Toke Makinwa, Banana Island house & Festus Fadeyi: Toke Makinwa fọhùn síta; Jude tí Amcon náà dá a padà pé...

Toke

Oríṣun àwòrán, tokemakinwa

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Toke Makinwa to jẹ gbajugbaja sọrọsọrọ lori ẹrọ redio ti sọrọ lori ọrọ ile rẹ ni agbegbe Banana Island ati ileeṣẹ Amcon to ti n ja lori ayelujara yii.

Agbenuso ileeṣẹ Asset Management Coporatiion of Nigeria, Ogbẹni Jude Uwauzor ti ba ileeṣẹ BBC sọrọ ni kikun bayii.

Jude ni Ko si ohun to pamọ ninu pe Pan Ocean jẹ Amcon lowo ni eyi ti a mọ si gbese.

Ati pe, Ileeṣẹ Amcon ti gbẹsẹ le awọn ohun ini Pan Ocean kọọkan nitori gbese naa to to oji le ni igba biliọnu owo naira.

Toke

Oríṣun àwòrán, tokemakinwa

O ni oun ko mọ nipa ile Toke Makinwa ti wọn n pariwo yii nitori oun ko le ṣo ni pato boya ile naa wa lara eyi ti ileeṣẹ Amcon gbesẹ le tabi boya ko si nibẹ.

Ogbẹni Uwauzor ṣalaye pe ile ẹjọ lo buwọlu awọn ohun ini Pan Ocean ti Amcon fofin de ni eyi ti kii ṣe pe Amcon kan deede gbe igbesẹ to wuu ni.

O fidi ẹ mulẹ pe ti ile Toke Makinwa ba wa nibẹ ko si ohun ti ẹnikẹni le ṣe sii nitori ko sẹni to kọja ofin.

Jude fi kun un pe ni kete ti Amcon ba ti gbeṣẹ le ohun ini kan, labẹ ofin, o ti di tita ni ori igba ni yẹn ni eyi ti wọn yoo fi ri owo tiru ẹni bẹẹ ba jẹ gba pada lẹyin tita irufẹ ohun ini bẹẹ.

Kini Toke Makinwa funra rẹ sọ lori iṣẹlẹ yii?

Toke MAkinwa funra rẹ ti sọrọ sita pe: Toke Makinwa ṣi wa ninu ile rẹ o!

O ni ile oun to wa ni Ikoyi ni oun ṣi wa titi di asiko yii ati pe ile oun ko si ni agbegbe Banana Island rara bikoṣe Ikoyi.

Eyi ni ọrọ mánéjà Toke Makinwa nigba ti BBC kan sii lati mọ okodoro ọrọ to n ṣẹlẹ.

Alamojuto Toke Makinwa ni irọ ni gbogbo ahesọ naa ati pe awọn ko le maa dahun si gbogbo ahesọ ti awọn eeyan ba n sọ nipa oju oge sọrọsọrọ naa.

Toke Makinwa

Oríṣun àwòrán, @tokstarr

Ṣé lóòótọ́ ni Amcon gba ilé Toke Makinwa ti wọn ní bàbá olówó rà á fun?

Wọn ní Bàbá olówó jẹ báńkì kan ní ₦240bn ni Amcon ṣe gba ilé náà

Ariwo orúkọ gbajugbaja oṣiṣẹ radio kan nilu Eko, Toke Makinwa, lo gba ori ayelujara lati ọjọ Aje.

Eyi ko sẹyin iroyin kan to jade pe, ajọ to ma n ba ni sin gbèsè ni Naijiria, AMCON, ti gbẹsẹ le ile rẹ to wa ni Banana Island nipinlẹ Eko.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Banana Island jẹ ọkan lara awọn adugbo ti awọn ile to jẹ oju ni gbese pọ si julọ, ẹnikẹni ti yoo ba gbé nibẹ, si gbọdọ jẹun kanu daada, nitori pe obitibiti miliọnu ni wọn n ta ilẹ nibẹ.

Ile Toke Makinwa

Oríṣun àwòrán, @tokstarr

Iroyin naa sọ pe, Makinwa fun ẹnikan ni èsì lórí Twitter pe, o da oun loju pe awọn to n fi oun ṣe yẹyẹ nitori pe Amcon ti ile oun pa, si n pada bọ wa tọrọ owó lọwọ òun.

