Hydroxychloroquine, Zinc ati Zithromax : Ààrẹ Trump tí sọ̀rọ̀ nípa Dókítà Stella Immanuel,ẹ gbọ́ ohùn tó sọ

Aworan Dokita Stella Immanuel ati Aarẹ Trump

Oríṣun àwòrán, Getty/Twitter

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Aarẹ orilẹede Amẹrika, Donald Trump ti fesi lori ọrọ Dokita Stella Immanuel to sọrọ pe Hydroxychloroquine (HCQ), Zinc ati Zithromax jẹ oogun to daju lati wo awọn to ba ni arun Covid-19.

Ninu ọrọ rẹ, o gbaruku ti Dokita yi to si sọ pe awọn onimọ iṣegun n tako lilo oogun yi nitori pe ohun ni oun kọkọ sọ pe ki awọn eeyan ma lo.

O fi ọrọ yii sita lẹyin ti oju opo Twitter gbọn ọmọ rẹ agba lọkunrin kuro lori opo wọn nitori pe o ṣe alabapin fidio ti Dokita Stella ti sọ pe ki awọn eeyan ma lo Hydroxychloroquine (HCQ).

Ki gaan ni Aarẹ Trump sọ?

Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni Ile Ijọba Amẹrika, White House ni Aarẹ Trump fesi lori ọrọ yii ni idahun si akọroyin to ni ki lo ri si ọrọ naa.

Aarẹ Trump sọ pe ''Mo le sọ fun yin pe arabinrin naa ati awọn Dokita miran ti wọn faramọ lilo oogun Hydroxychloroquine ni wọn jijọ sọrọ lori afẹfẹ.

Mo si le ro pe ọrọ rẹ jọju botilẹjẹ wi pe mi o mọ ibi to ti wa.

Ṣugbọn o sọ pe oun ti ṣe aṣeyọri pupọ lori lilo oogun yi pẹlu awọn alarun Covid-19.Mo lero pe o ṣe apataki ki a tẹti gbọ ọrọ rẹ ṣugbọn mi o mọ nkankan nipa rẹ''

Kete to sọrọ yii tan lo ba wọ inu ọfisi rẹ lọ pada.

Bakan naa ni Aarẹ Trump sọ fun awọn akọroyin ni Ọjọ Iṣẹgun pe: ''Ohun ti o ye mi nipa ọrọ yi ni mo le sọ.

Ti a ba si fi bi mo ti ṣe ka nipa arun yi ati imọ ti mo ni,mo lero pe lilo hydroxychloroquine lati tọju awọn eeyan nibẹrẹ ni anfaani to pọ''

''Mi o lero pe eeyan le padanu nkankan ti o ba lo bi kii ṣe pe lọdọ awọn oloṣelu ọrọ yii ko ta leti wọn''

Trump fi kun pe ''Bi mo ba daba nkan , wọn maa n fẹ lati sọ pe 'ẹ ma tẹlẹ ọrọ rẹ' .''

''Ẹyin ti ẹ lo hydroxychloroquine ti ara yin si ya, ẹ bọsita wa jẹri mi''

Dokita Stella Immanuel ti kesi gbogbo awọn ti oun ati awọn Dokita miran ti tọju pẹlu oogun hydroxychloroquine lati yọju lati wa jẹri si iṣẹ rere ti oogun yi ṣe lagọ ara wọn.

O fi ọrọ yii sita ninu fọnran fidio kan lẹyin ti Twitter yọ fidio to kọkọ ti sọrọ nipa lilo oogun yii lati tọju arun Covid-19.

Eeyan to le ni eeyan ọọdunrun ti Dokita Stella ti sọ pe oun tọju pẹlu Hydroxychloroquine ti ara wọn si ti ya.

Aworan Dokita Stella Immanuel

Oríṣun àwòrán, Twitter

O sọ pe ''ti o ba ti lo hydroxychloroquine ti ara rẹ si ti ya. Asiko rẹ lati jade wa sọrọ. A fara da ewu to pọ lati tọju yin, koda a fi ẹmi awọn mọlẹbi wa sinu ewu lati tọju yin''

Stella fi kun pe ''A ni lati jẹ ki awọn eeyan mọ pe awọn eeyan tia le foju ri lo ti jẹ anfaani itọju yi''

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Irọ́ ni o, kò sí ẹ̀rí pé Hydroxychloroquine leè kojú àrùn Coronavirus- Ẹgbẹ́ àwọn adarí ilé ìwòsàn ní Naijiria

Ẹgbẹ awọn adari ile iwosan ni Najiria, GMD ti ni ọrọ ti dokita Stella Emmanuel, to jẹ oṣiṣẹ eto ilera nilẹ Amẹrika sọ pe oun lo Hydroxychloroquine (HCQ), Zinc ati Zithromax lati fi ṣetọju arun Covid-19 ko bojumu to.

