Justice for Jubril: Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kebbi tẹ bàbá àti ìyàwó rẹ̀ méjì fún pé wọn so ọmọ pọ̀ mọ́ ewúrẹ́ fún ọdún méjì

Jubril ti wọn so mọ ewurẹ.

Oríṣun àwòrán, KBSTGOV

Àkọlé àwòrán, Aye le!

Ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Kebbi, ti mu ọkunrin kan ati iyawo rẹ meji, fun pe wọn so ọmọ orogún wọn, Jubril Aliyu, ọmọ ọdún mẹwaa, pọ mọ ewurẹ fun ọdun meji.

Ọga Agba Ọlọpaa, DSP Nafiu Abubakar, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe awọn ṣi n wadii nkan to mu ki awọn òbí ọmọ naa fi ìyà jẹ ẹ to bẹ ẹ, debi pe wọn ni ko ma a sun pẹlu awọn ewurẹ wọn.

O fi kun un ọrọ rẹ pe ọmọ naa ti n gba itọju nileewosan bayii, ti iwadii si n lọ.

Àkọlé fídíò, Alaafin: Olori Aanu Adeyemi ṣàlàyé ìdí tó ṣe gẹ́ Oba Lamidi Adeyemi ti ìlú Oyo

Ẹnikan lára àwọn to n tọ pinpin iṣẹlẹ naa, Amofin Hamza Attahiru, lati ajọ ajafẹtọ ọmọniyan Human Rights Network, sọ pe ẹnikan lára àwọn to doola ẹmi Jubril jẹri pe bi oun ṣe maa n ri ọmọ naa ti wọn so o pọ mọ àwọn ewurẹ jẹ iyalẹnu.

O ni eyi lo mú ki oun si beere lọwọ àwọn iyawo baba rẹ ohun to fa a, o ni wọn fun oun ni esi pe nitori pe ọmọ naa ko gbọ́n daadaa ni.

O ni: "Ibi ti wọn so o mọ pẹlu awọn ewurẹ, ni a ti ba ọmọ naa ninu igbọnsẹ gbígbẹ to jẹ ti ẹ ati ti ewurẹ.

Koda, o ti n jẹ ìgbẹ́ naa.

Awọn iyawo baba rẹ sọ pe nitori o ni arun ọpọlọ ati warapa, ni wọn ṣe fi sibẹ."

"O jẹ ibanujẹ ọkàn pe ọmọ naa ti n hu iwa bi ewurẹ, nitori pe o ti pẹ ni aarin wọn."

Sugbọn nínú ifọrọwanilẹnu miran, ọkan lara awọn iyawo baba rẹ sọ pe oun maa n fun un ni oúnjẹ.

Àkọlé fídíò, Working religious women: Ẹ̀lẹ́hàá kìí ṣe ọ̀lẹ- Aminat Adegoke

Gomina ipinlẹ Kebbi, Abubakar Bagudu ti pàṣẹ pe ki iwadii ijinlẹ waye lori ọrọ Jubril.

Ijọba sọ ninu atẹjade ti wọn fi sita lori iṣẹlẹ naa pe "o ba ni lọkan jẹ pe lati ọdun meji sẹyin ti ìyá ọmọ naa ti kú, ni igbeaye rẹ ti yi pada.

Fidio bi awọn ajafẹtọ ọmọniyan ati awọn ọlọpaa ṣe doola ọmọ naa wa lori ayelujara.

Bakan naa ni Gomina Abubakar Bagudu kede pe ijọba òun ti gbakoso itọju ọmọ naa, eto ilera ati ẹ̀kọ́ rẹ.

Àkọlé fídíò, BBC Africa Eye: ìwádìí ìkọ̀ks BBC fihàn pé àwọn kan ń jí ohun èèlò ìdáàbòbò ìjọba tà nígbo