Kaduna killings: Afurasí mẹ́jọ ti wọ gbaga agbófinró nítorí ìpànìyàn Gúúsù Kaduna

Oríṣun àwòrán, @simonfmudu
Ikọ alaabo to n jẹ Security forces of Operation Safe Haven ti mu eeyan mẹjọ gẹgẹ bii afurasi to wa nidii ipaniyan to n waye ni lemọ lemọ ni iha Guusu Kaduna.
Ikọ alaabo yii lo n ri si biboju to alaafia ni ipinlẹ Plateau atawọn apa ibi kọọkan ni Bauchi ati iha Guusu Kaduna.
Nigba to n foju awọn afurasi apaniyan naa han niluu Kafanchan lọjọ Aje, oludari ikọ naa, ọgagun Chukwuemeka Okonkwo ni bi ọwọ ṣe tẹ wọn yii jẹ lara akitiyan ikọ ọhun lati gewọ ipaniyan naa.
- Èèyàn 290 míràn ló ṣẹ̀ṣẹ̀ fara káásá àrùn Covid-19 ní Nàìjíríà, 160 gbàwòsàn
- Wọ́n ti sún ọjọ́ ìjà Mike Tyson pẹ̀lú Roy Jones Jr síwájú
- Asojú ìjọba orílẹ̀-èdè Lebanon ti kọ̀wé fipò silẹ̀ nítorí ìbágbàmù tó gbẹ̀mi ènìyàn 200
- Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún ọ̀rọ̀ ibojì òkú, àti àwọn ipò òṣèlú mìíràn tó jẹ́ kàyééfì ní Nàìjíríà
- Diezani gan an ní Hushmummy tó ń bú àwọn Yahoo boys- Àwọn Ọmọ Naijiria lórí Twitter
Ogagun Chukwuemeka Okonkwo ṣalaye pe awọn iroyin ọlọgbọ́n ti awọn ri gba lo jẹ ki wọn ri awọn apaayan mu.
Ẹwẹ, oludari ikọ naa ni wọn ti bẹrẹ afikun iwadii, ati pe awọn yoo ko wọn le ọlọpaa lọwọ lati tẹsiwaju ninu iwadii ati fifi wọn jofin.
Okonkwo tun jẹ ko di mimọ pe wọn pa ọkan lara awọn to kopa ninu ikọlu laipẹ yii lagbegbe naa.
O ni: "Ikọ wa lo ri oku rẹ ni abule Kibori lasiko ti a n ṣe iṣẹ idoola".
O ni awọn yoo ṣi ta awọn ọlọpaa lolobo nipa awọn ọdaran to ṣe ikọlu eyi to ṣẹṣẹ kọja.
- A ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ibì tí owó tí àwọn adigunjalẹ̀ gbé ní banki Okeho wọ̀lẹ̀ sí- Ọlọ́pàá
- Ìyàwó Bukola Saraki fún tìyá-tọmọ olójú búlúù ní N250, 000!
- Ẹgbẹ́ àwọn awakọ̀ epo rọ̀bì NUPENG so ìyanṣẹ́lódì tí wọ́n gùnlé l'Eko rọ̀
- Ìdí rèé tí igbákejì Gómìnà Ondo Agboola Ajayi tún ṣe fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀
- Baba Obasanjọ kò ní àrùn Coronavirus- NCDC

Oríṣun àwòrán, others
Ṣaaju ni Kaduna lẹyin ipaniyan awọn eeyan Guusu ni ibẹrẹ:
Awuyewuye ń wáyé lórí bí ìjọba Ìpínlẹ̀ Kaduna ṣe kó àwọn oníbárà sí àhámọ́
Ede aiyede ti n waye laarin ijọba ipinlẹ Kaduna, ati awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ, nitori bi ìjọba ṣe mu àwọn onibara kuro ni titi.
Awọn afọ́jú, arọ, adití, obìnrin ati arugbo ni wọn ko kuro lopopona gbogbo.
Diẹ lara awọn eniyan naa sọ fún BBC pe lasiko ti awọn n tọrọ bara ni awọn agbofinro ko àwọn ni ilu Kaduna, lọjọ Ẹti.
