir ni iroyin kan lo gbe igbesẹ naa lati ipasẹ ẹgbẹ awọn ọdọ nilu Ilori, to da si aawọ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ọmọ Nàíjíríà tí wọn fi pósí ‘₦34m’ sin
- Yéèpà, òfin ìtakété síra ẹni forí ṣánpọ́n lásìkò ọdún Osun Osogbo
- Ẹ fura, iyọ̀ onímájèlé tó dóde ti gbẹ̀mí èèyàn méje!
- Ta bá yá owó lókèèrè kò láìfí, ìpèsè ohun amáyédẹrùn là ń ṣe – Lai Mohammed
- Ìtàn ayé Alájọ Ṣómólú rèé, tó ta mọ́tò ra kẹ̀kẹ́?
- Ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ Donald Trump, àbúrò rẹ̀ Robert, dèrò ọrun
- Ibùdó ìyàsọ́tọ̀ ni mo wà, ló fi pẹ́ kí ń tó sọ̀rọ̀ lórí tírélà tó já l‘Eko - Omotola Jalade Ekeinde
Alaga ẹgbẹ Ilorin Emirate Youth Development Association naa, Alhaji Abdullahi Salahudeen Babatundesi lo n gbiyanju lati da si aawọ laarin lọkọlaya naa.
Tọkọtaya naa si ni wọn mọriri Emir fun bo se da si aawọ naa sugbọn aridaju ko tii wa pe Risikatu ti pada sile ọkọ rẹ.
Bẹẹ ba n fọkan tẹle wa bọ lati bii ọsẹ meji sẹyin, la ti n mu iroyin wa fun yin nipa ipo ti Risikat ati ọmọ rẹ obinrin mejeeji wa lẹyin ti to kuro nile ọkọ rẹ nitoriidẹyẹsi pe o n i oju buluu.Yoruba ni agba kii wa lọja, ki ori ọmọ tuntun wọ, bẹẹ si ni aye ko gbọdọ toju awọn agba bajẹ.

Oríṣun àwòrán, others
Àwọ̀ ojú pọ̀ bíi àwọ̀ òṣùmàrè, àmọ́ ojú búlúù Risikat kò nílò àtúnṣe- Dókítà Feyi Adepoju
Lori ọrọ oju buluu Risikat Moromoke Azeez atawọn ọmọ rẹ meji naa la si wa.
Akọṣẹmọṣẹ nipa itọju oju, Ọjọgbọn Feyi Adepoju tun ti tan imọlẹ si ohun to le mu ki eeyan ni irufẹ oju buluu.
Ọjọgbọn Adepoju ṣalaye pe oriṣiiriiṣii awọ ni oju le ni, irufẹ awọ oju dabi awọ oṣumare ni.
Dokita Adepoju ṣalaye pe awọn awọ oju to wọpọ ni Naijiria ati ilẹ Afirika ni awọn buluu, awọn ewe(green) ati awọn ''brown.''
- À kò gba owó kankan lọ́wọ́ àwọn ẹgbẹ́ agbésùmọ̀mí ISWAP- MURIC
- ‘Àwọn òlóṣèlú kò ní ìwà ọmọlúwàbí ló jẹ́ kí wọ́n má a lọ láti ẹgbẹ́ òṣèlú kan lọ sí òmìràn’
- Àmọ̀tẹ́kùn gbéra! Kò séwu nínú ìdìbò tó ń bọ̀ l'Ondo àfi gìrì àparò- Akeredolu
- Àwọn ǹkan tí ó yẹ kí o mọ̀ nípa 'Sharia Law' ní Nàìjíríà
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kebbi tẹ bàbá àti ìyàwó rẹ̀ méjì fún pé wọn so ọmọ pọ̀ mọ́ ewúrẹ́ fún ọdún méjì
Ojọgbọn Feyi ṣalaye siwaju sii pe awọ ''brown'' lo wọpọ ju lorilẹ-ede Naijiria nigba ti ọpọ eeyan ni awọ buluu loju wọn nilẹ Yuroopu.
Ninu alaye rẹ, dokita Adepoju ni oju buluu Risikat atawọn ọmọ rẹ ko nilo itọju rara nitori abimọ lo jẹ fun wọn.
O fikun ọrọ rẹ pe irufẹ oju buluu bayii ko ni ki wọn maa riran daadaa.
Amọ, Ọjọgbọn Adepoju sọ pe awọn mii ti wọn ba loju buluu lai ṣe wi pe wọn bi mọ wọn ni gbọdọ lọ si ile iwosan fun itọju.
Ọjọgbọn Feyi mẹnuba oriṣii awọ oju ti eeyan le ni boya rẹsurẹsu ni tabi dudu, tabi awọ ayinrin tabi olomi aro.