Toke Makinwa

Oríṣun àwòrán, @tokstarr

Ko tan síbẹ̀ o, iroyin naa sọ pe, ọkùnrin olowo tabua kan, Festus Fadeyi, to tun jẹ alaga ileesẹ epo bẹtiro Pan Oceanic Oil Corporation, lo fun Toke ni ile naa lọdun diẹ sẹyin.

A gbọ pe Fadeyi jẹ ile ifowopamọ Skye Bank ni ojilerugba biliọnu Naira (240 billion) , ti ko si ti i san án.

Alaye banki Skye lori gbese ti Fadeyi jẹ

Oríṣun àwòrán, Skye Bank release

Eyi lo mu ki ajọ Amcon gbẹsẹ le awọn dukia rẹ kan to fi ṣe oniduro. Lara awọn dukia naa ni ile ti Toke n gbe.

Toke Makinwa fúnra rẹ ko ti i sọ boya otitọ tabi irọ ni iroyin naa.

Festus Fadeyi ati Toke Makinwa

Oríṣun àwòrán, @tokstarr

Gbolohun kan to kọ sori ayelujara Twitter rẹ lati igba ti ariwo naa ti bẹrẹ ni pe "We move" - eyi ti a le sọ pe o tumọ si pe, ohunkohun to wu ko ṣẹlẹ, igbe aye n tẹsiwaju naa ni.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Bo tilẹ jẹ pe BBC Yoruba ko le fidi eyi mulẹ, oriṣiriṣi ni awọn ololufẹ Makinwa ati awọn eeyan ti n sọ lori ọrọ naa.

Awọn miran ti ẹ tun hu iroyin kan to jade lọdun 2017 sita, nibi ti awọn ọmọ Fadeyi ti pariwo sita pe, ki Toke fi baba wọn lọrun silẹ.

Wọn ni ori Toke ni baba awọn n run owo le.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

African Parents: Òbí ayé àtijọ́ ló tọ́ ọ dàgbà tí o bá ṣe àwọn ǹkan wọ̀nyii

Toke Makinwa

Oríṣun àwòrán, @TokeMakinwa/Instagram

Àkọlé àwòrán, African Parents: Obí ayé atijọ ló tọ́ ọ ti o ba ṣe àwọn ǹkan wọ̀nyii

Gbájugbaja sọ̀rọ̀ sọ̀rọ̀ orí radio kan Toke Makinwa lo fa ibínuyọ laipẹ yìí lori ayelujara tirẹ̀ to n dari pé obí aye atijọ l'Afrika lo baye ọ̀pọ̀ ọmọ míràn jẹ́.

Toke Makinwa nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò dá òbi kankan si ni ilẹ̀ Afrika, o ní pàápàá jùlọ ọ̀na ti wọ́n ń gbà tọ ọmọ nípa ìbásepọ láàrin ọ̀kùnrin àti obìrin, ìdúró wọ́n lóri ǹkan ti o gbọdọ̀ ka ni Fasiti àti fífi ìbẹ̀rù si ọmọ lọ́kàn.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kọ́ ọmọ rẹ lẹ́kọ̀ọ́ ìbálọ̀pọ̀- Ọ̀jọ̀gbọ́n Fagbohungbe

Makinwa ni àwọn obi ni wọ́n maa n fẹ́ láti da'ri ayé ọmọ ti ọmọ náà ko si ni ẹ̀tọ lati sọ ǹkan to fẹ́ nítori wọ́n ti ko ọmọ láya jẹ tán. "Tí ènìyàn bá dàgbà nile obi nílẹ̀ Afirika, àwọn ǹkan wà ti oò le ni ore-ọ̀fẹ́ láti ṣe tabi sọ, botilẹ jẹ́ pe mo ti pé ọmọ ọdun marùnlélọ́gbọ̀n mi o ṣì lẹ́tọ lati dide lori ẹ̀sẹ̀ mi lòdì sí ǹkan ti àwọn òbí mi ba sọ"