Bakan naa ni awọn eeyan naa sọ pe ibi ti wọn ko wọn si ko dara rara, nitori ko si oúnjẹ ati omi.
- Àwọn aláànú dìde ìrànlọ́wọ́ fún tìyá-tọmọ olójú búlúù
- Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún ọ̀rọ̀ ibojì òkú, àti àwọn ipò òṣèlú mìíràn tó jẹ́ kàyééfì ní Nàìjíríà
- Diezani gan an ní Hushmummy tó ń bú àwọn Yahoo boys- Àwọn Ọmọ Naijiria lórí Twitter
- A ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ibì tí owó tí àwọn adigunjalẹ̀ gbé ní banki Okeho wọ̀lẹ̀ sí- Ọlọ́pàá
Ẹnikan lara wọn to fẹ ká fi orukọ bo oun ni asiri sọ pe "igbẹ ewurẹ, ati ẹfọn lo kun ibi ti wọn ko wa si. Ko si si ẹni to fẹ ta oúnjẹ fun wa, ayafi fun awọn to ba mu owo dani lara wa".
Sugbọn sa, ijọba sọ lati ẹnu kọmiṣọnna fun ìdẹ̀rùn ara ilu, Hafsat Muhammad Baba, pe igbesẹ naa jẹ dandan nitori pe awọn onibara naa ko tẹle asẹ ati ilana ti ijọba la kalẹ.
Bakan naa lo sọ pe awọn eeyan to n gbe ni awọn agbegbe ti awọn onibara naa ti n tọrọ owo sọ pe wọn n ba agbegbe awọn jẹ.
Ẹgbẹ awọn akanda ẹ̀dá láwùjọ sọ pe igbesẹ naa tako ileri tí wọn ṣe fun awọn lasiko ìpolongo ibo.
Akọwe ẹgbẹ naa ni ipinlẹ Kaduna, Muntari Saleh sọ fun BBC pe ijọba ṣeleri fun wọn ni awọn ipade ti wọn jọ ṣe latẹyinwa pe, òun ko ni i fi ofin mu ẹnikẹni lasiko yii.
O ni: "Ojiji ni a deede ri wọn, ti wọn si bẹrẹ si ni i ko gbogbo wa.
Wọn ko bikita boya onibara ni ọ, tabi bẹẹkọ. To o ba ṣa ti jẹ akanda ẹ̀dá, mímú ni.
O le ni ọgọrun eeyan ti wọn ti mu si ahamọ."
O ni o jẹ ibanujẹ pe ijọba ko awọn eeyan naa si ahamọ, lai bikita fun aarun coronavirus to wa l'ode.
Ọpọ eeyan si ti sọ pe òṣì lo n mu ki awọn eeyan o ma a tọrọ baara, paapa awọn ọmọde ti awọn obi wọn maa n fi si abẹ ẹ̀kọ́ almajiri, nitori a ti jẹun.
Ọpọlọpọ ipinlẹ ni Ariwa Naijiria ti gbiyanju lati fi opin si ti tọrọ baara.
Ọpọ wọn lo si ti da awọn ọmọ almajiri pada si ipinlẹ ti wọn ti wa, lasiko coronavirus.
Bo tilẹ jẹ pe ijiroro si n waye lori pe boya ki ijọba fi aaye gba awọn akanda ẹ̀dá lati ma a tọrọ bara, awọn onímọ̀ sọ pe iyatọ wa laarin awọn to n tọrọ bara jẹun ati awọn ọmọ almajiri.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ki lo ti kọkọ ṣẹlẹ ni ipinlẹ Kaduna laipẹ?
Tí ìjọba kó bá dẹ́kun ìpànìyàn ní Gúúṣù Kaduna, aráàlú yóò jà fúnra wọn - CAN
CAN ní àwọn ènìyàn yóò jà fún ara wọn tí ìjọba kó bá paná ìṣekúpani ní Gúúṣù Kaduna
Ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi lorilẹede Naijiria, CAN ti fesi si iṣekupani ojoojumọ to n waye ni Guusu ipinlẹ Kaduna, ti agbegbe ti awọn ọmọlẹyin Kristi pọ si julọ.