Ninu atẹjade kan ti aarẹ ẹgbẹ naa, Ọjọgbọn Olufemi Babalola fọwọ si ni ilu Abuja, o ni ko si ẹri aridaju to fidi rẹ mulẹ pe awọn oogun ti dokita naa darukọ lee wo arun Coronavirus.

Ẹgbẹ naa ni dokita Stella ko sọrọ lorukọ apapọ awọn oṣiṣẹ eto ilera, bikoṣe lorukọ ara rẹ.

Ṣaaju ni fidio kan ti jade lori ayelujara, ninu eyii ti dokita naa ti sọ pe oun lo awọn oogun naa lati fi tọju aadọtalelọọdunrun eeyan to ni arun Coronavirus, ti gbogbo wọn si ri iwosan.

Lẹyin naa lo ke pe awọn oṣiṣẹ eto ilera ilẹ Amẹrika lati doola ẹmi awọn ọmọ orilẹede naa to n ku nitori arun ọhun pe, oogun Hydroxychloroquine ni idahun si arun Covid-19.

Àkọlé fídíò, Hepatitis: A kò leè kóo nípa dídìmọ́ ara ẹni

Aarẹ GMD ni awọn onimọ nipa eto ilera ko tii pari iwaddi wọn lati mọ boya apapọ Hydroxychloroquine, Zinc ati Zithromax lee koju Covid-19.

O ni ki ẹnikẹni ma ṣe gba imọran dokita Stella Emmanuel wọle titi di igba ti imọ ijinlẹ yoo fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni awọn oogun naa le wo alarun Coronavirus san

Ẹwẹ, ileeṣẹ atẹsjiṣẹ Twitter ti pa a laṣẹ fun ọmọ aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump kekere pe ko yọ ohun to sọ nipa oogun Hydroxychloroquine kuro loju opo rẹ nitrori o le e ṣi awọn eeyan lọna.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Washington Post ṣe sọ, igbesẹ yii lo waye lẹyin ti ọmọ aarẹ ọhun pin fidio awọn dokita kan to n sọrọ ti wọn ni o le e ṣi awọn eeyan lọna nipa ajakalẹ arun Coronavirus.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Coro

Oríṣun àwòrán, others

Dr Stella Immanuel: Facebook yọ fídíò òògùn ìwòsàn Coronavirus

Oju opo ayelujara Facebook, Periscope atawọn oju opo ayelujara miran ti fa fidio obinrin alawọ dudu kan, Dokita Stella Immanuel yọ, eyi to se lati salaye idi ti oogun iba Hydroxychloroquine fi pegede lati wo arun Coronavirus san.

Wọn fa fidio naa yọ lori ayelujara lẹyin ti eeyan miliọnu mẹrinla ti wo o.

Koda, aarẹ Donald Trump tilẹ Amẹrika fi fidio naa soju oò Twitter rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu fido naa ni Dokita Stella Immanuel, tii se onisegun alabọde nilu Houston kede nibi ipade akọroyin kan pe, oun ti fi oogun Hydroxychloroquine wo alarun Coronavirus to to ọtalelọọdunrun o din mẹwa.

Oogun chloroquine

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Immanuel ni awọn arugbo lo pọ ju ninu awọn alaisan Coronavirus ti oun wosan, koda, awọn miran ni aisan atọgbẹ ati ikọ semisemi.

"Mo fun wọn ni oogun Hydroxychloquine mu pẹlu Zinc ati Zithroma, ti ara gbogbo wọn si da."

Lọwọlọwọ bayii, awọn eeyan to ni arun Coronavirus le ni miliọnu mẹrindinlogun ni orilẹede mejidinlaadọwa.

Awọn eeyan to to ẹgbẹrun lọna ọtalelẹẹdẹgbẹta lo ti ku lati ipasẹ arun Coronavirus.

Òhun tó yẹ ko mọ nípa Dókítà Stella Immanuel to ní ohùn dóòlà alàrùn 300 lọ̀wọ̀ ààrùn Covid-19

Jiji ti awọn ọmọ Naijiria ji lowurọ ọjọ Iṣẹgun ni wọn ṣalabapade fọnran fidio kan, ti o ṣe afihan Dokita obinrin alawọdudu kan lorileede Amẹrika to n sọ fawọn eeyan pe arun Covid-19 ni oogun to daju.

