Oman ń ṣelédè lẹ́yìn Sultan Qaboos bin Said

Odidi aadtadun ni Sultan Qaboos fi gbakoso igbe aye oṣelu orilẹede Oman

Oríṣun àwòrán, Reuters

Sultan Qaboos ni adari ilẹ Arab to pẹ ju lagbaye, o si ti wọ kaa ilẹ sun bayii lẹni ọdun mọkandinlọgọrin.

Pẹlu ibinujẹ ni idile ọba ilẹ Gẹẹsi fi kẹdun iku Ọlọlajulọ Sultan Qaboos bin Said, to jẹ Ọlọrun nipe lọjọ ẹti gẹgẹ bi ọrọ ti ile ẹjọ fi sita.

Loṣu to kọja lo pada sile lẹyin to lọ fun ilera ni orilẹede Belgium. Iroyin ti a gb ni pe aisan jẹjẹrẹ lo n ba a ja.

Nibayii, orilẹede naa ti kede ọjọ mẹta lati fi ṣ'ọfọ rẹ.

Àkọlé fídíò, 'Mo fọ kọ́mú, pátá, ògiri ilé lórí 200,000 láìlèfọhùn lórílẹ̀èdè Oman'

Bakan naa, wọn ti ṣe ibura wọle fun minisita orilede Oman fun ọrọ aṣa, Haitham bin Tariq lati tẹsiwaju ni ipo rẹ.

Ohun taa gbọ ni wi pe Sultan Qaboos ko ni ọmọ tirẹ nitori naa o kọ orukọ ibatan rẹ sinu lẹta to kọ silẹ ti wọn ka jade gẹgẹ bi ẹni ti yoo gba eku ida lọwọ rẹ.

Sultan Qaboos gbajọba lọwọ baba rẹ lọdun 1970

Oríṣun àwòrán, KEYSTONE

Ohun to yẹ koo mọ nipa Sultan Qaboos bin Said ti Oman ree

Sultan Qaboos ko fẹ́ iyawo bẹẹ si ni ko bimọ kankan tabi ẹni ti yoo gbe ade le lori lẹyin ipapoda rẹ.

Ni ẹni ọdun mkandinlọgbọn ni Sultan yii gbajọba lọwọ baba to bi i lọmọ, Said bin Taimur lasiko itajẹsilẹ buruku kan ti ilẹ Britain ṣatilẹyin fun lọdun 1970.

Pẹlu ọwọ lile ni baba rẹ fi dari orilẹede Oman.

O fi ofin silẹ lati ma jẹ ki awọn eeyan rẹ ni anfani awọn nkankan bii gbigbọ rẹdio tabi wiwọ gilaasi oju koda to fi m yiyan ẹni ti wọn yoo fẹ funrawọn, ọrọ ileewe tabi bi wọn ba fẹ kuro lorilẹede.

Adari yii lo owo epo rọbi orilẹede naa lati fi san na idagbasoke fun Oman.

Nkan bii aadọta dun lo fi ṣejọba, Sultan Qaboos lo wa ni ori akoso igbe aye oṣelu orilẹede Oman nibi ti eeyan to fẹrẹẹ to miliọnu mẹrin abọ o le diẹ (4.6 million) wa.

Sultan Qaboos bin Said ni adari to ṣakoso ijọba orilẹede Oman to pẹ ju lagbaye.