Aarẹ ẹgbẹ naa, Samson Ayokunle sọ ninu atẹjade to fi sita lati ipasẹ gba ọwọ oluranlọwọ pataki lori eto iroyin, Adebayo Oladeji pe ki ijọba wa nkan ṣe si ni kiakia.
Laarin ọsẹ kan, eniyan mẹtalelọgọta ni awọn aṣekupani da ẹmi wọn legbodo ni Guusu Kaduna.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ayẹyẹ ìgbaniwọlé sínú ẹgbẹ́ òkùnkùn bẹ́yìn yọ, wọ́n lu ọmọ ẹgbẹ́ tuntun pa
- Akeredolu yan ọmọ Ilajẹ gẹ́gẹ́ bíi igbákejì rẹ̀ tí wọ́n yóò jọ díje dupò ní Ondo
- Ìjọba àpapọ̀ ti gba 800 bílíọ̀nù padà lọ́wọ́ àwọn tó jí owó ìlú kó, àwọn 1,400 ti wà nínú ẹ̀wọ̀n -Lai Mohammed
- Toke Makinwa ti sọ̀rọ̀; Amcon náà dá a padà fún un pé...
- Ọwọ́ tẹ́ àwọn ọkùnrin Fulani mẹ́ta tí wọ́n jí Màálù méjì kó ní Ogbomọṣọ- Àjọ NSCDC
- Ọmọ́ Yorùbá korò ojú sí Buhari bí kò ṣe fi orúkọ Obasanjo sọ ibùdókọ̀ ojú'rin
- Ọ̀nà tó fi le è mọ gbájúẹ̀ babaláwo - Ẹlẹ́buìbọn
Ayokunle ni iṣekupani olojoojumọ yii gbọdọ dopin, lai jẹ bẹẹ awọn eniyan yoo bẹrẹ si ni da aabo bo ara wọn.
Bakan naa lo fikun pe awọn eniyan naa yoo bẹrẹ si ni koju awọn aṣekupani naa nitori ipaniyan naa ti pọ ju bo ṣe lọ.

Oríṣun àwòrán, Twitter
O fikun pe awọn eniyan n wo oju ijọba ti wọn dibo yan fun aabo to peye, amọ wọn kọ lati dide si wọn.
- Ìjọba àpapọ̀ ti gba 800 bílíọ̀nù padà lọ́wọ́ àwọn tó jí owó ìlú kó, àwọn 1,400 ti wà nínú ẹ̀wọ̀n -Lai Mohammed
- Ọwọ́ tẹ́ àwọn ọkùnrin Fulani mẹ́ta tí wọ́n jí Màálù méjì kó ní Ogbomọṣọ- Àjọ NSCDC
- Ọmọ́ Yorùbá korò ojú sí Buhari bí kò ṣe fi orúkọ Obasanjo sọ ibùdókọ̀ ojú'rin
- Irọ́ ni o, kò sí ẹ̀rí pé Hydroxychloroquine leè kojú àrùn Coronavirus- Ẹgbẹ́ àwọn adarí ilé ìwòsàn ní Naijiria
Aarẹ ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi, Samson Ayokunle naa ni, ọpọlọpọ igba ni oun ti kọ iwe si Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai, to si fi da oun loju pe awọn yoo pese aabo fun awọn eniyan.
Amọ, o ni ibanujẹ lo jẹ fun awọn, nitori pe ijọba ipinlẹ Kaduna kọ lati gbe igbesẹ to yẹ lati pese aabo fun wọn.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ayọdele ni ijọba gbọdọ pese aabo fun awọn eniyan ara Guusu Kaduna naa ki wọn ba le ni igbagbọ ninu ijọba.
Ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi lorilẹede Naijiria naa ni ohun to buruju ni pe ijọba aarẹ Buhari ni ọrọ oṣelu lo n fa iṣekupani to n waye ni Guusu Kaduna naa.