"Àwọn obí ni Afrika lo burú jùlọ ni gbogbo àgbàyé. obí yóò sọ irú ẹkọ ti oó kà ni ilé iwe gíga"

"Wọ́n ko ni jẹ́ ki o mọ ìgbà ti o bá ń ṣe dáada ṣùgbọ́n wọ́n le sọ ǹkan ti wọ́n lérò pe o yẹ kí o maa ṣe. O dàbi ẹni pé mo nilò Dokita, o yẹ ki ọmọ mi gboye imọ iṣegun oyinbo, ti o ba si kùna nínu imọ isiro, o túmọ si pé ẹkọ imọ isìro owó ni ẹni náà yóò kangun sí."

"Awọn obi ilẹ̀ Afrika kii tọ̀rọ̀ aforiji ti wọ́n ba ṣẹ ọmọ. Wọ́n kìí ṣe àṣìṣe, Kílo fẹ́ jẹ yo láti sọ pé òbí rẹ̀ ṣe àsiṣe, o gbọdọ dá ara rẹ loju jù nitori bi àwọn òbi aye atijọ se maa n ba ọmọ wi"

O ní ìhà ti àwọn òbi Afrika wa lásìkò ti ọmọ n dàgbà pàápàá julọ lori yíyan ọrẹkunrin tabi ọ̀rẹ́binrin ti jẹ́ ki ẹlọmiran máa ni ìṣòrò nínú igbéyawọ nígba ti wọ́n ba pada lọ ilé ọkọ tàbi fẹ́ ìyàwó.

Àkọlé fídíò, 'Mo fọ́ lójú ṣùgbọ́n mo mọ gbogbo irinṣẹ́ tí mo fi ń ṣe mọkalíìkì'

Toke Makinwa ni àwọn ǹkan wọ́nyi sẹlẹ̀ si òun ni, Bi ọkùnrin ba pe mi lori aago tabi kọ lẹta ifẹ́ simi, Mo ti sàgbákò! Lóòtọ a n lọ ile ijọsin ṣùgbọ́n nítori pe ǹkan ti òbí n fẹ́ ni"

"Wọ́n a sọ fun wá pe ẹ sá fun ọkùnrin a ṣe èyi títí a o ni ọ̀rẹ́kùnrin, ṣùgbọ́n wàá dàgbà tán ko sọkọ wọ́n à sì bẹ̀rẹ̀ si ni pé oníruuru pasitọ lati wá gbàdura.

Bo tilẹ̀ jẹ́ pé Toke Makinwa sọ gbogbo ǹkan wọ̀nyi, o fi kun un pé elòmíran ko ba ti maa bugi jẹ bayii ti kìí ba ṣe pe àwọn obi rẹ̀ o buru mọ ọ.

Kekere ninu agbami ọrọ wa ni awọn apẹrẹ ti Toke Makinwa ka silẹ yii tori ṣe ni awọn eniyan gba a lẹnu rẹ ti wọn si bẹrẹ si ni wu iriri tiwọn naa sita.

"Ìya ọrẹ mi kan lọba oun ati kọ rẹ lalejo ma ni op. La ba wa nibi apejẹ kan o. Iya ọrẹ mi ba pe e pe ko ma pẹ wọle o to si da a lohun pe maami mo ma ti wa nile ọkọ kẹ. Idahun iya ni wi pe bi o ba dan an wo, o fẹ sun ita niyẹn".

Toke Makinwa

Oríṣun àwòrán, @tokstarr

"... Ori mi maa n wu ti mo ba ri awọn ọmọ to ni obi to fi ifẹ han wọn. Afi bii ara ilu oyinbo lo maa n ri loju temi. Mi o ni iru iriri yii ri. Koda ko tọ ki awọn kan ni ọmọ tabi iyawo latọdọ Ọlọrun.

Toke Makinwa

Oríṣun àwòrán, @tokstarr

"Iya mi ko ni tun ọrọ rẹ sọ lẹẹmeji, o dara koo yaa la eti rẹ daadaa koo ma baa jẹ ẹgba. A o le jade lọ ba ọrẹ ṣere afi ka ṣaa ma de oju mo ile ka si wa layika wọn...".

Toke Makinwa

Oríṣun àwòrán, @tokstarr