O ni o dẹ ṣeeṣe fun ẹnikẹni lati yi awọ oju rẹ pada nipa wiwọ awọn nkan to le yi awọ oju pada boya fun oge tabi fun iṣẹ bii ti awọn oṣere ni gbedeke asiko kan.
Ṣugbọn to ba jẹ aisan lo fa yiyi awọ oju pada, o san ki ẹni bẹ́ẹ̀ tete lọ fun itọju bi o ṣe yẹ lasiko.
Ati pe fun awọn to ba jẹ awọ oju Abimọ ni bii ti Risika ati awọn ọmọ rẹ, ko nilo atunṣe rara.
Ṣaaju ni oriṣiiriṣii ti ṣẹlẹ nipa oju buluu Risikat ati awọn ọmọ rẹ̀:
Wo ìdí tí Risikat Moromoke Azeez n'Ilorin fi ní ''Blue Eyes- Dókítà:
Awọ oju arabinrin Risikat Alabi atawọn ọmọbinrin rẹ meji ti wọn n gbe niluu Ilorin, orilẹ-ede Naijiria ti n ya ọpọlọpọ lẹnu.
Ọrọ oju alawọ omi aro buluu ti Risikat ni ti di ọrọ to kan gbogbo eeyan bayii lẹyin ti iroyin fọn sigboro pe ọkọ rẹ kọ ọ tọmọ tọmọ tori awọ oju wọn.

Oríṣun àwòrán, Event Plus
BBC Yoruba ṣe akọjọpọ awọn fọto oriṣiriṣi nipa awọ oju wọn fun un yin:
Ohun ti dokita ti BBC ba sọrọ sọ niyii:
"O ṣee ṣe ki Risikat Azeez atawọn ọmọ rẹ mejeji ni ohun to jọ mọ irufẹẹ "Àfín" kan ti oyinbo n pe ni "Ocular Albinism" eyi to jẹ nkan teeyan n ni lati iran de iran to si jẹ ohun to maa n mu adinku ba awọ lẹyin oju eeyan".
Lara ohun ti eeyan le ma mọ nipa eyi ni wi pe o lee ṣakoba fun iriran ẹni bẹẹ ti oju naa yoo si maa ṣe bakan-bakan si ina to ba mọlẹ yan an".
Ẹwẹ, ọkọ Risikat, Wasiu Dada ti jade lati sọ pe irọ ni o, kii ṣe torii oju buluu loun ṣe pa iyawo oun ti.
O ni torii oju buluu ọhun gan an ni oun ṣe fẹ ẹ oun ko si kabamọ pe awọn ọmọ awọn naa ni oju buluu.
"Oju buluu ti Risikat ni ṣeeṣe ko jẹ ṣegeṣege to maa n waye ninu ẹyinju, gẹgẹ bi Dokita Yetunde Oladipo ṣe sọ fun wa.
- Orílẹ̀-èdè Chad pé ọgọ́ta ọdún, àwọn ara ìlú ń pariwo lábẹ́ Aàrẹ Deby tó gba 'Field Marshal'
- Ọwọ́ ikọ̀ aláàbò STF tẹ afurasí mẹ́jọ tó lọ́wọ́ nínú ìpànìyàn lemọ́-lemọ́ọ Gúúsù Kaduna
- Diezani gan an ní Hushmummy tó ń bú àwọn Yahoo boys- Àwọn Ọmọ Naijiria lórí Twitter
- Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún ọ̀rọ̀ ibojì òkú, àti àwọn ipò òṣèlú mìíràn tó jẹ́ kàyééfì ní Nàìjíríà
- Asojú ìjọba orílẹ̀-èdè Lebanon ti kọ̀wé fipò silẹ̀ nítorí ìbágbàmù tó gbẹ̀mi ènìyàn 200
Kini o ti ṣẹlẹ sẹyin?
Ọkọ Risikat ní ojú búlúù tí ìyàwó òun ní gan an lòun ṣe fẹ́ ẹ
Ọkọ Risikat Moromoke Azeez, iya awọn ọmọ oloju buluu, Wasiu Dada ti sọ pe ija lode ni orin di owe, o ni oun ko le iyawo oun nitori o bi awọn ọmọ oloju buluu.
Dada ṣalaye fawọn akọroyin pe awọn iwa kan ti Risikat n hu ti ko tẹ oun lọrun lo fa ija laarin awọn mejeeji ti ipinya fi de bawọn.
O ni niṣe loun maa n gbe ounjẹ lọ fawọn ọmọ oun nile awọn obi iya oun ti wọn wa pẹlu rẹ.
- Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún ọ̀rọ̀ ibojì òkú, àti àwọn ipò òṣèlú mìíràn tó jẹ́ kàyééfì ní Nàìjíríà
- Diezani gan an ní Hushmummy tó ń bú àwọn Yahoo boys- Àwọn Ọmọ Naijiria lórí Twitter
- Nítorí pé mo gba ẹ̀há kò ní kí ń ṣọlẹ̀ tàbí ṣagbe- Ẹ̀lẹ́hàá Amina
- Èdè Yorùbá dùn lẹ́nu àwọn ọmọ òyìnbó yìí ní Michigan!