Aráàlú faraya torí èèyàn 63 tó dèrò ọ̀run ní Gúúṣù Kàdúná láàrin ọ̀sẹ̀ kan
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe, ariwo ẹkun tun sọ ni Guusu ipinlẹ Kaduna lopin ọsẹ nigba ti awọn gende agbebọn tun se ọsẹ.
Bi o tilẹ jẹ pe isede konile o gbele wa ni agbegbe naa lati dẹkun iwa isekupani to n waye ni lemọlemọ, sibẹ, akọtun isẹlẹ ikọlu tuntun yii waye.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Lizzy Anjọnrin fẹ̀si fáwọn agbọ́yì-sọ̀yí lórí ìgbéyàwó rẹ̀, Madam Sajẹ dasójú ilé iṣẹ́, àti àwọn ǹkan míràn tó ṣẹlẹ̀ lágbo tíátà lọ́sẹ̀ yìí
- Bí o ṣe lè forúkọ silẹ̀ fún ètò "N75BN Nigerian Youth Investment Fund" rèé...
- Ilé iṣẹ́ ọmọogun òfurufú ti bẹ̀rẹ̀ ètò ìgbaníwọlé- Àwọ ìlànà ìforúkọsilẹ̀ rèé
- Ṣé àbáwọle sójú òpó NPF policerecruitment.gov.ng.ng yìí níra? wo àwọn nọ́mba ọlọ́pàá tí o lé pé láti mọ ọ̀nà àbáyọ
- Wọ́n kí irún Jimọ àkọ́kọ́ ní Hagai Sophia lẹ́yìn ọdún 85 ní Turkey
Gẹgẹ bi ẹgbẹ awọn eeyan ẹkun Guusu Kaduna ti kede rẹ lọjọ Satide, eeyan mẹtalelọgọta lo ti dero ọrun laarin ọsẹ kan latọwọ awọn agbebọn.
Akọtun isẹlẹ yii ni wọn lo waye ni aago meje owurọ ọjọ Satide, nigba ti awọn agbebọn naa kọlu abule mẹta, ti wọn si pa eeyan mẹsan.

Oríṣun àwòrán, @simonfmudu
Eeyan mọkanla lo fi ara gbọgbẹ lorisirisi lasiko ikọlu naa, ti wọn si tun jo ọpọ ilegbe kanlẹ.
Nigba to n salaye bi isẹlẹ naa se waye, ẹnikan ti isẹlẹ naa soju rẹ ni o to awọn agbegbọn bii aadọta lo ya bo abule Zikpak, ti wọn si n yinbọn laibikita.
Lẹyin ti wọn pari ọṣẹ ti wọn fẹ se ni abule naa ni wọn tun morile abule Ungwan Masara ati Maraban Kagoro.
Nibayii, ọpọ ọmọ Naijiria ni wọn ti n koro oju si iwa isekupani to n fi ojoojumọ waye ni ẹkun Guusu Kaduna naa ati ikọlu awọn agbegbọn to n waye loore koore nibẹ.
Ẹmi marun un sọnu ninu ija Kaduna

Oríṣun àwòrán, AFP
Saaju la ti kọkọ mu iroyin wa fun yin pe, eniyan marun ti padanu ẹmi wọn, ti ọgọọrọ mii si farapa ninu isẹlẹ to waye lagbegbe Kasuwan nipinlẹ Kaduna.
Iroyin naa sọ wipe agbegbe tikọlu naa ti sẹlẹ ko jinna si aarin gbungbun ilu Kaduna to lọ si ipinlẹ Plateau, Nasarawa ati Benue.
Awọn eeyan kan to bawọn akọroyin sọrọ ni awọn ko lee sọ ohun to sokunfa aawọ ọtun yi.
Wọn fikun wipe, awọn ọlọpa to tete koju isẹlẹ naa, ni ko jẹ ki ọrọ naa di ti ija ẹsin.
Nibayi, Gomina ipinlẹ Kaduna, Malam Nazir El-Rufai ti pasẹ fun awọn eleto aabọ ipinlẹ naa lati se ofin toto isẹlẹ naa, ki wọn si fi awọn to wa nidii ọrọ naa jofin.
















