JAMB ṣe ìdádúró lílo nọ́mbà ìdánimọ̀ fún ìdánwò àṣewọlé ọdún 2020

Oríṣun àwòrán, @EyeWitness101
Ajọ to n ri si idanwo aṣewọle iwe giga, JAMB ti ṣe idaduro lilo nọmba idanimọ Naijiria, NIN, fun iforukọ silẹ idanwo aṣewọle ọdun 2020.
Ọga agba ajọ JAMB, Ishaq Oloyede lo fi ọrọ naa lede nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ l'Abuja.
Bakan naa ni ajọ ọhun fi ọrọ naa lede loju opo Twitter rẹ, nibi to ti dari awọn oluṣedanwo lati fi orukọ wọn ranṣẹ si 55019 fun iforukọ silẹ idanwo naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
- Amotekun kò ní gbé ìbọn o! Ẹ wo ohun tí wọn yóò máa ṣe ní ìpínlẹ̀ - DAWN Commission
- African Parents: Òbí ayé àtijọ́ ló tọ́ ọ dàgbà tí o bá ṣe àwọn ǹkan wọ̀nyii
- Ilé iṣẹ́ ọmọogun kò sọ fún mi pé ọkọ mi kú fún ọdún kan- Iyawo soja
- Iran ní àwọn kò mọ̀ọ́mọ̀ ju irínṣẹ́ ìbúgbàmù "missile" lu bàálù Ukrain tó já
Ishaq sọ pe, idaduro lilo nọmba idanimọ naa jẹ ọna lati fun awọn to n ṣe idanwo JAMB lanfaani sii, lati lee gba nọmba idanimọ wọn.
O ni igbesẹ naa tun jẹ ọna lati lee wa ojutu si awọn kudiẹkudiẹ to n waye ni awọn ojuko idanwo JAMB kaakiri oriliẹ-ede yii.
- Obìnrin Kwara tí wọ́n tà sóko ẹrú ní Lebanon figbe ta, ọwọ́ tẹ èèbó kọ̀ráà tó ṣiṣẹ́ náà
- Kí ló ṣẹlẹ̀ lágbo tíátà lọ́sẹ̀ yìí?
- Ẹ́ kéde iye ọlọ́pá tó gba rìbá, kẹ tó máa yin ara yín - Aráàlú sọ fún ọlọ́pàá
- Ìjọba Ondo, inú fìfo la fi ń ṣiṣẹ́, ẹ ṣan ọ̀pọ̀ owó oṣù tẹ jẹ wa - Àwọn dókítà fárígá
- Wo Sultan Qaboos bin Said, ẹni tó gbàkóso ìgbé ayé òṣèlú Oman fún àádọta ọdún
Ọga agba ọhun ṣalaye siwaju sii pe, awọn oluṣedanwo ko nilo nọmba idanimọ fun idanwo ọdun 2020, ṣugbọn wọn yoo nilo nọmba naa fun idanwo ọdun 2021.
Ṣaaju lọdun 2019 ni ajọ JAMB sọ pe awọn to ba fẹ ṣe idanwo aṣewọle ọdun yii yoo nilo nọmba idanimọ naa lati lee fopin si bi awọn kan ṣe ma n forukọ silẹ funn idanwo ọhun ju igba kan lọ.