- Mo ti buwọ́lu àdínkù owó orí nítorí ìrọ̀rùn àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ogun lásìkò Covid 19- Dapo Abiodun
Wasiu Dada tun sọ pe irọ nla ni pe awọn obi oun sọ pe ki oun pinya pẹlu Risikat nitori pe awọn ọmọ ti o n bi ni oju buluu.
Amọ, Risikat yari, o ni nitori oju buluu ti awọn ọmọ ti oun bi fun un ni ipinya fi wa laarin awọn.
Ṣugbọn iya Risikat naa sọ pe niṣe ni ọkọ pa a ti pẹlu awọn ọmọ ti ko si bikita nipa wọn mọ.
Mama Risikat ni lọpọ igba ni oun pe ọkọ rẹ lati pẹtu si aawọ to wa laarin wọn, ṣugbọn oun rii wi pe ọkọ Risikat ko ni nnkan ṣe.
Mama Risikat ni lootọ ko wu oun pe ki Risikat ni ọkọ miiran nigba ti ọkọ akọkọ rẹ si wa laaye, ṣugbọn ibanujẹ lo maa n jẹ f'oun pe Wasiu ko tọju Risikat.
Risikat gan an fun ra rẹ ko le sọ pato bo ya oun ati ọkọ rẹ le pada jọ maa gbe pọ.
Ohun to sọ ni pe oun fẹ kawọn ọmọ oun ló sile iwe, ki wọn si di eeyan nla lawujọ.
- Ọwọ́ ikọ̀ aláàbò STF tẹ afurasí mẹ́jọ tó lọ́wọ́ nínú ìpànìyàn lemọ́-lemọ́ọ Gúúsù Kaduna
- Diezani gan an ní Hushmummy tó ń bú àwọn Yahoo boys- Àwọn Ọmọ Naijiria lórí Twitter
- Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún ọ̀rọ̀ ibojì òkú, àti àwọn ipò òṣèlú mìíràn tó jẹ́ kàyééfì ní Nàìjíríà
- Asojú ìjọba orílẹ̀-èdè Lebanon ti kọ̀wé fipò silẹ̀ nítorí ìbágbàmù tó gbẹ̀mi ènìyàn 200
- Dẹ́rẹ́bà kẹ̀kẹ́ Maruwa rí ẹ̀wọ̀n gbére he lẹ̀yìn tó fi ipá bá ọmọ ọdún mẹ́rìnlá lòpọ̀
Awọn oluranlọwọ ti dide fun iya ọmọ oloju buulu:
Ìyàwó Bukola Saraki fún tìyá-tọmọ olójú búlúù ní N250, 000!
Aya gomina ipinlẹ Kwara, Olufolake Abdulrazaq, ti kede pe oun ti setan lati ran iya ati ọmọbinrin meji ti wọn ni oju buluu lọwọ .
Arabinrin Toyin Saraki to jẹ aya Aarẹ ile igbimọ Aṣofin agba ni Abuja tẹlẹ, Bukola Saraki naa ti fun tiya tọmọ oloju buulu ni ẹgbẹrun lọna igba ati aadọta owo naira lati fi tọju ara rẹ ati ọmọ rẹ.
- Àjọ JAMB kéde ìlànà ìgbà ni wọlé tuntun fún àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga
- Ifẹ̀họ̀núhàn ń lọ lọ́wọ́ ní Belarus lẹ́yìn tí ìdìbò tùn gbé Ààrẹ̀ Lukashenko tó ti wà nípò fún ọdún 26 wọlé
- Ẹgbẹ́ òṣèlú ZLP gbàmí tọwọ́tẹsẹ̀ láti díbò gómínà ní Ondo- Agboola Ajayi
- Orílẹ̀-èdè Chad pé ọgọ́ta ọdún, àwọn ara ìlú ń pariwo lábẹ́ Aàrẹ Deby tó gba 'Field Marshal'
Mínísíta fún ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ àti eré ìdáraya ní Naijiria Sunday Dare ti kéde pé àwọn ṣetán láti rán àwọn ọmọ olójú búlúù ti bàbá wọ́n lé àwọn àti ìyá wọ́n síta lọ si ilé iwé.
Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún mínísítà, Shola Kolawole lo sọ èyí lásìkò tó sàbẹ̀wò si ìyá àwọn ọmọ náà Risikat tí òun pẹ̀lú ni ojú búlúù.
Bẹẹ ba gbagbe, a ti mu iroyin wa fun yin saaju pe, obinrin to ni oju buluu naa, Risikat Azeez, ni ọkọ rẹ le jade nitori o bi ọmọbìnrin meji ti oju wọn buluu bi i ti iya wọn.