Dokita Stella Immanuel ninu fọnran fidio yii darukọ oogun hydroxychloroquine, zinc ati Zythromax gẹgẹ bi awọn oogun ti ohun ti fi tọju alaisan Covid-19 to le ni ọọdunrun.

Ohun ati awọn agbarijọpọ onimọ iṣegun ti wọn pe ara wọn ni America Frontline Doctors ni wọn ba awọn oniroyin sọrọ ninu fọnran fidio yi ni Washington DC.

Jakejado agbaye lawọn eeyan ti n sọ nipa lilo oogun yi lati koju ati fun itọju arun Covid-19.

Ajọ eleto ilera agbaye WHO ti sọ pe ki wọn da iwaadi duro lori lilo oogun yi fun itọju Covid 19 nitori pe ko ṣiṣẹ.

Amọ ṣa fọnran fidio yi gbode kan koda eeyan to le ni miliọnu mẹrinla lo ti wo loju opo Facebook ki wọn to yọ kuro.

Àkọlé fídíò, Ǹjẹ àgbo lè ṣe òògùn coronavirus?

Fidio yi ti wa mu ki awọn eeyan ma beere pe ta ni Dokita yi to sọ pe ni Naijiria loun ti kẹkọ nipa eto iṣegun ilera.

Iwaadi ti BBC Yoruba ṣe nipa rẹ tu aṣiri awọn nkankan nipa Dokita yi. Diẹ ninu ohun ta mọ nipa rẹ ree

Kii ṣe ọmọ Naijiria ni Dokita Stella

Ọpọ awọn to n ṣalabapin fidio yi lo lero wi pe ọmọ Naijiria ni Dokita Stella.

Ninu awọn fọnran fidio to gbe sita Dokita Stella sọ pe ohun kẹkọ gboye ni orileede Naijiria.

Ko sọ ni pato boya ọmọ Naijiria lohun n ṣe ṣugbọn ninu apejuwe to ṣe si oju opo Facebook rẹ, o kọ sibẹ pe fasiti ilu Calabar, ni Naijiria ni ohun ti kẹkọ nipa imọ ilera.

Bakan naa lo kọ sibẹ pe oun lọ si ile ẹkọ Cameroon Protestant College.

Loju opo Amazon nibi to ti polowo iwe kan ti o kọ, apejuwe nipa Dokita Stella sọ pe ọmọ ilẹ Cameroon nii ṣe.

Orukọ rẹ Gwandiku Tita jẹ orukọ tawọn eeyan to wa lati ilu Bali ni orileede Cameroon n jẹ.

Yatọ si pe o jẹ Dokita,oniwaasu Kristẹni ni Dokita Stella

''Dokita nikan kọ ni mi.Mo n fi adura jagun''

Ọrọ ti Dokita Stella fi ṣe apejuwe ara rẹ ree ninu fọnran fidio kan to fi si oju opo ile iwosan rẹ Rehoboth Medical Centre to wa ni ilu Houston Texas lorileede Amẹrika.

Dokita Stella tun ni oju opo ile ijọsin rẹ,Fire Power Deliverance Ministries nibi ti o ti n ṣe iwaasu loore koore nilana Kristẹni.

Dokita Stella

Oríṣun àwòrán, @stella_immanuel

Lọpọ awọn fọnran fidio to fi sita, o ma n ṣe iwaasu lori bi awọn eeyan ti ṣe yago kuro lọna Kristi nipa kikopa ninu awọn iwa ẹṣẹ bi ibalopo laarin akọ si akọ ati abo si abo.

Imọ nipa itọju ọmọde lo kọ nipa bawo lo ṣe wa n tọju alarun Covid-19

Aworan Dokita Stella Immanuel

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ibeere yi wa lara ohun tawọn to n tako ọrọ rẹ n beere nipa bi o ti ṣe ni ohun n tọju alarun Covid 19.

Leyi ti BBC ri fidi rẹ mulẹ, Dokita Stella kẹkọ gboye ti o ṣi n ṣe itọju awọn ọmọde nile iwosan Rehoboth Medical Centre to ti n ṣiṣẹ.

Ko daju igba to bẹrẹ si ni tọju awọn agbalagba tabi boya o kẹkọ gboye nipa itọju awọn agbalagba ṣugbọn o sọ pe awọn agbalagba alarun Covid 19 to ni ipenija ilera bi aisan itọ ṣuga ati aisan ọkan wa lara awọn ti ohun ti tọju ti ara wọn si ti ya.