Oríṣun àwòrán, Alabi Rukayat Oyindamola
Bayii, awọn ẹgbẹ alaanu meji miran tun ti ṣetan lati dide iranlọwọ fun iya awọn ọmọ oloju buluu yii.
Iroyin naa si lo gba ori ayelujara kan lati bii ọjọ melo kan, ti Risikat ti kígbe sita nipa iriri rẹ naa loju opo Facebook.
- A ti gùnlé ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ ní ìpílẹ̀ Eko- NUPENG
- A ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ibì tí owó tí àwọn adigunjalẹ̀ gbé ní banki Okeho wọ̀lẹ̀ sí- Ọlọ́pàá
- Diezani gan an ní Hushmummy tó ń bú àwọn Yahoo boys- Àwọn Ọmọ Naijiria lórí Twitter
- Àwọn adarí lágbàyé ṣèpàdé láti ṣèrànwọ́ fún Lebanon lẹ́yìn ìbúgbàmù tó pa ènìyàn 158

Oríṣun àwòrán, Just Event Online
Nigba to n fesi si iṣẹlẹ yii, aya Abdulrazaq kede loju opo Twitter rẹ pe oun yoo ran tiya- tọmọ lọwọ lati gbe igbe aye to dẹrun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Obìnrin akọkọ nipinlẹ Kwara ni oun ti kan si Risikat Azeez atawọn ọmọ rẹ lati ipasẹ ibudo ajọ alaanu to da silẹ, iyen, Ajike People Support Centre.
Ko tan sibẹ, aya gomina ipinlẹ Kwara tun kede pe oun ti n gbe igbesẹ lati ri daju pe aarin obìnrin naa ati ọkọ rẹ gun pada, ki wọn si di idile alayọ.
Arabinrin kan to mọ nipa iṣẹlẹ naa, Alabi Rukayat Oyindamola, lo kọkọ gbe iroyin nipa rẹ si ori ayelujara Facebook.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Eyi lo si mu ki BBC kan si iya awọn ọmọ naa, Arabinrin Risiqot Moromoke.
Arabinrin Moromoke sọ fun BBC Yoruba pe, awọn ẹbi ọkọ oun lo ko ọrọ si ọkọ lori lati gbe igbesẹ to gbe.
"Wọn sọ fun ọkọ mi pe, ṣe bi gbogbo ọmọ ti ma a bi yoo ṣe ma a ri niyi?"
O tẹ̀siwaju lati sọ pe akọbi ọmọ oun, Kaosara jẹ ọmọ ọdun mẹjọ, ti eyi aburo, Hassanat si jẹ ọmọ ọdun mẹrin aabọ.
Arabinrin Moromoke tẹsiwaju pe lati igba ti wahala yii ti bẹrẹ ni ọkọ oun ko ti fi owo silẹ fun ounjẹ tabi itọju ile silẹ mọ.
"Emi naa ni iru àwọ̀ oju yii. Emi nikan ni mo si ni iru rẹ ninu ẹbi wa. Nitori naa, ko jẹ iyalẹnu pe mo n bi awọn ọmọ to ni i.

Oríṣun àwòrán, Alabi Rukayat Oyindamola
Koda, ayẹwo oriṣiriṣi ni wọn ṣe fun ọmọ mi keji nigba ti mo bi silewoosan nitori oju naa, ṣugbọn wọn ko ri aisan kankan lara rẹ."
- Mo ké bòòsí tòò bí mo ṣe bí ìbejì, ti ọ̀kan jẹ́ àfín, ìkejì jẹ́ dúdú-Màmá Ọlátẹ́jú
- Iya Woli: Ẹ̀mí ìjókíjó, Wòó, Ṣọ̀kí, Wojú, Ṣàkùṣákù, One Corner...jáde!
- Ìbúgbàmù ńlá wáyé nílùú Beirut ṣáájú àbọ̀ ìdájọ́ ikú Hariri
- Ariwo ayọ̀ sọ nílé Remi Surutu, ọmọ rẹ̀ mú ọkọ wale
- Ṣé òótọ́ ni pé Tayo Amusan ni yóò gba ìṣàkóso ilé ìtajà Shoprite?
- Ọmọ Downsydrome ti mo bí ló fún mí láǹfàní láti de ilú Oyinbo
O fi kun ọrọ rẹ pe awọn obi oun ranṣẹ pe ẹbi ọkọ oun lati yanju ọrọ, ṣugbọn ẹnikẹni ninu wọn ko yọju.
Ni bayii, Arabinrin sọ pe ile awọn obi oun ni oun pada si lati ma a gbe lati igba ti ọkọ ti le e jade tọmọtọmọ.




