Mo fẹ foju kan aarẹ Trump

Lara awọn ti ọrọ Dokita Stella yoo dun mọ ninu ni aarẹ orileede Amẹrika Donald Trump ati awọn alatilẹyin rẹ.

Idi ni pe Aarẹ Trump ko ye tẹnu mọ pe oogun hydroxychloroquine jẹ oogun kan gbogi to ma n koju arun Covid 19.

Ninu ọrọ rẹ to fi sita loju opo Twitter, Dokita Stella kesi aarẹ Trump lati gba ohun lalejo ni olu ilu Amẹrika ti ṣe Washington DC nibi ti ohun ati awọn Dokita kan ti n sọrọ nipa lilo hydroxychloroquine.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Ki lawọn eeyan ri si ohun ti Dokita Stella sọ nipa hydroxychloroquine

Ero ṣe ọtọọtọ lori ohun ti Dokita Stella sọ loju opo Twitter nipa lilo hydroxychloroquine lati koju arun Covid 19.

Bi awọn kan ti ṣe n bẹnu atẹ lu lawọn miran gboṣuba kare fun gẹgẹ bi oniṣegun to dantọ.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

Ìjọba ti wọ́gilé, ètò ìgbéyàwó tó le ni 4000 nítori Covid-19

Ó lé ni ètò ìgbéyàwó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin tí kóòtù ìgbeyawo ìjọba àpapọ̀ tó wà ni Ikoyi ló ti wọ̀gile forúkọsilẹ̀ àwọn tó fẹ́ ṣe ìgbéyàwó níbẹ̀.

Ikoyi Registry: Ìjọba ti wọ́gilé, ètò ìgbéyàwó tó le ni 4000 nítori ààrùn Coronavirus

Oríṣun àwòrán, others

Ilé iṣẹ́ tó n ri si ọ̀rọ̀ abẹ́le ní Naijria, to sì tún ṣe àmújúto kóòtù to n ṣe ìgbéyàwó ti paa láṣẹ pé kí wọ́n mú ìdádúró ba ètò ìgbéyàwọ́ ti wọ́n forúkọsílẹ̀ láti inú oṣù kẹta nítóri àjàkálẹ̀ ààrùn Coronvirus.

Ìwádìí fi han pé ẹni tó bá fẹ le lọ lo àwọn kóòtù míràn ni àwọn agbègbè míràn kí wọ́n wá sọ, sùgbọ́n ẹni náà yóò san bi ẹgbẹ̀rùn lọ́nà ọgbọ̀n náírà sí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ààdọ́ta náírà.

Gẹ́gẹ́ bi ẹni kan ti ọ̀rọ̀ náà kàn ṣe sọ yíyí ibi ti wọ́n yóò ti ṣe ìgbéyàwó pada ní kí wọ́n sọ ìbi tó bá wù wọ̀n lọ́kan, àwọn òṣìsẹ́ kóòtù yóò lọ síbẹ̀ láti ṣe ètò náà.

Ó ní òun ti fi orúkọ sílẹ̀ láti inú oṣù kẹfà ọdún yìí to sì san ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n náìrà tí wọ́n si fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ pé ètò náà yóò wáyé ní ọjọ́kẹrìnlá, oṣù kẹfà, ọdún 2020.

Sùgbọ́n nígbà ti òun débẹ̀ lọ́jọ́ náà ni wọ́n sàlàyé pé nítori ààrùn Covid-19, àwọn kò ní lé ṣe ètò náà mọ́.

"Ẹni náà ni ọkùnrin tó gbé fóònù sọ pé ó lé ni ènìyàn ẹgbẹ̀run mẹ́rin tó ti wà nílẹ̀ láti inú oṣù kẹ̀ta, o ní wọ́n sọ pé tí òn bá le dúro àwọn yóò fi ìpè ránṣk ti àsìkò bá ti tó, sùgban ti kò bá le dúro àwọn lé wá ṣe fun nílé, sùgbọ́n yóò san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ààdọ́ta náírà."

Àbẹ̀wò sí kóòtù Ikoyi, lógúnjọ oṣù kéjé fi han pé , ẹni tó bá wù nìkàn ló le mú ibi tó bá wùú ti yóò sì san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ààdọ́ta náírà.

Ẹ̀wẹ̀, àgbẹnusọ ilé iṣẹ́ tó ọ̀rọ̀ abẹ́lé, Mohammed Manga sàlàyé pé, owó ayípada ibudó tuntun láti ọ̀ds ìjọba kò ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀gbọ̀n náírà lọ